o ṣe aluwala fun wọn ni aluwala Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-
Choose an available translation of this Hadeeth
Hadeeth text
Lati ọdọ Yahya ọmọ 'Umaaroh Al-Maaziniy o sọ pe: Mo ri ti Amru ọmọ Abu Hasan bi Abdullahi ọmọ Zaid leere nipa aluwala Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni o ba beere fun igba kan ti omi wa ninu ẹ, o ṣe aluwala fun wọn ni aluwala Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o da omi si ọwọ rẹ lati inu igba, o fọ ọwọ rẹ mejeeji lẹẹmẹta, lẹyin naa o ti ọwọ rẹ bọ inu igba, o fi omi yọ ẹnu o si fa a simu, O si fa a sita, ni gẹẹ mẹta, lẹyin naa o ti ọwọ rẹ bọ ọ, o si fọ oju rẹ lẹẹmẹta, lẹyin naa o fọ ọwọ rẹ mejeeji ni ẹẹmeji titi de igunpa mejeeji, lẹyin naa o ti ọwọ rẹ bọ ọ, o si pa ori rẹ, o gbe mejeeji lọ si ẹyin ati ṣíwájú ni ẹẹkan, lẹyin naa, o fọ ẹsẹ rẹ mejeeji titi de kokosẹ
Explanation
Benefits
Ṣíṣe pipaara lẹẹmẹta lẹtọọ ni apakan awọn orikee aluwala ati ẹẹmeji ni apakan rẹ, ati pe eyi ti o jẹ dandan ni ẹẹkan.
Jijẹ dandan titotẹlera laaarin awọn orikee aluwala gẹgẹ bi o ṣe wa ninu hadiisi naa.
Aala oju ni ibi ti irun ori ti n hù ti a ba saaba titi de nnkan ti o sọkalẹ ninu irun-agbọn ati agbọn ni òró, ati lati eti kan si eti keji ni ìbú.
Attribution
Categories
Share hadeeth
Sharing options · 0 Total shares

