Ọlọhun a mu u wọ al-jannah lori èyíkéyìí iṣẹ ti o ba wa lori rẹ
Choose an available translation of this Hadeeth
Hadeeth text
Lati ọdọ ‘Ubadah - ki Ọlọhun yọnu si i - lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe: «Ẹni ti o ba jẹrii pe ko si ẹni ti ijọsin ododo tọ si ayaafi Allāhu ni ọkan soso ti ko si akẹgbẹ fun Un, ati pe dajudaju Muhammad ẹrusin Rẹ ati ojiṣẹ Rẹ ni, ati pe Isa ẹrusin Ọlọhun ni ojiṣẹ Rẹ si tun ni ati pe ọ̀rọ̀ Rẹ̀ (kun fayakūn) tí Ó sọ ránṣẹ́ sí Mọryam l’Ó sì fi ṣẹ̀dá rẹ̀. Ẹ̀mí kan (tí Allāhu ṣẹ̀dá) láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni, ati pe al-jannah ododo ni, ina ododo ni, Ọlọhun a mu u wọ al-jannah lori èyíkéyìí iṣẹ ti o ba wa lori rẹ»
Explanation
Benefits
Ikopapọ laarin jíjẹ́ ẹru Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ ti Anabi Isa ati Anabi Muhammad - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba awọn mejeeji - jẹ, awọn mejeeji ojiṣẹ Ọlọhun ni wọn ti wọn ko si ki n parọ, ati pe ẹrusin ni wọn ti wọn ko kii n sin wọn.
Ọla ti n bẹ fun mimu Ọlọhun lọkan ati iparẹ rẹ fun awọn ẹṣẹ, ati pe ibudesi olumu-Ọlọhun-lọkan ni alujanna, koda ki awọn ẹṣẹ kan o ti ọwọ rẹ wa.
Attribution
Categories
Share hadeeth
Sharing options · 0 Total shares

