Ti ẹ ba ti gbọ oluperun ki ẹ yaa maa sọ gẹgẹ bi o ṣe n sọ, lẹyin naa ki ẹ wa ṣe asalaatu fun mi
Choose an available translation of this Hadeeth
Hadeeth text
Lati ọdọ Abdullāh ọmọ ‘Amru ọmọ al-‘Aas – ki Ọlọhun yọnu si i – dajudaju o gbọ ti Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – n sọ pe: «Ti ẹ ba ti gbọ oluperun ki ẹ yaa maa sọ gẹgẹ bi o ṣe n sọ, lẹyin naa ki ẹ wa ṣe asalaatu fun mi, torí pé dajudaju ẹni ti o ba ṣe asalaatu kan fun mi Ọlọhun a fi ṣe mewaa fun un, lẹyin naa ki ẹ beere al-Wasiilah fun mi lọdọ Ọlọhun, ati pe dajudaju oun ni ipo kan ninu al-jannah, ti ko si lẹtọọ ayaafi fun ẹru kan ninu awọn ẹru Ọlọhun, mo si fẹ ki o jẹ emi, nitori naa ẹni ti o ba beere al-Wasiilah fun mi iṣipẹ ti di ẹtọ fun un».
Explanation
Lẹyin naa ni o wa paṣẹ pẹlu bibi Ọlọhun leere al-Wasiilah fun oun– ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, ati pe oun (al-Wasiilah) naa ni ipo kan ninu al-jannah, ati pe oun lo ga jùlọ ninu rẹ, ko si lẹtọọ bẹẹ ni ko rọrun ayaafi fun ọkan ninu gbogbo awọn ẹru Ọlọhun ti ọla Rẹ ga, ti mo si n tanmọọn ki n jẹ ẹni naa, ati pe o sọ iyẹn – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ni ti itẹriba; torí pé dajudaju ti ipo giga yẹn o ba nii wa ayaafi fun ẹnikan, ko wa si ẹni ti o lẹ jẹ ẹnikan yẹn ayaafi oun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -; torí pé oun ni o lọla julọ ninu awọn ẹda.
Lẹyin naa o – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa ṣe alaye pe dajudaju ẹni ti o ba ṣe adua al-Wasiilah fun Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – iṣipẹ rẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – a jẹ tiẹ.
Benefits
Ọla ti n bẹ fun ṣiṣe asalaatu fun Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – lẹyin ijẹpe oluperun (sisọ gẹgẹ bi oluperun ṣe sọ).
Ṣiṣenilojukokoro lori bibeere al-Wasiilah fun Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – lẹyin ṣiṣe asalaatu fun un.
Alaye itumọ al-Wasiilah, ati giga ipo rẹ, latari pe ko lẹtọọ ayaafi fun ẹru kan.
Alaye ọla Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – latari pe wọn ṣe ipo ti o ga yẹn ni ẹsa fun un.
Ẹni ti o ba beere al-Wasiilah ni ọwọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- fún Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – iṣipẹ rẹ (Anabi) ti di ẹtọ fun un.
Alaye itẹriba rẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – latari pe o wa lati ọdọ awọn ijọ rẹ ki wọn ṣe adua fun un pẹlu ipo yẹn, toun ti pe dajudaju ti ẹ naa ni yio jẹ.
Gbigbaaye ọla Ọlọhun ati ikẹ Rẹ, nitori naa iṣẹ rere kan ilọpo mẹwaa iru rẹ ni ẹsan rẹ.
Attribution
Categories
Share hadeeth
Sharing options · 0 Total shares

