Ojiṣẹ Ọlọhun- kí ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba wa sọrọ, olódodo ni, ẹni tí a sọ òdodo fún si ni: “Wípé wọ́n maa kó ẹ̀dá ẹnikan nínú yín jọ sínú ikùn ìyá rẹ̀ fún ogójì ọjọ́
Choose an available translation of this Hadeeth
Hadeeth text
Láti ọ̀dọ̀ Abdullah ọmọ Mas’huud- ki Ọlọhun yọnu si i-: Ojiṣẹ Ọlọhun- kí ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba wa sọrọ, olódodo ni, ẹni tí a sọ òdodo fún si ni: “Wípé wọ́n maa kó ẹ̀dá ẹnikan nínú yín jọ sínú ikùn ìyá rẹ̀ fún ogójì ọjọ́, lẹ́yìn náà yóò di ẹjẹ dídì fun ogójì ọjọ́, lẹyin naa yoo di baaṣi ẹran fun ogójì ọjọ́, lẹ́yìn náà wọn maa ran malaika si i, wọ́n maa pa a láṣẹ pẹ̀lú gbólóhùn mẹrin kan, wọn maa waa kọ: Arisiki rẹ, ati àsìkò rẹ, ati iṣẹ rẹ, ati pe ṣe oloriburuku ni abi oloriire, lẹ́yìn naa wọn maa fẹ́ ẹ̀mí si i lára, dájúdájú ẹnikan ninu yin yoo maa ṣe iṣẹ́ ọmọ alujanna, titi ti ohun ti o ṣẹku láàrin rẹ ati láàrin alujanna ko fi nii ju apá lọ, àkọsílẹ̀ maa wa borí rẹ, yoo waa maa ṣe iṣẹ́ ọmọ iná, yoo si wọ ọ, dájúdájú ẹnikan nínú yin, yoo maa ṣe iṣẹ́ ọmọ ina, titi ti ohun ti o ṣẹku láàrin rẹ ati láàrin iná ko fi nii ju apá lọ, àkọsílẹ̀ maa wa borí rẹ, yoo waa maa ṣe iṣẹ́ ọmọ alujanna, yoo si wọ̀ ọ́”.
Explanation
Benefits
Ikilọ kúrò nibi gbígba ẹtan pẹ̀lú àwọn àwòrán iṣẹ; torí pé igbẹyin gan ni iṣẹ.
Attribution
Categories
Share hadeeth
Sharing options · 0 Total shares

