النساء
An-Nisa
The Women
1 - An-Nisa (The Women) - 001
يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ ٱتَّقُواْ رَبَّكُمُ ٱلَّذِي خَلَقَكُم مِّن نَّفۡسٖ وَٰحِدَةٖ وَخَلَقَ مِنۡهَا زَوۡجَهَا وَبَثَّ مِنۡهُمَا رِجَالٗا كَثِيرٗا وَنِسَآءٗۚ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ ٱلَّذِي تَسَآءَلُونَ بِهِۦ وَٱلۡأَرۡحَامَۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلَيۡكُمۡ رَقِيبٗا
Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ bẹ̀rù Olúwa yín, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín láti ara ẹ̀mí ẹyọ kan (ìyẹn, Ànábì Ādam). Ó sì ṣẹ̀dá aya rẹ̀ (Hawā’) láti ara rẹ̀. Ó fọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọkùnrin àti obìnrin jáde láti ara àwọn méjèèjì. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu, Ẹni tí ẹ̀ ń fi bẹ ara yín. (Ẹ ṣọ́) okùn-ìbí. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Olùṣọ́ lórí yín.
2 - An-Nisa (The Women) - 002
وَءَاتُواْ ٱلۡيَتَٰمَىٰٓ أَمۡوَٰلَهُمۡۖ وَلَا تَتَبَدَّلُواْ ٱلۡخَبِيثَ بِٱلطَّيِّبِۖ وَلَا تَأۡكُلُوٓاْ أَمۡوَٰلَهُمۡ إِلَىٰٓ أَمۡوَٰلِكُمۡۚ إِنَّهُۥ كَانَ حُوبٗا كَبِيرٗا
Ẹ fún àwọn ọmọ òrukàn ní dúkìá wọn.[1] Ẹ má ṣe fi n̄ǹkan dáadáa pààrọ̀ n̄ǹkan burúkú.² Ẹ sì má ṣe jẹ dúkìá wọn mọ́ dúkìá yín; dájúdájú ó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó tóbi.
1. Ìyẹn nígbà tí ọmọ òrukàn bá bàlágà, tí ó sì ní òye àmójútó dúkìá náà fúnra rẹ̀. 2. Bí àpẹ̀ẹrẹ, èyí ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí alágbàtọ́ ọmọ-òrukàn bá fi dúkìá kan tó dára nínú àwọn dúkìá ọmọ òrukàn pààrọ̀ dúkìá tirẹ̀ tí kò dára mọ́ ọn lọ́wọ́. Allāhu sì ṣe ìṣesí yìí ní èèwọ̀.
3 - An-Nisa (The Women) - 003
وَإِنۡ خِفۡتُمۡ أَلَّا تُقۡسِطُواْ فِي ٱلۡيَتَٰمَىٰ فَٱنكِحُواْ مَا طَابَ لَكُم مِّنَ ٱلنِّسَآءِ مَثۡنَىٰ وَثُلَٰثَ وَرُبَٰعَۖ فَإِنۡ خِفۡتُمۡ أَلَّا تَعۡدِلُواْ فَوَٰحِدَةً أَوۡ مَا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُكُمۡۚ ذَٰلِكَ أَدۡنَىٰٓ أَلَّا تَعُولُواْ
Tí ẹ bá páyà pé ẹ ò níí ṣe déédé nípa (fífẹ́) ọmọ òrukàn,[1] ẹ fẹ́ ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ si yín nínú àwọn obìnrin; méjì tàbí mẹ́ta tàbí mẹ́rin.² Ṣùgbọ́n tí ẹ bá páyà pé ẹ ò níí ṣe déédé, (ẹ fẹ́) ẹyọ kan tàbí ẹrúbìnrin yín. Ìyẹn súnmọ́ jùlọ pé ẹ ò níí ṣàbòsí.
1. Bí àpẹ̀ẹrẹ, kí ẹni tí ó ń mójútó ọmọ òrukàn obìnrin nífẹ̀ẹ́ láti fẹ́ ọmọbìnrin náà lẹ́yìn tí ó bàlágà tán, àmọ́ ọkùnrin náà kọ̀ láti fún un ní sọ̀daàkí rẹ̀ nítorí pé, ó mọ bí ogún ọmọbìnrin náà ṣe tó ní iye. 2. Láti ọ̀dọ̀ ọmọ Ṣihāb, dájúdájú ó gbọ́ pé dájúdájú Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sọ fún ọkùnrin kan láti ìdìlé Thaƙīf tí ó gba ’Islām, tí ìyàwó rẹ̀ sì jẹ́ mẹ́wàá ní àsìkò tí ó gba ’Islām pé, “Mú mẹ́rin nínú wọn, kí o sì kọ àwọn yòókù sílẹ̀.” (Muwattọ’u Imām Mọ̄lik, Musnad Ṣāfi‘iy, Sunan Baehaƙiy àti Sọhīhu bn Hibbān)
4 - An-Nisa (The Women) - 004
وَءَاتُواْ ٱلنِّسَآءَ صَدُقَٰتِهِنَّ نِحۡلَةٗۚ فَإِن طِبۡنَ لَكُمۡ عَن شَيۡءٖ مِّنۡهُ نَفۡسٗا فَكُلُوهُ هَنِيٓـٔٗا مَّرِيٓـٔٗا
Ẹ fún àwọn obìnrin ní sọ̀daàkí wọn tó jẹ́ ọ̀ran-anyàn ní tọkàn-tọkàn. Tí wọ́n bá sì fi inú dídùn yọ̀ǹda kiní kan fún yín nínú rẹ̀, ẹ jẹ ẹ́ pẹ̀lú ìrọ̀rùn àti ìgbádùn.
5 - An-Nisa (The Women) - 005
وَلَا تُؤۡتُواْ ٱلسُّفَهَآءَ أَمۡوَٰلَكُمُ ٱلَّتِي جَعَلَ ٱللَّهُ لَكُمۡ قِيَٰمٗا وَٱرۡزُقُوهُمۡ فِيهَا وَٱكۡسُوهُمۡ وَقُولُواْ لَهُمۡ قَوۡلٗا مَّعۡرُوفٗا
Ẹ má ṣe kó dúkìá yín tí Allāhu fí ṣe gbẹ́mìíró fún yín lé àwọn aláìlóye lọ́wọ́. Ẹ pèsè ìjẹ-ìmu fún wọn nínú rẹ̀, kí ẹ sì raṣọ fún wọn. Kí ẹ sì máa sọ̀rọ̀ dáadáa fún wọn.
