الأنفال

 

Al-Anfal

 

The Spoils of War

1 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 001

يَسۡـَٔلُونَكَ عَنِ ٱلۡأَنفَالِۖ قُلِ ٱلۡأَنفَالُ لِلَّهِ وَٱلرَّسُولِۖ فَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَأَصۡلِحُواْ ذَاتَ بَيۡنِكُمۡۖ وَأَطِيعُواْ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥٓ إِن كُنتُم مُّؤۡمِنِينَ
Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa ọrọ̀ ogun. Sọ pé: “Ọrọ̀ ogun jẹ́ ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì ṣe àtúnṣe n̄ǹkan tí ń bẹ láààrin yín. Ẹ tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.

2 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 002

إِنَّمَا ٱلۡمُؤۡمِنُونَ ٱلَّذِينَ إِذَا ذُكِرَ ٱللَّهُ وَجِلَتۡ قُلُوبُهُمۡ وَإِذَا تُلِيَتۡ عَلَيۡهِمۡ ءَايَٰتُهُۥ زَادَتۡهُمۡ إِيمَٰنٗا وَعَلَىٰ رَبِّهِمۡ يَتَوَكَّلُونَ
Àwọn onígbàgbọ́ òdodo ni àwọn tó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá fi (ìyà) Allāhu ṣe ìrántí (fún wọn), ọkàn wọn yóò wárìrì, nígbà tí wọ́n bá sì ké àwọn āyah Rẹ̀ fún wọn, wọn yóò lékún ní ìgbàgbọ́ òdodo. Olúwa wọn sì ni wọ́n ń gbáralé.

3 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 003

ٱلَّذِينَ يُقِيمُونَ ٱلصَّلَوٰةَ وَمِمَّا رَزَقۡنَٰهُمۡ يُنفِقُونَ
(Àwọn ni) àwọn tó ń kírun, tí wọ́n sì ń ná nínú ohun tí A pèsè fún wọn.

4 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 004

أُوْلَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡمُؤۡمِنُونَ حَقّٗاۚ لَّهُمۡ دَرَجَٰتٌ عِندَ رَبِّهِمۡ وَمَغۡفِرَةٞ وَرِزۡقٞ كَرِيمٞ
Ní òdodo, àwọn wọ̀nyẹn ni onígbàgbọ́ òdodo. Àwọn ipò gíga, àforíjìn àti arísìkí alápọ̀n-ọ́nlé ń bẹ fún wọn lọ́dọ̀ Olúwa wọn.

5 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 005

كَمَآ أَخۡرَجَكَ رَبُّكَ مِنۢ بَيۡتِكَ بِٱلۡحَقِّ وَإِنَّ فَرِيقٗا مِّنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ لَكَٰرِهُونَ
Gẹ́gẹ́ bí Olúwa rẹ ṣe mú ọ jáde (lọ sí ojú ogun) láti inú ilé rẹ pẹ̀lú òdodo, dájúdájú igun kan nínú àwọn onígbàgbọ́ ni ẹ̀mí wọn kórira rẹ̀.

6 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 006

يُجَٰدِلُونَكَ فِي ٱلۡحَقِّ بَعۡدَ مَا تَبَيَّنَ كَأَنَّمَا يُسَاقُونَ إِلَى ٱلۡمَوۡتِ وَهُمۡ يَنظُرُونَ
Wọ́n sì ń takò ọ́ níbi òdodo lẹ́yìn tí ó ti fojú hàn (sí wọn) àfi bí ẹni pé wọ́n ń wà wọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ ikú, tí wọ́n sì ń wò ó (báyìí).

7 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 007

وَإِذۡ يَعِدُكُمُ ٱللَّهُ إِحۡدَى ٱلطَّآئِفَتَيۡنِ أَنَّهَا لَكُمۡ وَتَوَدُّونَ أَنَّ غَيۡرَ ذَاتِ ٱلشَّوۡكَةِ تَكُونُ لَكُمۡ وَيُرِيدُ ٱللَّهُ أَن يُحِقَّ ٱلۡحَقَّ بِكَلِمَٰتِهِۦ وَيَقۡطَعَ دَابِرَ ٱلۡكَٰفِرِينَ
(Rántí) nígbà tí Allāhu ṣàdéhùn ọ̀kan nínú àwọn ìjọ méjèèjì fún yín pé ó máa jẹ́ tiyín, ẹ̀yin sì ń fẹ́ kí ìjọ tí kò dira ogun jẹ́ tiyín. Allāhu sì fẹ́ mú òdodo ṣẹ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀, Ó sì (fẹ́) pa àwọn aláìgbàgbọ́ run pátápátá

8 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 008

لِيُحِقَّ ٱلۡحَقَّ وَيُبۡطِلَ ٱلۡبَٰطِلَ وَلَوۡ كَرِهَ ٱلۡمُجۡرِمُونَ
nítorí kí (Allāhu) lè fi òdodo (’Islām) rinlẹ̀ ní òdodo, kí Ó sì lè paná irọ́ (ìbọ̀rìṣà), àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ (ọ̀ṣẹbọ) ìbáà kórira rẹ̀.

9 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 009

إِذۡ تَسۡتَغِيثُونَ رَبَّكُمۡ فَٱسۡتَجَابَ لَكُمۡ أَنِّي مُمِدُّكُم بِأَلۡفٖ مِّنَ ٱلۡمَلَـٰٓئِكَةِ مُرۡدِفِينَ
(Rántí) nígbà tí ẹ̀ ń wá ìrànlọ́wọ́ Olúwa yín, Ó sì da yín lóhùn pé dájúdájú Èmi yóò ràn yín lọ́wọ́ pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún kan nínú àwọn mọlāika tó máa wá ní tẹ̀léǹtẹ̀lé.

