Ẹni ti o ba ṣe aluwala gẹgẹ bi mo ṣe ṣe aluwala mi yii lẹyin naa o wa ki rakah meji ti ko ba ẹmi rẹ sọrọ nibi mejeeji, Ọlọhun yoo fori nnkan ti o ṣíwájú ninu ẹṣẹ rẹ jin in
Lati ọdọ Humraan ẹru Uthman ọmọ ‘Affan pé o ri Uthman ọmọ ‘Affan ti o beere fun omi aluwala, o ti ọwọ rẹ mejeeji bọ inu igba rẹ, o fọ mejeeji lẹẹmẹta, lẹyin naa o ti ọwọ rẹ ọtun bọ inu omi aluwala, lẹyin naa o fi omi yọ ẹnu rẹ o si fin in simu o si fin in síta, lẹyin na…