6 - An-Nisa (The Women) - 006
وَٱبۡتَلُواْ ٱلۡيَتَٰمَىٰ حَتَّىٰٓ إِذَا بَلَغُواْ ٱلنِّكَاحَ فَإِنۡ ءَانَسۡتُم مِّنۡهُمۡ رُشۡدٗا فَٱدۡفَعُوٓاْ إِلَيۡهِمۡ أَمۡوَٰلَهُمۡۖ وَلَا تَأۡكُلُوهَآ إِسۡرَافٗا وَبِدَارًا أَن يَكۡبَرُواْۚ وَمَن كَانَ غَنِيّٗا فَلۡيَسۡتَعۡفِفۡۖ وَمَن كَانَ فَقِيرٗا فَلۡيَأۡكُلۡ بِٱلۡمَعۡرُوفِۚ فَإِذَا دَفَعۡتُمۡ إِلَيۡهِمۡ أَمۡوَٰلَهُمۡ فَأَشۡهِدُواْ عَلَيۡهِمۡۚ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ حَسِيبٗا
Ẹ dán àwọn ọmọ òrukàn wò[1] títí wọn yóò fi dàgbà wọ ẹni tí ò lè ṣe ìgbéyàwó.² Tí ẹ bá sì ti rí òye lára wọn, kí ẹ dá dúkìá wọn padà fún wọn. Ẹ ò gbọdọ̀ jẹ dúkìá wọn ní ìjẹ àpà àti ìjẹkújẹ kí wọ́n tó dàgbà. Ẹni tí ó bá jẹ́ ọlọ́rọ̀, kí ó mójú kúrò (níbẹ̀). Ẹni tí ó bá jẹ́ aláìní, kí ó jẹ nínú rẹ̀ ní ọ̀nà tó dára. Nítorí náà, tí ẹ bá fẹ́ dá dúkìá wọn padà fún wọn, ẹ pe àwọn ẹlẹ́rìí sí wọn. Allāhu sì tó ní Olùṣírò.
1. Ìyẹn ni pé, ẹ kọ́kọ́ fi díẹ̀ tó kéré gan-an lé e lọ́wọ́ nínú ogún rẹ̀ tó jẹ́ ohun àmúṣọrọ̀, kí ẹ wo bí ó ṣe máa ṣe àmójútó rẹ̀. 2. “eni tí ó lè ṣe ìgbéyàwó” ni ẹni tí ó ti di ọmọkùnrin tàbí ẹni tí ó ti di ọmọbìnrin ẹni tí “ó ti bàlágà”.
7 - An-Nisa (The Women) - 007
لِّلرِّجَالِ نَصِيبٞ مِّمَّا تَرَكَ ٱلۡوَٰلِدَانِ وَٱلۡأَقۡرَبُونَ وَلِلنِّسَآءِ نَصِيبٞ مِّمَّا تَرَكَ ٱلۡوَٰلِدَانِ وَٱلۡأَقۡرَبُونَ مِمَّا قَلَّ مِنۡهُ أَوۡ كَثُرَۚ نَصِيبٗا مَّفۡرُوضٗا
Àwọn ọkùnrin ní ìpín nínú ohun tí òbí méjèèjì àti ẹbí fi sílẹ̀. Àti pé àwọn obìnrin náà ní ìpín nínú ohun tí òbí méjéèjì àti ẹbí fi sílẹ̀. Nínú ohun tó kéré nínú rẹ̀ tàbí tó pọ̀; (ó jẹ́) ìpín tí wọ́n ti pín (tí wọ́n ti ṣàdáyanrí rẹ̀ fún wọn).
8 - An-Nisa (The Women) - 008
وَإِذَا حَضَرَ ٱلۡقِسۡمَةَ أُوْلُواْ ٱلۡقُرۡبَىٰ وَٱلۡيَتَٰمَىٰ وَٱلۡمَسَٰكِينُ فَٱرۡزُقُوهُم مِّنۡهُ وَقُولُواْ لَهُمۡ قَوۡلٗا مَّعۡرُوفٗا
Nígbà tí àwọn ẹbí, àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn mẹ̀kúnnù bá wà ní (ìjókòó) ogún pípín, ẹ fún wọn nínú rẹ̀ (ṣíwájú kí ẹ tó pín ogún), kí ẹ sì sọ̀rọ̀ dáadáa fún wọn.
9 - An-Nisa (The Women) - 009
وَلۡيَخۡشَ ٱلَّذِينَ لَوۡ تَرَكُواْ مِنۡ خَلۡفِهِمۡ ذُرِّيَّةٗ ضِعَٰفًا خَافُواْ عَلَيۡهِمۡ فَلۡيَتَّقُواْ ٱللَّهَ وَلۡيَقُولُواْ قَوۡلٗا سَدِيدًا
Àwọn (olùpíngún àti alágbàwò-ọmọ-òrukàn) tí ó bá jẹ́ pé àwọn náà máa fi ọmọ wẹ́wẹ́ sílẹ̀, tí wọ́n sì ń páyà lórí wọn, kí wọ́n yáa bẹ̀rù Allāhu. Kí wọ́n sì máa sọ̀rọ̀ dáadáa (fún ọmọ òrukàn).
10 - An-Nisa (The Women) - 010
إِنَّ ٱلَّذِينَ يَأۡكُلُونَ أَمۡوَٰلَ ٱلۡيَتَٰمَىٰ ظُلۡمًا إِنَّمَا يَأۡكُلُونَ فِي بُطُونِهِمۡ نَارٗاۖ وَسَيَصۡلَوۡنَ سَعِيرٗا
Dájúdájú àwọn tó ń jẹ dúkìá ọmọ òrukàn pẹ̀lú àbòsí, Iná kúkú ni wọ́n ń jẹ sínú ikùn wọn. Wọ́n sì máa wọ inú Iná tó ń jó.