10 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 010

وَمَا جَعَلَهُ ٱللَّهُ إِلَّا بُشۡرَىٰ وَلِتَطۡمَئِنَّ بِهِۦ قُلُوبُكُمۡۚ وَمَا ٱلنَّصۡرُ إِلَّا مِنۡ عِندِ ٱللَّهِۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَزِيزٌ حَكِيمٌ
Allāhu kò sì ṣe (ìrànlọ́wọ́ àwọn mọlāika) lásán bí kò ṣe nítorí kí ó lè jẹ́ ìró ìdùnnú àti nítorí kí ọkàn yín lè balẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Kò sí àrànṣe kan àfi láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

11 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 011

إِذۡ يُغَشِّيكُمُ ٱلنُّعَاسَ أَمَنَةٗ مِّنۡهُ وَيُنَزِّلُ عَلَيۡكُم مِّنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗ لِّيُطَهِّرَكُم بِهِۦ وَيُذۡهِبَ عَنكُمۡ رِجۡزَ ٱلشَّيۡطَٰنِ وَلِيَرۡبِطَ عَلَىٰ قُلُوبِكُمۡ وَيُثَبِّتَ بِهِ ٱلۡأَقۡدَامَ
(Rántí) nígbà tí (Allāhu) ta yín ní òògbé lọ (kí ó lè jẹ́) ìfọ̀kànbalẹ̀ (fún yín) láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ó tún sọ omi kalẹ̀ fún yín láti sánmọ̀ nítorí kí Ó fi lè fọ̀ yín mọ́ (pẹ̀lú ìwẹ̀ ọ̀ran-anyàn), àti nítorí kí Ó fi lè mú èròkérò aṣ-Ṣaetọ̄n (bí àlá ìbálòpò ojú oorun) kúrò fún yín àti nítorí kí Ó lè kì yín lọ́kàn àti nítorí kí Ó lè mú ẹsẹ̀ yín dúró ṣinṣin.

12 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 012

إِذۡ يُوحِي رَبُّكَ إِلَى ٱلۡمَلَـٰٓئِكَةِ أَنِّي مَعَكُمۡ فَثَبِّتُواْ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْۚ سَأُلۡقِي فِي قُلُوبِ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ ٱلرُّعۡبَ فَٱضۡرِبُواْ فَوۡقَ ٱلۡأَعۡنَاقِ وَٱضۡرِبُواْ مِنۡهُمۡ كُلَّ بَنَانٖ
(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ fi mọ àwọn mọlāika pé dájúdájú Èmi ń bẹ pẹ̀lú yín. Nítorí náà, ẹ fi ẹsẹ̀ àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo rinlẹ̀. Èmi yóò ju ẹ̀rù sínú ọkàn àwọn tó ṣàì gbàgbọ́. Nítorí náà, ẹ máa gé (wọn) lọ́rùn. Kí ẹ sì máa gé gbogbo ọmọ ìka wọn.

13 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 013

ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ شَآقُّواْ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥۚ وَمَن يُشَاقِقِ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ فَإِنَّ ٱللَّهَ شَدِيدُ ٱلۡعِقَابِ
Ìyẹn nítorí pé, wọ́n yapa (ọ̀rọ̀) Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì yapa (ọ̀rọ̀) Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, dájúdájú Allāhu le (níbi) ìyà.

14 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 014

ذَٰلِكُمۡ فَذُوقُوهُ وَأَنَّ لِلۡكَٰفِرِينَ عَذَابَ ٱلنَّارِ
Ìyẹn (ni ìyà tayé). Nítorí náà, ẹ tọ́ ọ wò. Àti pé dájúdájú ìyà Iná ń bẹ fún àwọn aláìgbàgbọ́.

15 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 015

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِذَا لَقِيتُمُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ زَحۡفٗا فَلَا تُوَلُّوهُمُ ٱلۡأَدۡبَارَ
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí ẹ bá pàdé àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n ń wọ́ jáde níkọ̀ níkọ̀, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ pẹ̀yìn dà sí wọn (láti ságun).

16 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 016

وَمَن يُوَلِّهِمۡ يَوۡمَئِذٖ دُبُرَهُۥٓ إِلَّا مُتَحَرِّفٗا لِّقِتَالٍ أَوۡ مُتَحَيِّزًا إِلَىٰ فِئَةٖ فَقَدۡ بَآءَ بِغَضَبٖ مِّنَ ٱللَّهِ وَمَأۡوَىٰهُ جَهَنَّمُۖ وَبِئۡسَ ٱلۡمَصِيرُ
Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì pẹ̀yìn dà sí wọn ní ọjọ́ yẹn, yàtọ̀ sí ẹni tó yẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ kan (láti túnra mú) fún ogun tàbí ẹni tó fẹ́ darapọ̀ mọ́ ikọ̀ (mùsùlùmí láti fún wọn ní ìró ọ̀tẹlẹ̀-múyẹ́), dájúdájú (aságun) ti padà wálé pẹ̀lú ìbínú láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Iná Jahanamọ sì ni ibùgbé rẹ̀. Ìkángun náà sì burú.

17 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 017

فَلَمۡ تَقۡتُلُوهُمۡ وَلَٰكِنَّ ٱللَّهَ قَتَلَهُمۡۚ وَمَا رَمَيۡتَ إِذۡ رَمَيۡتَ وَلَٰكِنَّ ٱللَّهَ رَمَىٰ وَلِيُبۡلِيَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ مِنۡهُ بَلَآءً حَسَنًاۚ إِنَّ ٱللَّهَ سَمِيعٌ عَلِيمٞ
Ẹ̀yin kọ́ lẹ pa wọ́n, ṣùgbọ́n Allāhu l’Ó pa wọ́n. Àti pé ìwọ kọ́ lo jùkò nígbà tí o jùkò, àmọ́ dájúdájú Allāhu l’Ó jùkò[1] nítorí kí (Allāhu) lè fi àmìwò dáadáa kan àwọn onígbàgbọ́ òdodo láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni. Dájúdájú Allāhu ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
1. Ìyẹn ni pé, àṣẹ Allāhu - subhānahu wa ta'ālā - tó ń bẹ lára òkò tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - jù lu àwọn kèfèrí l’ó gba ẹ̀mí wọn.

