«Mi o ni ki ẹ bura nítorí pé mo n fẹsun kan yin o, ṣugbọn Jubril wa ba mi o si fun mi ni iro pe dajudaju Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn n ṣe iyanran pẹlu yin ni ọdọ awọn malaika
Choose an available translation of this Hadeeth
Hadeeth text
Lati ọdọ Abu Sa’ēd Al-Khuduriy o sọ pe: Mu’āwiya lọ sibi àpéjọ kan ninu masalasi, ni o wa sọ pe: Kini nkan ti o mu yin jokoo? Wọn sọ pe: A jokoo fun iranti Ọlọhun, o sọ pe: Ẹ bura pẹlu Ọlọhun pe nkankan o mu yin jokoo ayaafi ìyẹn? Wọn sọ pe: A fi Ọlọhun bura ko si nkankan ti o mu wa jokoo ayaafi ìyẹn, o sọ pe: Mi o ni ki ẹ bura nítorí pé mo n fẹsun kan yin o, ko si si ẹnikankan ti o wa ni iru ipo mi si Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ti ẹgbawa hadiisi rẹ lati ọdọ rẹ (Anabi) kere to temi: Ati pe dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jade si ibi akojọ awọn saabe rẹ, ni o wa sọ pe: Kini nkan ti o mu yin jokoo? Wọn sọ pe: A jokoo lati maa ranti Ọlọhun ati lati maa fi ẹyin fun Un lori bi O ṣe fi wa m'ọna si Isilaamu, ati idẹkun ti O fi i ṣe le wa lori, o sọ pe: «Ẹ bura pẹlu Ọlọhun ṣe nkankan o mu yin jokoo ayaafi ìyẹn?» Wọn sọ pe: A fi Ọlọhun bura ko si nkankan ti o mu wa jokoo ayaafi ìyẹn, o sọ pe : «Mi o ni ki ẹ bura nítorí pé mo n fẹsun kan yin o, ṣugbọn Jubril wa ba mi o si fun mi ni iro pe dajudaju Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn n ṣe iyanran pẹlu yin ni ọdọ awọn malaika».
Explanation
Benefits
Jijẹ ẹtọ bibeere fun ibura lai si ifura si, lati ṣe itaniji lórí pataki ìròyìn naa.
Ọla ti n bẹ fun awọn ijokoo iranti ati imọ ati pe dajudaju Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si i O si tun maa n ṣe iyanran pẹlu rẹ niwaju awọn malaika.
Attribution
Categories
Share hadeeth
Sharing options · 0 Total shares