11 - An-Nisa (The Women) - 011
يُوصِيكُمُ ٱللَّهُ فِيٓ أَوۡلَٰدِكُمۡۖ لِلذَّكَرِ مِثۡلُ حَظِّ ٱلۡأُنثَيَيۡنِۚ فَإِن كُنَّ نِسَآءٗ فَوۡقَ ٱثۡنَتَيۡنِ فَلَهُنَّ ثُلُثَا مَا تَرَكَۖ وَإِن كَانَتۡ وَٰحِدَةٗ فَلَهَا ٱلنِّصۡفُۚ وَلِأَبَوَيۡهِ لِكُلِّ وَٰحِدٖ مِّنۡهُمَا ٱلسُّدُسُ مِمَّا تَرَكَ إِن كَانَ لَهُۥ وَلَدٞۚ فَإِن لَّمۡ يَكُن لَّهُۥ وَلَدٞ وَوَرِثَهُۥٓ أَبَوَاهُ فَلِأُمِّهِ ٱلثُّلُثُۚ فَإِن كَانَ لَهُۥٓ إِخۡوَةٞ فَلِأُمِّهِ ٱلسُّدُسُۚ مِنۢ بَعۡدِ وَصِيَّةٖ يُوصِي بِهَآ أَوۡ دَيۡنٍۗ ءَابَآؤُكُمۡ وَأَبۡنَآؤُكُمۡ لَا تَدۡرُونَ أَيُّهُمۡ أَقۡرَبُ لَكُمۡ نَفۡعٗاۚ فَرِيضَةٗ مِّنَ ٱللَّهِۗ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلِيمًا حَكِيمٗا
Allāhu ń sọ àsọọ́lẹ̀ (òfin) fún yín nípa (ogún tí ẹ máa pín fún) àwọn ọmọ yín; ti ọkùnrin ni irú ìpín ti obìnrin méjì. Tí wọ́n bá sì jẹ́ obìnrin (nìkan), méjì sókè, tiwọn ni ìdá méjì nínú ìdá mẹ́ta ohun tí (òkú) fi sílẹ̀. Tí ó bá jẹ́ obìnrin kan ṣoṣo, ìdajì ni tirẹ̀. Ti òbí rẹ̀ méjèèjì, ìdá kan nínú ìdá mẹ́fà ni ti ìkọ̀ọ̀kan àwọn méjèèjì nínú ohun tí òkú fi sílẹ̀, tí ó bá ní ọmọ láyé. Tí kò bá sì ní ọmọ láyé, tí ó sì jẹ́ pé àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì l’ó máa jogún rẹ̀, ìdá kan nínú ìdá mẹ́ta ni ti ìyá rẹ̀. Tí ó bá ní arákùnrin (tàbí arábìnrin), ìdá kan nínú ìdá mẹ́fà ni ti ìyá rẹ̀, lẹ́yìn àsọọ́lẹ̀ tí ó sọ tàbí gbèsè. Àwọn bàbá yín àti àwọn ọmọkùnrin yín; ẹ̀yin kò mọ èwo nínú wọn ló máa mú àǹfààní ba yín jùlọ. (Ìpín) ọ̀ran-anyàn ni láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
12 - An-Nisa (The Women) - 012
۞وَلَكُمۡ نِصۡفُ مَا تَرَكَ أَزۡوَٰجُكُمۡ إِن لَّمۡ يَكُن لَّهُنَّ وَلَدٞۚ فَإِن كَانَ لَهُنَّ وَلَدٞ فَلَكُمُ ٱلرُّبُعُ مِمَّا تَرَكۡنَۚ مِنۢ بَعۡدِ وَصِيَّةٖ يُوصِينَ بِهَآ أَوۡ دَيۡنٖۚ وَلَهُنَّ ٱلرُّبُعُ مِمَّا تَرَكۡتُمۡ إِن لَّمۡ يَكُن لَّكُمۡ وَلَدٞۚ فَإِن كَانَ لَكُمۡ وَلَدٞ فَلَهُنَّ ٱلثُّمُنُ مِمَّا تَرَكۡتُمۚ مِّنۢ بَعۡدِ وَصِيَّةٖ تُوصُونَ بِهَآ أَوۡ دَيۡنٖۗ وَإِن كَانَ رَجُلٞ يُورَثُ كَلَٰلَةً أَوِ ٱمۡرَأَةٞ وَلَهُۥٓ أَخٌ أَوۡ أُخۡتٞ فَلِكُلِّ وَٰحِدٖ مِّنۡهُمَا ٱلسُّدُسُۚ فَإِن كَانُوٓاْ أَكۡثَرَ مِن ذَٰلِكَ فَهُمۡ شُرَكَآءُ فِي ٱلثُّلُثِۚ مِنۢ بَعۡدِ وَصِيَّةٖ يُوصَىٰ بِهَآ أَوۡ دَيۡنٍ غَيۡرَ مُضَآرّٖۚ وَصِيَّةٗ مِّنَ ٱللَّهِۗ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَلِيمٞ
Tiyín ni ìlàjì ohun tí àwọn ìyàwó yín fi sílẹ̀, tí wọn kò bá ní ọmọ. Tí wọ́n bá sì ní ọmọ, tiyín ni ìdá kan nínú ìdá mẹ́rin ohun tí wọ́n fi sílẹ̀, lẹ́yìn àsọọ́lẹ̀ tí wọ́n sọ tàbí gbèsè. Tiwọn sì ni ìdá kan nínú ìdá mẹ́rin ohun tí ẹ fi sílẹ̀, tí ẹ̀yin kò bá ní ọmọ láyé. Tí ẹ bá ní ọmọ láyé, ìdá kan nínú ìdá mẹ́jọ ni tiwọn nínú ohun tí ẹ fi sílẹ̀ lẹ́yìn àsọọ́lẹ̀ tí ẹ sọ tàbí gbèsè. Tí ọkùnrin kan tàbí obìnrin kan tí wọ́n fẹ́ jogún rẹ̀ kò bá ní òbí àti ọmọ, tí ó sì ní arákùnrin kan tàbí arábìnrin kan, ìdá kan nínú ìdá mẹ́fà ni ti ìkọ̀ọ̀kan àwọn méjèèjì. Tí wọ́n bá sì pọ̀ ju bẹ́ẹ̀ lọ, wọn yóò dìjọ pín ìdá kan nínú ìdá mẹ́ta, lẹ́yìn àsọọ́lẹ̀ tí wọ́n sọ tàbí gbèsè, tí kò níí jẹ́ ìpalára. Àsọọ́lẹ̀ (òfin) kan ni láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Allāhu sì ni Onímọ̀, Aláfaradà.
13 - An-Nisa (The Women) - 013
تِلۡكَ حُدُودُ ٱللَّهِۚ وَمَن يُطِعِ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ يُدۡخِلۡهُ جَنَّـٰتٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَاۚ وَذَٰلِكَ ٱلۡفَوۡزُ ٱلۡعَظِيمُ
Ìyẹn ni àwọn ẹnu-ààlà (tí) Allāhu (gbékalẹ̀ fún ogún pípín). Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, (Allāhu) yóò mú un wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ ńlá.
14 - An-Nisa (The Women) - 014
وَمَن يَعۡصِ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ وَيَتَعَدَّ حُدُودَهُۥ يُدۡخِلۡهُ نَارًا خَٰلِدٗا فِيهَا وَلَهُۥ عَذَابٞ مُّهِينٞ
Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì yapa (àṣẹ) Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, tí ó sì ń tayọ àwọn ẹnu-ààlà tí Allāhu gbékalẹ̀, (Allāhu) yóò mú un wọ inú Iná kan. Olùṣegbére ni nínú rẹ̀. Ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá sì ń bẹ fún un.[1]
1. Kò bá òfin ’Islām mu láti pín ogún ara ẹni sílẹ̀. Àti pé bí ènìyàn kò bá tí ì kú, dúkìá rẹ̀ kò ì di ogún fún ẹnì kan kan.