18 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 018

ذَٰلِكُمۡ وَأَنَّ ٱللَّهَ مُوهِنُ كَيۡدِ ٱلۡكَٰفِرِينَ
Ìyẹn (báyẹn). Dájúdájú Allāhu máa sọ ète àwọn aláìgbàgbọ́ di lílẹ.

19 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 019

إِن تَسۡتَفۡتِحُواْ فَقَدۡ جَآءَكُمُ ٱلۡفَتۡحُۖ وَإِن تَنتَهُواْ فَهُوَ خَيۡرٞ لَّكُمۡۖ وَإِن تَعُودُواْ نَعُدۡ وَلَن تُغۡنِيَ عَنكُمۡ فِئَتُكُمۡ شَيۡـٔٗا وَلَوۡ كَثُرَتۡ وَأَنَّ ٱللَّهَ مَعَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ
Tí ẹ̀yin (aláìgbàgbọ́) bá ń wá ìdájọ́, dájúdájú ìdájọ́ ti kò le yín lórí. Tí ẹ bá jáwọ́ (níbi ogun), ó sì dára jùlọ fún yín. Tí ẹ bá tún padà (síbi ogun), A máa padà (ran àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́wọ́); àkójọ yín kò sì níí rọ̀ yín lọ́rọ̀ kan kan, ìbáà pọ̀. Dájúdájú Allāhu ń bẹ pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

20 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 020

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ أَطِيعُواْ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ وَلَا تَوَلَّوۡاْ عَنۡهُ وَأَنتُمۡ تَسۡمَعُونَ
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ẹ má ṣe gbúnrí kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ nígbà tí ẹ bá ń gbọ́ (āyah) lọ́wọ́.

21 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 021

وَلَا تَكُونُواْ كَٱلَّذِينَ قَالُواْ سَمِعۡنَا وَهُمۡ لَا يَسۡمَعُونَ
Ẹ má se dà bí àwọn tí wọ́n wí pé: “A gbọ́.” Wọn kò sì gbọ́.

22 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 022

۞إِنَّ شَرَّ ٱلدَّوَآبِّ عِندَ ٱللَّهِ ٱلصُّمُّ ٱلۡبُكۡمُ ٱلَّذِينَ لَا يَعۡقِلُونَ
Dájúdájú ẹ̀dá abẹ̀mí tó burú jùlọ ní ọ̀dọ̀ Allāhu ni àwọn adití, ayaya tí kò ṣe làákàyè.

23 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 023

وَلَوۡ عَلِمَ ٱللَّهُ فِيهِمۡ خَيۡرٗا لَّأَسۡمَعَهُمۡۖ وَلَوۡ أَسۡمَعَهُمۡ لَتَوَلَّواْ وَّهُم مُّعۡرِضُونَ
Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu mọ oore kan lára wọn ni, ìbá jẹ́ kí wọ́n gbọ́. Tí (Allāhu) bá sì fún wọn gbọ́ ni, dájúdájú wọn máa pẹ̀yìn dà, wọn yó sì máa gbúnrí.

24 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 024

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱسۡتَجِيبُواْ لِلَّهِ وَلِلرَّسُولِ إِذَا دَعَاكُمۡ لِمَا يُحۡيِيكُمۡۖ وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ يَحُولُ بَيۡنَ ٱلۡمَرۡءِ وَقَلۡبِهِۦ وَأَنَّهُۥٓ إِلَيۡهِ تُحۡشَرُونَ
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ jẹ́pè ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́ nígbà tí ó bá pè yín síbi n̄ǹkan tí ó máa mu yín ṣẹ̀mí. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ń ṣèdíwọ́ láààrin ènìyàn àti ọkàn rẹ̀. Dájúdájú ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọ́n máa ko yín jọ sí.

25 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 025

وَٱتَّقُواْ فِتۡنَةٗ لَّا تُصِيبَنَّ ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ مِنكُمۡ خَآصَّةٗۖ وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ شَدِيدُ ٱلۡعِقَابِ
Ẹ ṣọrá fún àdánwò kan tí kò níí mọ lórí àwọn tó ṣàbòsí nínú yín nìkan. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu le níbi ìyà.

26 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 026

وَٱذۡكُرُوٓاْ إِذۡ أَنتُمۡ قَلِيلٞ مُّسۡتَضۡعَفُونَ فِي ٱلۡأَرۡضِ تَخَافُونَ أَن يَتَخَطَّفَكُمُ ٱلنَّاسُ فَـَٔاوَىٰكُمۡ وَأَيَّدَكُم بِنَصۡرِهِۦ وَرَزَقَكُم مِّنَ ٱلطَّيِّبَٰتِ لَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ
Ẹ rántí pé nígbà tí ẹ̀yin kéré ní òǹkà, tí ẹ wà ní ipò ọ̀lẹ (lábẹ́ wọn) lórí ilẹ̀ (ìyẹn nínú ìlú Mọkkah), ẹ sì ń páyà pé àwọn ènìyàn máa ji yín gbé lọ, nígbà náà (Allāhu) ṣe ibùgbé fún yín (nínú ìlú Mọdīnah Onímọ̀ọ́lẹ̀), Ó sì fi àrànṣe Rẹ ṣe ìkúnlọ́wọ́ fún yín. Ó tún pèsè fún yín nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa nítorí kí ẹ lè dúpẹ́.

