Awọn iwa Musulumi

اخلاق المسلم

Awọn iwa Musulumi

اسم اللغة
يوروبا
Yoruba

و لا تعتدوا.
E ma ṣe tayọ ala

و لا تعثوا في الأرض مفسدين.
E ma ṣe ibajẹ lori ilẹ.

و لا تلبسوا الحق بالباطل
E ma ṣe da irọ pọ mọ otitọ.

و لا تقف ما ليس لك به علم
Ma tẹle ohun ti o ni imọ nipa ẹ

و لا تمش في الأرض مرحا
Má rìn irin igberaga lórí ilẹ̀

و لا تصعر خدك للناس
Má ṣe yí ẹ̀kẹ́ rẹ sí àwọn ènìyàn

و اخفض جناحك للمؤمنين.
Ni itẹriba fun awọn onigbagbọ ododo.

و اغضض من صوتك
Rẹ ohun rẹ nlẹ

و اقصد في مشيك.
Rin lọna iwọntuwọnsi

و اعرض عن الجاهلين.
ṣẹri kuro lọdọ awọn alaimọkan

خذ العفو و أمر بالعرف.
ṣe amojukuro ki o si paṣẹ iwa daada

ادفع بالتي هي أحسن.
Fi iwa daada ti iwa bu lọ

ادع إلى سبيل ربك بالحكمة
pèpè sí ọ̀nà Olúwa rẹ pẹ̀lú ọgbọ́n

لا تبطلوا صدقاتكم بالمن و الأذى
Ẹ ma ṣe ba saara yin jẹ pẹlu iregun ati ipalara

و لا تأكلوا أموالكم بينكم بالباطل
Ẹ ma ṣe jẹ owo ara yin pelu ibajẹ

و لا تنابزوا بالألقاب.
Ẹ ma ṣe pe ra yin ni orukọ ti koda

و لا يسخر قوم من قوم
Ki awọn ènìyàn kan maṣe fi awọn ènìyàn kan ṣe yẹ̀yẹ́

و لا يغتب بعضكم بعضا
Ẹ má sọ̀rọ̀ ara yín lẹyin

و لا تجسسوا.
Ẹ má tọpinpin ara yín

إجتنبوا كثيرا من الظن
Ẹ jina si pupọ abadida

ادخلوا في السلم كافة
Ẹ wọ inu ẹsin yanyan

و إذا حييتم بتحية فحيوا بأحسن منها
Bí wọn a bá kí yín, ẹ kí wọn pẹlu eyi to dára jùlọ

و بالوالدين إحسانا و ذي القربى و اليتامى
Ẹ ṣe daada si awọn obi yin, ati awọn to sun mọ yin ati awọn ọmọ orukan

و أطعموا البائس الفقير
Ẹ fun àwọn aláìní ni ounjẹ

و لا تتبدلوا الخبيث بالطيب
Ẹ má fi nkan daada ṣe pàṣípààrọ̀ ohun búburú

و آتوا اليتامى أموالهم
Ẹ fún àwọn ọmọ òrukàn ní owó wọn

أنفقوا مما رزقناكم
Ẹ na ninu ohun ti A fun nyin

و قولوا قولا سديدا
Ẹ sọ ọrọ ti o tọ

و قولوا للناس حسنا
Ẹ sọ ọrọ daada fun àwọn eniyan

و لا تعاونوا على الإثم و العدوان
Ẹ ma ṣe fọwọsowọpọ lori ẹṣẹ ati ikọja ala

و تعاونوا على البر و التقوى
Ẹ fi ọwọsowọpọ lori daada ati ibẹru Olohun

و احفظوا أيمانكم
Ẹ mu ibura yin ṣẹ

و أوفوا بعهد الله إذا عاهدتم
Ẹ mu adehun Ọlọrun ṣẹ nigbati ẹ ba ṣe adehun

و أوفوا الكيل إذا كلتم
Ẹ pe oṣuwọn nigbati ẹ ba nwọn

و زنوا بالقسطاس المستقيم
Ẹ wọn pẹ̀lú òṣùwọ̀n to dọgba

كونوا قوامين بالقسط
Ẹ jẹ oluduro sinsin pẹlu deede

اعدلوا
Ẹ ṣe deede