15 - An-Nisa (The Women) - 015
وَٱلَّـٰتِي يَأۡتِينَ ٱلۡفَٰحِشَةَ مِن نِّسَآئِكُمۡ فَٱسۡتَشۡهِدُواْ عَلَيۡهِنَّ أَرۡبَعَةٗ مِّنكُمۡۖ فَإِن شَهِدُواْ فَأَمۡسِكُوهُنَّ فِي ٱلۡبُيُوتِ حَتَّىٰ يَتَوَفَّىٰهُنَّ ٱلۡمَوۡتُ أَوۡ يَجۡعَلَ ٱللَّهُ لَهُنَّ سَبِيلٗا
Àwọn tó ń ṣe sìná nínú àwọn obìnrin yín, ẹ wá ẹlẹ́rìí mẹ́rin nínú yín tí ó máa jẹ́rìí lé wọn lórí. Tí wọ́n bá jẹ́rìí lé wọn lórí, kí ẹ dè wọ́n mọ́ inú ilé títí ikú yóò fi pa wọ́n tàbí (títí) Allāhu yóò fi gbé ọ̀nà (ìjìyà) kan kalẹ̀ fún wọn.[1]
1. Èyí ni òfin àkọ́kọ́ lórí ìdíyàjẹ onísìná obìnrin tó ti ní yìgì lórí rí. Lẹ́yìn náà, òfin lílẹ onísìná lókò pa dé lórí ẹni tí ó bá ṣe sìná lẹ́yìn tí ó ti ṣe nikāh rí, yálà obìnrin tàbí ọkùnrin.
16 - An-Nisa (The Women) - 016
وَٱلَّذَانِ يَأۡتِيَٰنِهَا مِنكُمۡ فَـَٔاذُوهُمَاۖ فَإِن تَابَا وَأَصۡلَحَا فَأَعۡرِضُواْ عَنۡهُمَآۗ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ تَوَّابٗا رَّحِيمًا
Àwọn méjì tí wọ́n ṣe sìná nínú yín, kí ẹ (fi ẹnu tàbí ọwọ́) bá wọn wí.[1] Tí wọ́n bá sì ronú pìwàdà, tí wọ́n ṣàtúnṣe, kí ẹ mójú kúrò lára wọn. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́- ọ̀run.
1. Wọ́n ti fi sūrah an-Nūr; 24:2 pa ìdájọ́ āyah yìí rẹ̀ nítorí pé, āyah méjèèjì dálé ìjìyà fún onísìná tí kò ì ṣe ìgbéyàwó rí.
17 - An-Nisa (The Women) - 017
إِنَّمَا ٱلتَّوۡبَةُ عَلَى ٱللَّهِ لِلَّذِينَ يَعۡمَلُونَ ٱلسُّوٓءَ بِجَهَٰلَةٖ ثُمَّ يَتُوبُونَ مِن قَرِيبٖ فَأُوْلَـٰٓئِكَ يَتُوبُ ٱللَّهُ عَلَيۡهِمۡۗ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلِيمًا حَكِيمٗا
Ìronúpìwàdà tí Allāhu yóò gbà ni ti àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ aburú pẹ̀lú àìmọ̀kan.[1] Lẹ́yìn náà, wọ́n ronú pìwàdà láìpẹ́ (ìyẹn ṣíwájú ọjọ́ ikú wọn). Àwọn wọ̀nyí ni Allāhu yóò gba ìronúpìwàdà wọn. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
1. Ṣíṣe aburú pẹ̀lú àìmọ̀kan ni ṣíṣe aburú nígbà tí ènìyàn kò nímọ̀ nípa ìdàjọ́ àti ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Kódà kí ènìyàn ní ìmọ̀, bí ó bá ṣiṣẹ́ aburú, kì í ṣe ìmọ̀ ló pàṣẹ aburú fún, ó ti wọ aṣọ àìmọ̀kan, ó sì ṣe aburú náà pẹ̀lú àìmọ̀kan tàbí ó ṣe aburú náà gẹ́gẹ́ bí aláìmọ̀kan.
18 - An-Nisa (The Women) - 018
وَلَيۡسَتِ ٱلتَّوۡبَةُ لِلَّذِينَ يَعۡمَلُونَ ٱلسَّيِّـَٔاتِ حَتَّىٰٓ إِذَا حَضَرَ أَحَدَهُمُ ٱلۡمَوۡتُ قَالَ إِنِّي تُبۡتُ ٱلۡـَٰٔنَ وَلَا ٱلَّذِينَ يَمُوتُونَ وَهُمۡ كُفَّارٌۚ أُوْلَـٰٓئِكَ أَعۡتَدۡنَا لَهُمۡ عَذَابًا أَلِيمٗا
Kò sí ìronúpìwàdà fún àwọn tó ń ṣe aburú títí ikú fi dé bá ọ̀kan nínú wọn, kí ó wá wí pé: “Dájúdájú èmi ronú pìwàdà nísisìnyìí.” (Kò tún sí ìronúpìwàdà) fún àwọn tó kú sípò aláìgbàgbọ́. Àwọn wọ̀nyẹn, A ti pèsè ìyà ẹlẹ́ta eléro sílẹ̀ dè wọ́n.
19 - An-Nisa (The Women) - 019
يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا يَحِلُّ لَكُمۡ أَن تَرِثُواْ ٱلنِّسَآءَ كَرۡهٗاۖ وَلَا تَعۡضُلُوهُنَّ لِتَذۡهَبُواْ بِبَعۡضِ مَآ ءَاتَيۡتُمُوهُنَّ إِلَّآ أَن يَأۡتِينَ بِفَٰحِشَةٖ مُّبَيِّنَةٖۚ وَعَاشِرُوهُنَّ بِٱلۡمَعۡرُوفِۚ فَإِن كَرِهۡتُمُوهُنَّ فَعَسَىٰٓ أَن تَكۡرَهُواْ شَيۡـٔٗا وَيَجۡعَلَ ٱللَّهُ فِيهِ خَيۡرٗا كَثِيرٗا
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, kò lẹ́tọ̀ọ́ fún yín láti jẹ àwọn obìnrin mógún pẹ̀lú ipá (bíi ṣíṣú obìnrin lópó.) Ẹ má ṣe fúnlẹ̀ mọ́ wọn nítorí kí ẹ le gba apá kan n̄ǹkan tí ẹ fún wọn àyàfi tí wọ́n bá hùwà ìbàjẹ́ tó fojú hàn. Ẹ bá wọn lòpọ̀ pẹ̀lú dáadáa. Tí ẹ bá kórira wọn, ó lè jẹ́ pé ẹ kórira kiní kan, kí Allāhu sì ti fi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ oore sínú rẹ̀.