27 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 027

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَخُونُواْ ٱللَّهَ وَٱلرَّسُولَ وَتَخُونُوٓاْ أَمَٰنَٰتِكُمۡ وَأَنتُمۡ تَعۡلَمُونَ
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe jàǹbá (ọ̀ran-anyàn) Allāhu àti (sunnah) Òjíṣẹ́; ẹ má ṣe jàǹbá àwọn àgbàfipamọ́ yín, ẹ sì mọ (ìjàǹbá).

28 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 028

وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّمَآ أَمۡوَٰلُكُمۡ وَأَوۡلَٰدُكُمۡ فِتۡنَةٞ وَأَنَّ ٱللَّهَ عِندَهُۥٓ أَجۡرٌ عَظِيمٞ
Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú ìfòòró ni àwọn dúkìá yín àti àwọn ọmọ yín, àti pé dájúdájú Allāhu ni ẹ̀san ńlá wà ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

29 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 029

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِن تَتَّقُواْ ٱللَّهَ يَجۡعَل لَّكُمۡ فُرۡقَانٗا وَيُكَفِّرۡ عَنكُمۡ سَيِّـَٔاتِكُمۡ وَيَغۡفِرۡ لَكُمۡۗ وَٱللَّهُ ذُو ٱلۡفَضۡلِ ٱلۡعَظِيمِ
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, tí ẹ bá bẹ̀rù Allāhu, Ó máa fún yín ní ọ̀nà àbáyọ. Ó máa pa àwọn àṣìṣe yín rẹ́ fún yín. Ó sì máa foríjìn yín. Allāhu sì ni Ọlọ́lá tó tóbi.

30 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 030

وَإِذۡ يَمۡكُرُ بِكَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لِيُثۡبِتُوكَ أَوۡ يَقۡتُلُوكَ أَوۡ يُخۡرِجُوكَۚ وَيَمۡكُرُونَ وَيَمۡكُرُ ٱللَّهُۖ وَٱللَّهُ خَيۡرُ ٱلۡمَٰكِرِينَ
(Rántí) nígbà tí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ń déte sí ọ láti dè ọ́ mọ́lẹ̀ tàbí láti pa ọ́ tàbí láti yọ ọ́ kúrò nínú ìlú; wọ́n ń déte, Allāhu sì ń déte. Allāhu sì lóore jùlọ nínú àwọn adéte.[1]
1. Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - kì í ṣe adéte. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:15 àti sūrah as-Sọ̄ffāt; 37:125.

31 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 031

وَإِذَا تُتۡلَىٰ عَلَيۡهِمۡ ءَايَٰتُنَا قَالُواْ قَدۡ سَمِعۡنَا لَوۡ نَشَآءُ لَقُلۡنَا مِثۡلَ هَٰذَآ إِنۡ هَٰذَآ إِلَّآ أَسَٰطِيرُ ٱلۡأَوَّلِينَ
Nígbà tí A bá ń ké àwọn āyah Wa fún wọn, wọ́n á wí pé: “A kúkú ti gbọ́. Tí ó bá jẹ́ pé a bá fẹ́ ni. àwa náà ìbá sọ irú èyí. Kí ni èyí bí kò ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́.”

32 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 032

وَإِذۡ قَالُواْ ٱللَّهُمَّ إِن كَانَ هَٰذَا هُوَ ٱلۡحَقَّ مِنۡ عِندِكَ فَأَمۡطِرۡ عَلَيۡنَا حِجَارَةٗ مِّنَ ٱلسَّمَآءِ أَوِ ٱئۡتِنَا بِعَذَابٍ أَلِيمٖ
(Rántí) nígbà tí wọ́n wí pé: “Allāhu, tí ó bá jẹ́ pé èyí ni òdodo láti ọ̀dọ̀ Rẹ, rọ òjò òkúta lé wa lórí láti sánmọ̀ tàbí kí O mú ìyà ẹlẹ́ta-eléro kan wá bá wa.”

33 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 033

وَمَا كَانَ ٱللَّهُ لِيُعَذِّبَهُمۡ وَأَنتَ فِيهِمۡۚ وَمَا كَانَ ٱللَّهُ مُعَذِّبَهُمۡ وَهُمۡ يَسۡتَغۡفِرُونَ
Allāhu kò níí jẹ wọ́n níyà nígbà tí ìwọ sì ń bẹ láààrin wọn. Allāhu kò sì níí jẹ wọ́n níyà nígbà tí wọ́n sì ń tọrọ àforíjìn.

34 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 034

وَمَا لَهُمۡ أَلَّا يُعَذِّبَهُمُ ٱللَّهُ وَهُمۡ يَصُدُّونَ عَنِ ٱلۡمَسۡجِدِ ٱلۡحَرَامِ وَمَا كَانُوٓاْ أَوۡلِيَآءَهُۥٓۚ إِنۡ أَوۡلِيَآؤُهُۥٓ إِلَّا ٱلۡمُتَّقُونَ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَهُمۡ لَا يَعۡلَمُونَ
Kò sí ìdí tí Allāhu kò fi níí jẹ wọ́n níyà níwọ̀n ìgbà tí wọ́n bá ń ṣẹ́ àwọn ènìyàn lórí kúrò nínú Mọ́sálásí Haram. Àti pé àwọn ọ̀ṣẹbọ kọ́ ni alámòjúútó rẹ̀. Kò sí alámòjúútó kan fún un bí kò ṣe àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu), ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.

35 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 035

وَمَا كَانَ صَلَاتُهُمۡ عِندَ ٱلۡبَيۡتِ إِلَّا مُكَآءٗ وَتَصۡدِيَةٗۚ فَذُوقُواْ ٱلۡعَذَابَ بِمَا كُنتُمۡ تَكۡفُرُونَ
Ìjọ́sìn àwọn ọ̀ṣẹbọ ní Ilé (Kaabah) kò sì tayọ ṣíṣú ìfé àti pípa àtẹ́wọ́. Nítorí náà, ẹ tọ́ Ìyà wò nítorí pé ẹ jẹ́ aláìgbàgbọ́.

