Ṣé ki n sọ ọrọ kan fun yin nipa dajjal, ti Anabi kan ko sọ nipa rẹ ri fun ijọ rẹ? O jẹ olójú kan, o maa mu nnkan ti o da bii alujanna ati ina wa pẹlu rẹ,
Choose an available translation of this Hadeeth
Hadeeth text
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Ṣé ki n sọ ọrọ kan fun yin nipa dajjal, ti Anabi kan ko sọ nipa rẹ ri fun ijọ rẹ? O jẹ olójú kan, o maa mu nnkan ti o da bii alujanna ati ina wa pẹlu rẹ, eyi ti o n pe ni alujanna ni ina, mo n ṣekilọ fun yin gẹgẹ bi Nuh ṣe ṣekilọ fun ijọ rẹ pẹlu rẹ".
Explanation
Pe o jẹ olójú kan.
Ati pe dajudaju Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- fi nnkan ti o daa bii alujanna ati ina pẹlu rẹ, ni ibamu si riri oju.
Ṣugbọn alujanna rẹ jẹ iná, ti ina rẹ si jẹ alujanna, ẹni ti o ba tẹle e o maa mu u wọ inu alujanna yii ninu nnkan ti awọn eniyan n ri, ṣùgbọ́n ina ti o n jóni ni, ẹni ti o ba yapa rẹ o maa mu u wọ ina ninu nnkan ti awọn eniyan n ri, ṣùgbọ́n alujanna ti o daa ni, Lẹyin naa, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣekilọ fun wa kuro nibi wahala rẹ gẹgẹ bi Nuh ṣe ṣekilọ fun ijọ rẹ pẹlu rẹ.
Benefits
Lila kuro nibi wahala dajjal maa jẹ pẹlu igbagbọ òdodo ati sisadi Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ati wiwa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro lọdọ rẹ nibi ataya ikẹyin, ati hiha aayah mẹwaa ninu akọkọ Suratul Kahf.
Ilekoko akolekan Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori ìjọ rẹ, nigba ti o ṣe alaye fun awọn Musulumi ninu awọn iroyin dajjal ninu nnkan ti Anabi kan ko ṣàlàyé rẹ ri ṣíwájú rẹ.
Attribution
Categories
Share hadeeth
Sharing options · 0 Total shares