20 - An-Nisa (The Women) - 020
وَإِنۡ أَرَدتُّمُ ٱسۡتِبۡدَالَ زَوۡجٖ مَّكَانَ زَوۡجٖ وَءَاتَيۡتُمۡ إِحۡدَىٰهُنَّ قِنطَارٗا فَلَا تَأۡخُذُواْ مِنۡهُ شَيۡـًٔاۚ أَتَأۡخُذُونَهُۥ بُهۡتَٰنٗا وَإِثۡمٗا مُّبِينٗا
Tí ẹ bá sì fẹ́ fi ìyàwó kan pààrọ̀ àyè ìyàwó kan, tí ẹ sì ti fún ọ̀kan nínú wọn ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ dúkìá, ẹ ò gbọdọ̀ gba n̄ǹkan kan nínú rẹ̀ mọ́. Ṣé ẹ̀yin yóò gbà á ní ti àdápa irọ́ (tí ẹ̀ ń pa mọ́ wọn) àti ẹ̀ṣẹ̀ tó fojú hàn(tí ẹ̀ ń dá nípa wọn)?[1]
1. Pípa irọ́ mọ́ ìyàwó ẹni àti fífi ìnira kàn án nítorí kí ó lè sọ pé òun kò ṣe mọ́, - ṣebí ọkọ kúkú ti mọ̀ pé bí ìkọ̀sílẹ̀ bá wáyé láti ọ̀dọ̀ obìnrin, èyí tí a mọ̀ sí kul‘u, ó máa dá sọ̀daàkí rẹ̀ padà fún ọkọ - ó jẹ́ ìṣesí burúkú tí āyah yìí ń ṣe ní harām.
21 - An-Nisa (The Women) - 021
وَكَيۡفَ تَأۡخُذُونَهُۥ وَقَدۡ أَفۡضَىٰ بَعۡضُكُمۡ إِلَىٰ بَعۡضٖ وَأَخَذۡنَ مِنكُم مِّيثَٰقًا غَلِيظٗا
Báwo ni ẹ̀yin ṣe lè gbà á padà nígbà tí ó jẹ́ pé ẹ ti wọlé tọ’ra yín, tí wọ́n sì ti gba àdéhùn tó nípọn lọ́wọ́ yín![1]
1. Àdéhùn tó nípọn tí ọkọ ṣe fún ìyàwó rẹ̀ ni pé, “Èmi yóò máa ṣe dáadáa pẹ̀lú rẹ̀ tàbí kí n̄g tú ọ sílẹ̀ pẹ̀lú dáadáa, ìyẹn tí ìkọ̀sílẹ̀ bá ṣẹlẹ̀.”
22 - An-Nisa (The Women) - 022
وَلَا تَنكِحُواْ مَا نَكَحَ ءَابَآؤُكُم مِّنَ ٱلنِّسَآءِ إِلَّا مَا قَدۡ سَلَفَۚ إِنَّهُۥ كَانَ فَٰحِشَةٗ وَمَقۡتٗا وَسَآءَ سَبِيلًا
Ẹ má ṣe fẹ́ ẹni tí àwọn bàbá yín ti fẹ́ nínú àwọn obìnrin àyàfi èyí tí ó ti ré kọjá. Dájúdájú ó jẹ́ ìwà ìbàjẹ́ àti ohun ìkórira. Ó sì burú ní ọ̀nà.
23 - An-Nisa (The Women) - 023
حُرِّمَتۡ عَلَيۡكُمۡ أُمَّهَٰتُكُمۡ وَبَنَاتُكُمۡ وَأَخَوَٰتُكُمۡ وَعَمَّـٰتُكُمۡ وَخَٰلَٰتُكُمۡ وَبَنَاتُ ٱلۡأَخِ وَبَنَاتُ ٱلۡأُخۡتِ وَأُمَّهَٰتُكُمُ ٱلَّـٰتِيٓ أَرۡضَعۡنَكُمۡ وَأَخَوَٰتُكُم مِّنَ ٱلرَّضَٰعَةِ وَأُمَّهَٰتُ نِسَآئِكُمۡ وَرَبَـٰٓئِبُكُمُ ٱلَّـٰتِي فِي حُجُورِكُم مِّن نِّسَآئِكُمُ ٱلَّـٰتِي دَخَلۡتُم بِهِنَّ فَإِن لَّمۡ تَكُونُواْ دَخَلۡتُم بِهِنَّ فَلَا جُنَاحَ عَلَيۡكُمۡ وَحَلَـٰٓئِلُ أَبۡنَآئِكُمُ ٱلَّذِينَ مِنۡ أَصۡلَٰبِكُمۡ وَأَن تَجۡمَعُواْ بَيۡنَ ٱلۡأُخۡتَيۡنِ إِلَّا مَا قَدۡ سَلَفَۗ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ غَفُورٗا رَّحِيمٗا
A ṣe é ní èèwọ̀ fún yín (láti fẹ́) àwọn ìyá yín àti àwọn ọmọbìnrin yín àti àwọn arábìnrin yín àti àwọn arábìnrin bàbá yín àti àwọn arábìnrin ìyá yín àti àwọn ọmọbìnrin arákùnrin yín àti àwọn ọmọbìnrin arábìnrin yín àti àwọn ìyá yín tí ó fún yín ní ọyàn mu àti àwọn arábìnrin yín nípasẹ̀ ọyàn àti àwọn ìyá ìyàwó yín àti àwọn ọmọbìnrin ìyàwó yín tí ẹ gbà tọ́, èyí tó wà nínú ilé yín,[1] tí ẹ sì ti wọlé tọ àwọn ìyá wọn, - tí ẹ̀yin kò bá sì tí ì wọlé tọ̀ wọ́n, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún yín (láti fẹ́ ọmọbìnrin wọn), - àti àwọn ìyàwó ọmọ yín, èyí tí ó ti ìbàdí yín jáde. (Ó tún jẹ́ èèwọ̀) láti fẹ́ tẹ̀gbọ́n tàbúrò papọ̀ àyàfi èyí tí ó ti ré kọjá. Dájúdájú Allāhu, Ó ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
1. Awẹ́ gbólóhùn “èyí t’ó wà nínú ilé yín” kì í ṣe májẹ̀mu. Àmọ́ ó ń fún wa ní ìtọ́ka sí pé, kì í ṣe èèwọ̀ fún ọmọ tí obìnrin ti bí fún ọkùnrin kan láti gbé lọ́dọ̀ ọkọ ìyá rẹ̀.