36 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 036

إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ يُنفِقُونَ أَمۡوَٰلَهُمۡ لِيَصُدُّواْ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِۚ فَسَيُنفِقُونَهَا ثُمَّ تَكُونُ عَلَيۡهِمۡ حَسۡرَةٗ ثُمَّ يُغۡلَبُونَۗ وَٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ إِلَىٰ جَهَنَّمَ يُحۡشَرُونَ
Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, wọ́n ń ná dúkìá wọn nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Wọ́n sì ń ná a lọ (bẹ́ẹ̀). Lẹ́yìn náà, ó máa di àbámọ̀ fún wọn. Lẹ́yìn náà, A sì máa borí wọn. Àti pé àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, inú iná Jahanamọ ni A máa kó wọn jọ sí

37 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 037

لِيَمِيزَ ٱللَّهُ ٱلۡخَبِيثَ مِنَ ٱلطَّيِّبِ وَيَجۡعَلَ ٱلۡخَبِيثَ بَعۡضَهُۥ عَلَىٰ بَعۡضٖ فَيَرۡكُمَهُۥ جَمِيعٗا فَيَجۡعَلَهُۥ فِي جَهَنَّمَۚ أُوْلَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡخَٰسِرُونَ
nítorí kí Allāhu lè ya àwọn ẹni ibi sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ẹni ire àti nítorí kí Ó lè kó àwọn ẹni ibi papọ̀; apá kan wọn mọ́ apá kan, kí Ó sì lè rọ́ gbogbo wọn papọ̀ pátápátá (sójú kan náà), Ó sì máa fi wọ́n sínú iná Jahanamọ. Àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni ẹni òfò.

38 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 038

قُل لِّلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ إِن يَنتَهُواْ يُغۡفَرۡ لَهُم مَّا قَدۡ سَلَفَ وَإِن يَعُودُواْ فَقَدۡ مَضَتۡ سُنَّتُ ٱلۡأَوَّلِينَ
Sọ fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ pé tí wọ́n bá jáwọ́ (nínú àìgbàgbọ́), A máa ṣàforíjìn ohun tó ti ré kọjá fún wọn. Tí wọ́n bá tún padà (síbẹ̀, àpèjúwe) ìparun àwọn ẹni àkọ́kọ́ kúkú ti ré kọjá (ní ìkìlọ̀ fún wọn).

39 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 039

وَقَٰتِلُوهُمۡ حَتَّىٰ لَا تَكُونَ فِتۡنَةٞ وَيَكُونَ ٱلدِّينُ كُلُّهُۥ لِلَّهِۚ فَإِنِ ٱنتَهَوۡاْ فَإِنَّ ٱللَّهَ بِمَا يَعۡمَلُونَ بَصِيرٞ
Ẹ jà wọ́n lógun títí kò fi níí sí ìfòòró (ìbọ̀rìṣà) mọ́, gbogbo ẹ̀sìn yó sì lè jẹ́ ti Allāhu pátápátá. Nítorí náà, tí wọ́n bá jáwọ́ (nínú àìgbàgbọ́), dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

40 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 040

وَإِن تَوَلَّوۡاْ فَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ مَوۡلَىٰكُمۡۚ نِعۡمَ ٱلۡمَوۡلَىٰ وَنِعۡمَ ٱلنَّصِيرُ
Tí wọ́n bá sì gbúnrí (kúrò nínú ìgbàgbọ́), ẹ mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Aláfẹ̀yìntì yín. Ó dára ní Aláfẹ̀yìntì. Ó sì dára ní Alárànṣe.

41 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 041

۞وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّمَا غَنِمۡتُم مِّن شَيۡءٖ فَأَنَّ لِلَّهِ خُمُسَهُۥ وَلِلرَّسُولِ وَلِذِي ٱلۡقُرۡبَىٰ وَٱلۡيَتَٰمَىٰ وَٱلۡمَسَٰكِينِ وَٱبۡنِ ٱلسَّبِيلِ إِن كُنتُمۡ ءَامَنتُم بِٱللَّهِ وَمَآ أَنزَلۡنَا عَلَىٰ عَبۡدِنَا يَوۡمَ ٱلۡفُرۡقَانِ يَوۡمَ ٱلۡتَقَى ٱلۡجَمۡعَانِۗ وَٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٌ
Ẹ mọ̀ pé ohunkóhun tí ẹ bá kó ní ọrọ̀ ogun, dájúdájú ti Allāhu ni ìdá márùn-ún rẹ̀. Ó sì wà fún Òjíṣẹ́ àti ẹbí (rẹ̀) àti àwọn ọmọ òrukàn, àwọn mẹ̀kúnnù àti onírìn-àjò (tí agara dá), tí ẹ bá jẹ́ ẹni tó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti n̄ǹkan tí A sọ̀kalẹ̀ fún ẹrúsìn Wa ní Ọjọ́ ìpínyà, ọjọ́ tí ìjọ méjì pàdé (lójú ogun Badr). Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.

