«Mi o ni ki ẹ bura nítorí pé mo n fẹsun kan yin o, ṣugbọn Jubril wa ba mi o si fun mi ni iro pe dajudaju Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn n ṣe iyanran pẹlu yin ni ọdọ awọn malaika
Lati ọdọ Abu Sa’ēd Al-Khuduriy o sọ pe: Mu’āwiya lọ sibi àpéjọ kan ninu masalasi, ni o wa sọ pe: Kini nkan ti o mu yin jokoo? Wọn sọ pe: A jokoo fun iranti Ọlọhun, o sọ pe: Ẹ bura pẹlu Ọlọhun pe nkankan o mu yin jokoo ayaafi ìyẹn? Wọn sọ pe: A fi Ọlọhun bura ko si nkank…