24 - An-Nisa (The Women) - 024
۞وَٱلۡمُحۡصَنَٰتُ مِنَ ٱلنِّسَآءِ إِلَّا مَا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُكُمۡۖ كِتَٰبَ ٱللَّهِ عَلَيۡكُمۡۚ وَأُحِلَّ لَكُم مَّا وَرَآءَ ذَٰلِكُمۡ أَن تَبۡتَغُواْ بِأَمۡوَٰلِكُم مُّحۡصِنِينَ غَيۡرَ مُسَٰفِحِينَۚ فَمَا ٱسۡتَمۡتَعۡتُم بِهِۦ مِنۡهُنَّ فَـَٔاتُوهُنَّ أُجُورَهُنَّ فَرِيضَةٗۚ وَلَا جُنَاحَ عَلَيۡكُمۡ فِيمَا تَرَٰضَيۡتُم بِهِۦ مِنۢ بَعۡدِ ٱلۡفَرِيضَةِۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلِيمًا حَكِيمٗا
(Ó tún jẹ́ èèwọ̀ láti fẹ́) àwọn abilékọ nínú àwọn obìnrin àyàfi àwọn ẹrúbìnrin yín. Òfin Allāhu nìyí lórí yín. Wọ́n sì ṣe ẹni tó ń bẹ lẹ́yìn àwọn wọ̀nyẹn (àwọn obìnrin yòókù) ní ẹ̀tọ́ fún yín pé kí ẹ wá wọn fẹ́ pẹ̀lú dúkìá yín; ẹ fẹ́ wọn ní fífẹ́ ìyàwó, láì nìí bá wọn ṣe sìná (ṣíwájú yìgì síso). Ẹni tí ẹ bá sì fẹ́ ní fífẹ́ ìyàwó nínú wọn, tí ẹ sì ti jẹ ìgbádùn oorun ìfẹ́ lára wọn[1] (àmọ́ tí ẹ fẹ́ kọ̀ wọ́n sílẹ̀), ẹ fún wọn ní sọ̀daàkí wọn tí ó jẹ́ ìpín ọ̀ran-anyàn.² Kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ fún yín nípa ohun tí ẹ dìjọ yọ́nú sí (láti fojúfò láààrin ara yín) lẹ́yìn sọ̀daàkí (tó jẹ́ ìpín ọ̀ran-anyàn)³. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
1. Ọmọ ‘Abbās - kí Allāhu yọ́nú sí àwọn méjèèjì - “Kódà kí ó jẹ́ ìbálòpọ̀ ẹ̀ẹ̀ kan péré.” 2. Gbólóhùn yìí jẹmọ́ sūrah al-Baƙọrah; 2:236 - 237 nítorí pé, ọ̀rọ̀ obìnrin tí ọkọ fẹ́ tán tí ìkọ̀sílẹ̀ wáyé láààrin wọn ṣíwájú ìbálòpọ̀, èyí ló jẹyọ nínú āyah méjèèjì yẹn. Àmọ́ nínú āyah yìí ìkọ̀sílẹ̀ wáyé lẹ́yìn ìbálòpọ̀ díẹ̀, ó kéré parí ẹ̀ẹ̀ kan péré. Ó gbọ́dọ̀ san sọ̀daàkí rẹ̀ fún un. 3. Ìyẹn ni pé, kò sí aburú tí obìnrin náà bá gba àdínkù, kò sì sí aburú tí ọkọ bá fún un ní àlékún sí òdíwọ̀n sọ̀daàkí tí wọ́n dìjọ fẹnukò sí.
25 - An-Nisa (The Women) - 025
وَمَن لَّمۡ يَسۡتَطِعۡ مِنكُمۡ طَوۡلًا أَن يَنكِحَ ٱلۡمُحۡصَنَٰتِ ٱلۡمُؤۡمِنَٰتِ فَمِن مَّا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُكُم مِّن فَتَيَٰتِكُمُ ٱلۡمُؤۡمِنَٰتِۚ وَٱللَّهُ أَعۡلَمُ بِإِيمَٰنِكُمۚ بَعۡضُكُم مِّنۢ بَعۡضٖۚ فَٱنكِحُوهُنَّ بِإِذۡنِ أَهۡلِهِنَّ وَءَاتُوهُنَّ أُجُورَهُنَّ بِٱلۡمَعۡرُوفِ مُحۡصَنَٰتٍ غَيۡرَ مُسَٰفِحَٰتٖ وَلَا مُتَّخِذَٰتِ أَخۡدَانٖۚ فَإِذَآ أُحۡصِنَّ فَإِنۡ أَتَيۡنَ بِفَٰحِشَةٖ فَعَلَيۡهِنَّ نِصۡفُ مَا عَلَى ٱلۡمُحۡصَنَٰتِ مِنَ ٱلۡعَذَابِۚ ذَٰلِكَ لِمَنۡ خَشِيَ ٱلۡعَنَتَ مِنكُمۡۚ وَأَن تَصۡبِرُواْ خَيۡرٞ لَّكُمۡۗ وَٱللَّهُ غَفُورٞ رَّحِيمٞ
Ẹni tí kò bá lágbára ọrọ̀ nínú yín láti fẹ́ àwọn olómìnira onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, kí ó fẹ́ nínú àwọn ẹrúbìnrin yín onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin. Allāhu nímọ̀ jùlọ nípa ìgbàgbọ́ yín, ara kan náà sì ni yín. Nítorí náà, ẹ fẹ́ wọn pẹ̀lú ìyọ̀ǹda àwọn olówó wọn (àwọn ọ̀gá wọn). Kí ẹ sì fún wọn ní sọ̀daàkí wọn ní ọ̀nà tó dára, (ìyẹn) àwọn ọmọlúàbí (ẹrúbìnrin), yàtọ̀ sí àwọn onísìná obìnrin àti àwọn obìnrin tí ń yan àlè[1]. Nígbà tí wọ́n bá sì di abilékọ, tí wọ́n bá (tún) lọ ṣe sìná, ìlàjì ìyà tí ń bẹ fún àwọn olómìnira obìnrin ni ìyà tí ń bẹ fún wọn.² (Fífẹ́ ẹrúbìnrin), ìyẹn wà fún ẹni tó ń páyà ìnira (sìná) nínú yín. Àti pé kí ẹ ṣe sùúrù lóore jùlọ fún yín. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
1. Musāfihah ni onísìná obìnrin tí kò sí lábẹ́ ọkọ. Muttẹkithatu- ’akdān ni onísìná obìnrin tí ó wà lábẹ́ ọkọ. 2. Ìyẹn ni pé, ẹrúbìnrin, tí ó bá ṣe sìná, kòbókò àádọ́ta ni ìjìyà rẹ̀, kì í ṣe lílẹ̀-lókò-pa nítorí pé, lílẹ̀-lókò-pa kò ṣe é pín sí méjì.
26 - An-Nisa (The Women) - 026
يُرِيدُ ٱللَّهُ لِيُبَيِّنَ لَكُمۡ وَيَهۡدِيَكُمۡ سُنَنَ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِكُمۡ وَيَتُوبَ عَلَيۡكُمۡۗ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٞ
Allāhu fẹ́ ṣàlàyé (òfin) fún yín, Ó fẹ́ tọ yín sí ọ̀nà àwọn tó ṣíwájú yín, Ó sì fẹ́ gba ìronúpìwàdà yín. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
27 - An-Nisa (The Women) - 027
وَٱللَّهُ يُرِيدُ أَن يَتُوبَ عَلَيۡكُمۡ وَيُرِيدُ ٱلَّذِينَ يَتَّبِعُونَ ٱلشَّهَوَٰتِ أَن تَمِيلُواْ مَيۡلًا عَظِيمٗا
Àti pé Allāhu fẹ́ gba ìronúpìwàdà yín. Àwọn tó sì ń tẹ̀lé ìfẹ́-adùn ara sì ń fẹ́ kí ẹ yẹ̀ kúrò (nínú ẹ̀sìn) ní yíyẹ̀ tó tóbi pátápátá.