42 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 042

إِذۡ أَنتُم بِٱلۡعُدۡوَةِ ٱلدُّنۡيَا وَهُم بِٱلۡعُدۡوَةِ ٱلۡقُصۡوَىٰ وَٱلرَّكۡبُ أَسۡفَلَ مِنكُمۡۚ وَلَوۡ تَوَاعَدتُّمۡ لَٱخۡتَلَفۡتُمۡ فِي ٱلۡمِيعَٰدِ وَلَٰكِن لِّيَقۡضِيَ ٱللَّهُ أَمۡرٗا كَانَ مَفۡعُولٗا لِّيَهۡلِكَ مَنۡ هَلَكَ عَنۢ بَيِّنَةٖ وَيَحۡيَىٰ مَنۡ حَيَّ عَنۢ بَيِّنَةٖۗ وَإِنَّ ٱللَّهَ لَسَمِيعٌ عَلِيمٌ
(Ẹ rántí) nígbà tí ẹ̀yin wà ní etí kòtò tó súnmọ́ (ìlú Mọdīnah), àwọn (kèfèrí) sì wà ní etí kòtò tó jìnnà sí (ìlú Mọdīnah), àwọn kèfèrí kan tó ń gun n̄ǹkan ìgùn (bọ̀ láti ìrìn-àjò òkòwò), wọ́n sì wà ní ìsàlẹ̀ ọ̀dọ̀ tiyín. Tí ó bá jẹ́ pé ẹ̀yin àti àwọn kèfèrí jọ mú ọjọ́ fún ogun náà ni, ẹ̀yin ìbá yapa àdéhùn náà, ṣùgbọ́n (ogun náà ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀) nítorí kí Allāhu lè mú ọ̀rọ̀ kan tí ó gbọ́dọ̀ ṣẹ wá sí ìmúṣẹ; nítorí kí ẹni tí ó máa parun (sínú àìgbàgbọ́) lè parun nípasẹ̀ ẹ̀rí tó yanjú, kí ẹni tó sì máa yè (nínú ìgbàgbọ́ òdodo) lè yè nípasẹ̀ ẹ̀rí tó yanjú. Àti pé dájúdájú Allāhu kúkú ni Olùgbọ́, Onímọ̀.

43 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 043

إِذۡ يُرِيكَهُمُ ٱللَّهُ فِي مَنَامِكَ قَلِيلٗاۖ وَلَوۡ أَرَىٰكَهُمۡ كَثِيرٗا لَّفَشِلۡتُمۡ وَلَتَنَٰزَعۡتُمۡ فِي ٱلۡأَمۡرِ وَلَٰكِنَّ ٱللَّهَ سَلَّمَۚ إِنَّهُۥ عَلِيمُۢ بِذَاتِ ٱلصُّدُورِ
(Rántí) nígbà tí Allāhu fi wọ́n hàn ọ́ nínú àlá rẹ (pé wọ́n) kéré. Tí ó bá jẹ́ pé Ó fi wọ́n hàn ọ́ (pé wọ́n) pọ̀ ni, ẹ̀yin ìbá ṣojo, ẹ̀yin ìbá sì ṣàríyànjiyàn nípa ọ̀rọ̀ náà. Ṣùgbọ́n Allāhu ko (yín) yọ. Dájúdájú Òun ni Onímọ̀ nípa n̄ǹkan tí ń bẹ nínú igbá-àyà ẹ̀dá.

44 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 044

وَإِذۡ يُرِيكُمُوهُمۡ إِذِ ٱلۡتَقَيۡتُمۡ فِيٓ أَعۡيُنِكُمۡ قَلِيلٗا وَيُقَلِّلُكُمۡ فِيٓ أَعۡيُنِهِمۡ لِيَقۡضِيَ ٱللَّهُ أَمۡرٗا كَانَ مَفۡعُولٗاۗ وَإِلَى ٱللَّهِ تُرۡجَعُ ٱلۡأُمُورُ
(Rántí) nígbà tí Ó ń fi wọ́n hàn yín pé wọ́n kéré lójú yín - nígbà tí ẹ pàdé (lójú ogun) - Ó sì mú ẹ̀yin náà kéré lójú tiwọn náà, nítorí kí Allāhu lè mú ọ̀rọ̀ kan tí ó gbọ́dọ̀ ṣẹ wá sí ìmúṣẹ. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni wọ́n máa ṣẹ́rí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá padà sí.

45 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 045

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِذَا لَقِيتُمۡ فِئَةٗ فَٱثۡبُتُواْ وَٱذۡكُرُواْ ٱللَّهَ كَثِيرٗا لَّعَلَّكُمۡ تُفۡلِحُونَ
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí ẹ bá pàdé ìjọ (ogun) kan, ẹ dúró ṣinṣin, kí ẹ sì ṣe (gbólóhùn) ìrántí Allāhu ní (òǹkà) púpọ̀ nítorí kí ẹ lè jèrè.

46 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 046

وَأَطِيعُواْ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ وَلَا تَنَٰزَعُواْ فَتَفۡشَلُواْ وَتَذۡهَبَ رِيحُكُمۡۖ وَٱصۡبِرُوٓاْۚ إِنَّ ٱللَّهَ مَعَ ٱلصَّـٰبِرِينَ
Ẹ tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ẹ má ṣe jara yín níyàn (nípa ogun ẹ̀sìn) nítorí kí ẹ má baà ṣojo àti nítorí kí agbára yín má baà kúrò lọ́wọ́ yín. Ẹ ṣe sùúrù, dájúdájú Allāhu wà pẹ̀lú àwọn onísùúrù.