28 - An-Nisa (The Women) - 028
يُرِيدُ ٱللَّهُ أَن يُخَفِّفَ عَنكُمۡۚ وَخُلِقَ ٱلۡإِنسَٰنُ ضَعِيفٗا
Allāhu fẹ́ gbé e fúyẹ́ fún yín; A sì ṣẹ̀dá ènìyàn ní ọ̀lẹ.[1]
1. Ìyẹn ni pé, àdámọ́ lílẹ wà nínú ìṣẹ̀dá ènìyàn.
29 - An-Nisa (The Women) - 029
يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَأۡكُلُوٓاْ أَمۡوَٰلَكُم بَيۡنَكُم بِٱلۡبَٰطِلِ إِلَّآ أَن تَكُونَ تِجَٰرَةً عَن تَرَاضٖ مِّنكُمۡۚ وَلَا تَقۡتُلُوٓاْ أَنفُسَكُمۡۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ بِكُمۡ رَحِيمٗا
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe fi èrú jẹ dúkìá yín láààrin ara yín àyàfi kí ó jẹ́ òwò ṣíṣe pẹ̀lú ìyọ́nú láààrin ara yín. Ẹ má ṣe para yín. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Aláàánú si yín.
30 - An-Nisa (The Women) - 030
وَمَن يَفۡعَلۡ ذَٰلِكَ عُدۡوَٰنٗا وَظُلۡمٗا فَسَوۡفَ نُصۡلِيهِ نَارٗاۚ وَكَانَ ذَٰلِكَ عَلَى ٱللَّهِ يَسِيرًا
Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣe ìyẹn láti fi tayọ ẹnu-ààlà àti láti fi ṣe àbòsí, láìpẹ́ A máa mú un wọ inú Iná. Ìrọ̀rùn sì ni ìyẹn jẹ́ fún Allāhu.
31 - An-Nisa (The Women) - 031
إِن تَجۡتَنِبُواْ كَبَآئِرَ مَا تُنۡهَوۡنَ عَنۡهُ نُكَفِّرۡ عَنكُمۡ سَيِّـَٔاتِكُمۡ وَنُدۡخِلۡكُم مُّدۡخَلٗا كَرِيمٗا
Tí ẹ bá jìnnà sí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ńlá tí A kọ̀ fún yín, A máa pa àwọn ìwà àìdáa yín rẹ́ fún yín, A sì máa mu yín wọ àyè alápọ̀n-ọ́nlé.
32 - An-Nisa (The Women) - 032
وَلَا تَتَمَنَّوۡاْ مَا فَضَّلَ ٱللَّهُ بِهِۦ بَعۡضَكُمۡ عَلَىٰ بَعۡضٖۚ لِّلرِّجَالِ نَصِيبٞ مِّمَّا ٱكۡتَسَبُواْۖ وَلِلنِّسَآءِ نَصِيبٞ مِّمَّا ٱكۡتَسَبۡنَۚ وَسۡـَٔلُواْ ٱللَّهَ مِن فَضۡلِهِۦٓۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٗا
Ẹ má ṣe jẹ̀rankàn ohun tí Allāhu fi ṣ’oore àjùlọ fún apá kan yín lórí apá kan.[1] Ìpín (ẹ̀san) ń bẹ fún àwọn ọkùnrin nípa ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́, ìpín (ẹ̀san) sì ń bẹ fún àwọn obìnrin nípa ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Kí ẹ sì tọrọ lọ́dọ̀ Allāhu nínú àlékún oore Rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
1. Āyah yìí sọ̀kalẹ̀ nítorí bí àwọn obìnrin kan ṣe ń jẹ̀rankàn pé kí àwọn obìnrin àti àwọn ọkùnrin dìjọ wà ní ipò orí-ò-jorí. Allāhu sì jẹ́ kí ó yé wa pé kò rí bẹ́ẹ̀ rárá àfi níbi iṣẹ́ ìjọ́sìn àti ẹ̀san rẹ̀.
33 - An-Nisa (The Women) - 033
وَلِكُلّٖ جَعَلۡنَا مَوَٰلِيَ مِمَّا تَرَكَ ٱلۡوَٰلِدَانِ وَٱلۡأَقۡرَبُونَۚ وَٱلَّذِينَ عَقَدَتۡ أَيۡمَٰنُكُمۡ فَـَٔاتُوهُمۡ نَصِيبَهُمۡۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ شَهِيدًا
Ìkọ̀ọ̀kan (nínú yín) ni A ti ṣe àdáyanrí àwọn ẹbí tí ó máa jogún rẹ̀ nínú ohun tí àwọn òbí àti ẹbí fi sílẹ̀. Àwọn tí ẹ sì búra fún (pé ẹ máa fún ní n̄ǹkan), ẹ fún wọn ní ìpín wọn. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Ẹlẹ́rìí lórí gbogbo n̄ǹkan.