47 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 047

وَلَا تَكُونُواْ كَٱلَّذِينَ خَرَجُواْ مِن دِيَٰرِهِم بَطَرٗا وَرِئَآءَ ٱلنَّاسِ وَيَصُدُّونَ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِۚ وَٱللَّهُ بِمَا يَعۡمَلُونَ مُحِيطٞ
Ẹ má ṣe dà bí àwọn tó jáde kúrò nínú ilé wọn pẹ̀lú fáààrí àti ṣekárími. Wọ́n sì ń ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

48 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 048

وَإِذۡ زَيَّنَ لَهُمُ ٱلشَّيۡطَٰنُ أَعۡمَٰلَهُمۡ وَقَالَ لَا غَالِبَ لَكُمُ ٱلۡيَوۡمَ مِنَ ٱلنَّاسِ وَإِنِّي جَارٞ لَّكُمۡۖ فَلَمَّا تَرَآءَتِ ٱلۡفِئَتَانِ نَكَصَ عَلَىٰ عَقِبَيۡهِ وَقَالَ إِنِّي بَرِيٓءٞ مِّنكُمۡ إِنِّيٓ أَرَىٰ مَا لَا تَرَوۡنَ إِنِّيٓ أَخَافُ ٱللَّهَۚ وَٱللَّهُ شَدِيدُ ٱلۡعِقَابِ
(Rántí) nígbà tí aṣ-Ṣaetọ̄n ṣe iṣẹ́ wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn, ó sì wí pé: “Kò sí ẹni tí ó máa borí yín lónìí nínú àwọn ènìyàn. Dájúdájú èmi ni alárànṣe yín.” Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ìjọ ogun méjèèjì fojú kanra wọn, ó padà sẹ́yìn, ó fẹsẹ̀ fẹ́ẹ, ó wí pé: “Dájúdájú èmi ti yọwọ́-yọsẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ yín. Dájúdájú èmi ń rí ohun tí ẹ̀yin kò rí. Èmi ń pàyà Allāhu. Allāhu sì le níbi ìyà.”

49 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 049

إِذۡ يَقُولُ ٱلۡمُنَٰفِقُونَ وَٱلَّذِينَ فِي قُلُوبِهِم مَّرَضٌ غَرَّ هَـٰٓؤُلَآءِ دِينُهُمۡۗ وَمَن يَتَوَكَّلۡ عَلَى ٱللَّهِ فَإِنَّ ٱللَّهَ عَزِيزٌ حَكِيمٞ
(Rántí) nígbà tí àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí àti àwọn tí àrùn ń bẹ nínú ọkàn wọn wí pé: “Ẹ̀sìn àwọn wọ̀nyí tàn wọ́n jẹ.” Ẹnikẹ́ni tó bá gbáralé Allāhu, dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

50 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 050

وَلَوۡ تَرَىٰٓ إِذۡ يَتَوَفَّى ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ ٱلۡمَلَـٰٓئِكَةُ يَضۡرِبُونَ وُجُوهَهُمۡ وَأَدۡبَٰرَهُمۡ وَذُوقُواْ عَذَابَ ٱلۡحَرِيقِ
Tí ó bá jẹ́ pé ìwọ rí i nígbà tí àwọn mọlāika bá ń gba ẹ̀mí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ni, tí wọ́n ń lu ojú wọn àti ẹ̀yìn wọn, (wọ́n sì máa sọ fún wọn pé), “Ẹ tọ́ ìyà Iná jónijóni wò.”

51 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 051

ذَٰلِكَ بِمَا قَدَّمَتۡ أَيۡدِيكُمۡ وَأَنَّ ٱللَّهَ لَيۡسَ بِظَلَّـٰمٖ لِّلۡعَبِيدِ
Ìyẹn nítorí ohun tí ọwọ́ yín tì ṣíwájú. Àti pé dájúdájú Allāhu kò níí ṣe àbòsí fún àwọn ẹrú (Rẹ̀).

52 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 052

كَدَأۡبِ ءَالِ فِرۡعَوۡنَ وَٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡۚ كَفَرُواْ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ فَأَخَذَهُمُ ٱللَّهُ بِذُنُوبِهِمۡۚ إِنَّ ٱللَّهَ قَوِيّٞ شَدِيدُ ٱلۡعِقَابِ
(Ìṣesí àwọn aláìgbàgbọ́) dà bí ìṣesí àwọn ènìyàn Fir‘aon àti àwọn tó ṣíwájú wọn - wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu. - Nítorí náà, Allāhu (fi ọwọ́ ìyà) mú wọn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Ó le níbi ìyà.

53 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 053

ذَٰلِكَ بِأَنَّ ٱللَّهَ لَمۡ يَكُ مُغَيِّرٗا نِّعۡمَةً أَنۡعَمَهَا عَلَىٰ قَوۡمٍ حَتَّىٰ يُغَيِّرُواْ مَا بِأَنفُسِهِمۡ وَأَنَّ ٱللَّهَ سَمِيعٌ عَلِيمٞ
Ìyẹn nítorí pé dájúdájú Allāhu kò níí ṣe ìyípadà ìdẹ̀ra tí Ó ṣe fún ìjọ kan títí wọn yóò fi ṣe ìyípadà n̄ǹkan tí ń bẹ lọ́dọ̀ ara wọn. Dájúdájú Allāhu sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.

54 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 054

كَدَأۡبِ ءَالِ فِرۡعَوۡنَ وَٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡۚ كَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِ رَبِّهِمۡ فَأَهۡلَكۡنَٰهُم بِذُنُوبِهِمۡ وَأَغۡرَقۡنَآ ءَالَ فِرۡعَوۡنَۚ وَكُلّٞ كَانُواْ ظَٰلِمِينَ
(Ìṣesí àwọn aláìmoore) dà bí ìṣesí àwọn ènìyàn Fir‘aon àti àwọn tó ṣíwájú wọn, tí wọ́n pe àwọn āyah Olúwa wọn nírọ́. Nítorí náà, A pa wọ́n run nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn; A sì tẹ àwọn ènìyàn Fir‘aon rì sínú agbami. Gbogbo wọn sì jẹ́ alábòsí.

55 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 055

إِنَّ شَرَّ ٱلدَّوَآبِّ عِندَ ٱللَّهِ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ فَهُمۡ لَا يُؤۡمِنُونَ
Dájúdájú ẹ̀dá abẹ̀mí tó burú jùlọ lọ́dọ̀ Allāhu ni àwọn tó ṣàì gbàgbọ́. Nítorí náà, wọn kò níí gbàgbọ́.

56 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 056

ٱلَّذِينَ عَٰهَدتَّ مِنۡهُمۡ ثُمَّ يَنقُضُونَ عَهۡدَهُمۡ فِي كُلِّ مَرَّةٖ وَهُمۡ لَا يَتَّقُونَ
Àwọn tí o bá ṣe àdéhùn nínú wọn, lẹ́yìn náà tí wọ́n ń tú àdéhùn wọn ní gbogbo ìgbà, tí wọn kò sì bẹ̀rù (Allāhu),

57 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 057

فَإِمَّا تَثۡقَفَنَّهُمۡ فِي ٱلۡحَرۡبِ فَشَرِّدۡ بِهِم مَّنۡ خَلۡفَهُمۡ لَعَلَّهُمۡ يَذَّكَّرُونَ
yálà tí ọwọ́ yín bá bà wọ́n lójú ogun, (ẹ fi ìyà tó le koko jẹ wọ́n,) kí ẹ lè (fi ìbẹ̀rù ìyà naa) tú àwọn ọmọlẹ́yìn wọn ká nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí;

58 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 058

وَإِمَّا تَخَافَنَّ مِن قَوۡمٍ خِيَانَةٗ فَٱنۢبِذۡ إِلَيۡهِمۡ عَلَىٰ سَوَآءٍۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يُحِبُّ ٱلۡخَآئِنِينَ
tàbí tí o bá sì ń páyà ìwà ìjàǹbá láti ọ̀dọ̀ ìjọ kan, ju àdéhùn wọn sílẹ̀ fún wọn kí ẹ dì jọ mọ̀ pé kò sí àdéhùn kan kan mọ́ láààrin ẹ̀yin méjèèjì. Dájúdájú Allāhu kò nífẹ̀ẹ́ àwọn oníjàǹbá.

59 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 059

وَلَا يَحۡسَبَنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ سَبَقُوٓاْۚ إِنَّهُمۡ لَا يُعۡجِزُونَ
Kí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ má ṣe lérò pé àwọn ti gbawájú. Dájúdájú wọn kò lè mórí bọ́ (nínú ìyà).

60 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 060

وَأَعِدُّواْ لَهُم مَّا ٱسۡتَطَعۡتُم مِّن قُوَّةٖ وَمِن رِّبَاطِ ٱلۡخَيۡلِ تُرۡهِبُونَ بِهِۦ عَدُوَّ ٱللَّهِ وَعَدُوَّكُمۡ وَءَاخَرِينَ مِن دُونِهِمۡ لَا تَعۡلَمُونَهُمُ ٱللَّهُ يَعۡلَمُهُمۡۚ وَمَا تُنفِقُواْ مِن شَيۡءٖ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ يُوَفَّ إِلَيۡكُمۡ وَأَنتُمۡ لَا تُظۡلَمُونَ
Ẹ pèsè sílẹ̀ dè wọ́n n̄ǹkan ìjà tí agbára yín ká nínú n̄ǹkan àmúṣagbára àti àwọn ẹṣin orí ìso, tí ẹ̀yin yóò fi máa dẹ́rù ba ọ̀tá Allāhu àti ọ̀tá yín pẹ̀lú àwọn mìíràn yàtọ̀ sí wọn, tí ẹ̀yin kò mọ̀ wọ́n – Allāhu sì mọ̀ wọ́n. – Ohunkóhun tí ẹ bá ná lójú ọ̀nà Allāhu (fún ogun ẹ̀sìn), A óò san án padà fún yín ní kíkún; A ò sì níí ṣe àbòsí fún yín.

61 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 061

۞وَإِن جَنَحُواْ لِلسَّلۡمِ فَٱجۡنَحۡ لَهَا وَتَوَكَّلۡ عَلَى ٱللَّهِۚ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡعَلِيمُ
Tí wọ́n bá tẹ̀ síbi (ètò) àlàáfíà (fún dídá ogun dúró), ìwọ náà tẹ̀ síbẹ̀, kí o sì gbáralé Allāhu. Dájúdájú Òun mà ni Olùgbọ́, Onímọ̀.

62 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 062

وَإِن يُرِيدُوٓاْ أَن يَخۡدَعُوكَ فَإِنَّ حَسۡبَكَ ٱللَّهُۚ هُوَ ٱلَّذِيٓ أَيَّدَكَ بِنَصۡرِهِۦ وَبِٱلۡمُؤۡمِنِينَ
Tí wọ́n bá tún fẹ́ tàn ọ́ jẹ, dájúdájú Allāhu á tó ọ. Òun ni Ẹni tí Ó fi àrànṣe Rẹ̀ àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo ràn ọ́ lọ́wọ́.

63 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 063

وَأَلَّفَ بَيۡنَ قُلُوبِهِمۡۚ لَوۡ أَنفَقۡتَ مَا فِي ٱلۡأَرۡضِ جَمِيعٗا مَّآ أَلَّفۡتَ بَيۡنَ قُلُوبِهِمۡ وَلَٰكِنَّ ٱللَّهَ أَلَّفَ بَيۡنَهُمۡۚ إِنَّهُۥ عَزِيزٌ حَكِيمٞ
Allāhu pa ọkàn wọn pọ̀ mọ́ra wọn. Tí ó bá jẹ́ pé o ná gbogbo n̄ǹkan tí ń bẹ lórí ilẹ̀ pátápátá, ìwọ kò lè pa ọkàn wọn pọ̀ mọ́ra wọn. Ṣùgbọ́n Allāhu pa ọkàn wọn pọ̀ mọ́ra wọn, dájúdájú Òun ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

64 - Al-Anfal (The Spoils of War) - 0

Scroll to Top