34 - An-Nisa (The Women) - 034
ٱلرِّجَالُ قَوَّـٰمُونَ عَلَى ٱلنِّسَآءِ بِمَا فَضَّلَ ٱللَّهُ بَعۡضَهُمۡ عَلَىٰ بَعۡضٖ وَبِمَآ أَنفَقُواْ مِنۡ أَمۡوَٰلِهِمۡۚ فَٱلصَّـٰلِحَٰتُ قَٰنِتَٰتٌ حَٰفِظَٰتٞ لِّلۡغَيۡبِ بِمَا حَفِظَ ٱللَّهُۚ وَٱلَّـٰتِي تَخَافُونَ نُشُوزَهُنَّ فَعِظُوهُنَّ وَٱهۡجُرُوهُنَّ فِي ٱلۡمَضَاجِعِ وَٱضۡرِبُوهُنَّۖ فَإِنۡ أَطَعۡنَكُمۡ فَلَا تَبۡغُواْ عَلَيۡهِنَّ سَبِيلًاۗ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلِيّٗا كَبِيرٗا
Àwọn ọkùnrin ni òpómúléró[1] fún àwọn obìnrin nítorí pé, Allāhu ṣ’oore àjùlọ fún apá kan wọn lórí apá kan² àti nítorí ohun tí wọ́n ń ná nínú dúkìá wọn.³ Àwọn obìnrin rere ni àwọn olùtẹ̀lé-àṣẹ (Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, lẹ́yìn náà àṣẹ ọkọ), àwọn olùṣọ́-ẹ̀tọ́ ọkọ ní kọ̀rọ̀ fún wí pé Allāhu ṣọ́ (ẹ̀tọ́ tiwọn náà fún wọn lọ́dọ̀ ọkọ wọn). Àwọn tí ẹ sì ń páyà oríkunkun wọn⁴, ẹ ṣe wáàsí fún wọn, ẹ takété sí ibùsùn wọn, ẹ lù wọ́n (láì níí kó ìnira bá wọn). Tí wọ́n bá sì tẹ̀lé àṣẹ yín, ẹ má ṣe fí ọ̀nà kan kan wá wọn níjà⁵. Dájúdájú Allāhu ga, Ó tóbi.⁶
1. aláṣẹ, olùdarí, alámòójútó àti onímọ̀ràn rere. 2. Ìyẹn ni pé, Allāhu ṣ’oore àjùlọ fún àwọn ọkùnrin lórí àwọn obìnrin wọn. 3. Ìyẹn ni pé, àwọn ọkùnrin ni wọn yóò máa gbé bùkátà àwọn obìnrin wọn. 4. Èyí ni ti olóríkunkun obìnrin. Ní ti olóríkunkun ọkùnrin, ẹ wo āyah 128. 5. Ẹ má ṣe fi ọ̀nà kan kan ṣàbòsí sí wọn, Ẹ má ṣe fi ọ̀nà kan kan tayọ ẹnu-ààlà sí wọn. 6. Kíyè sí i, ọkọ kò gbọ́dọ̀ lu ìyàwó rẹ̀ àfi pẹ̀lú ẹnu ààlà àti májẹ̀mu.
35 - An-Nisa (The Women) - 035
وَإِنۡ خِفۡتُمۡ شِقَاقَ بَيۡنِهِمَا فَٱبۡعَثُواْ حَكَمٗا مِّنۡ أَهۡلِهِۦ وَحَكَمٗا مِّنۡ أَهۡلِهَآ إِن يُرِيدَآ إِصۡلَٰحٗا يُوَفِّقِ ٱللَّهُ بَيۡنَهُمَآۗ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلِيمًا خَبِيرٗا
Tí ẹ bà sì mọ̀ pé ìyapa wà láààrin àwọn méjèèjì, ẹ gbé olóye kan dìde láti inú ẹbí ọkọ àti olóye kan láti inú ẹbí ìyàwó. Tí àwọn (tọkọ tìyàwó) méjèèjì bá ń fẹ́ àtúnṣe, Allāhu yóò fi àwọn (olóye méjèèjì) ṣe kòǹgẹ́ àtúnṣe lórí ọ̀rọ̀ ààrin wọn. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Alámọ̀tán.
36 - An-Nisa (The Women) - 036
۞وَٱعۡبُدُواْ ٱللَّهَ وَلَا تُشۡرِكُواْ بِهِۦ شَيۡـٔٗاۖ وَبِٱلۡوَٰلِدَيۡنِ إِحۡسَٰنٗا وَبِذِي ٱلۡقُرۡبَىٰ وَٱلۡيَتَٰمَىٰ وَٱلۡمَسَٰكِينِ وَٱلۡجَارِ ذِي ٱلۡقُرۡبَىٰ وَٱلۡجَارِ ٱلۡجُنُبِ وَٱلصَّاحِبِ بِٱلۡجَنۢبِ وَٱبۡنِ ٱلسَّبِيلِ وَمَا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُكُمۡۗ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يُحِبُّ مَن كَانَ مُخۡتَالٗا فَخُورًا
Ẹ jọ́sìn fún Allāhu, ẹ má ṣe fi n̄ǹkan kan ṣẹbọ sí I. Ẹ ṣe dáadáa sí àwọn òbí méjèèjì àti ẹbí àti àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn mẹ̀kúnnù àti aládùúgbò tó súnmọ́ àti aládùúgbò tó jìnnà àti ọ̀rẹ́ alábàárìn àti onírìn-àjò (tí agara dá) àti àwọn ẹrú yín. Dájúdájú Allāhu kò nífẹ̀ẹ́ onígbèéraga onífáàrí.
37 - An-Nisa (The Women) - 037
ٱلَّذِينَ يَبۡخَلُونَ وَيَأۡمُرُونَ ٱلنَّاسَ بِٱلۡبُخۡلِ وَيَكۡتُمُونَ مَآ ءَاتَىٰهُمُ ٱللَّهُ مِن فَضۡلِهِۦۗ وَأَعۡتَدۡنَا لِلۡكَٰفِرِينَ عَذَابٗا مُّهِينٗا
Àwọn tó ń ṣahun, (àwọn) tó ń pa ènìyàn láṣẹ ahun ṣíṣe àti (àwọn) tó ń fi ohun tí Allāhu fún wọn nínú oore àjùlọ Rẹ̀ pamọ́; A ti pèsè ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́.
38 - An-Nisa (The Women) - 038
وَٱلَّذِينَ يُنفِقُونَ أَمۡوَٰلَهُمۡ رِئَآءَ ٱلنَّاسِ وَلَا يُؤۡمِنُونَ بِٱللَّهِ وَلَا بِٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِۗ وَمَن يَكُنِ ٱلشَّيۡطَٰنُ لَهُۥ قَرِينٗا فَسَآءَ قَرِينٗا
Àwọn tó ń ná dúkìá wọn pẹ̀lú ṣekárími, tí wọn kò sì gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn; ẹnikẹ́ni tí aṣ-Ṣaetọ̄n bá jẹ́ ọ̀rẹ́ fún, ó burú ní ọ̀rẹ́.
39 - An-Nisa (The Women) - 039
وَمَاذَا عَلَيۡهِمۡ لَوۡ ءَامَنُواْ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِ وَأَنفَقُواْ مِمَّا رَزَقَهُمُ ٱللَّهُۚ وَكَانَ ٱللَّهُ بِهِمۡ عَلِيمًا
Kí ni ìpalára tí ó máa ṣe fún wọn tí wọ́n bá gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, tí wọ́n sì ná nínú ohun tí Allāhu ṣe ní arísìkí fún wọn? Allāhu sì jẹ́ Onímọ̀ nípa wọ́n.
40 - An-Nisa (The Women) - 040
إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَظۡلِمُ مِثۡقَالَ ذَرَّةٖۖ وَإِن تَكُ حَسَنَةٗ يُضَٰعِفۡهَا وَيُؤۡتِ مِن لَّدُنۡهُ أَجۡرًا عَظِيمٗا
Dájúdájú Allāhu kò níí ṣàbòsí òdíwọ̀n ọmọ iná-igún. Tí ó bá jẹ iṣẹ́ rere, Ó máa ṣàdìpèlé (ẹ̀san) rẹ̀. Ó sì máa fún (olùṣe rere) ní ẹ̀san ńlá láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
41 - An-Nisa (The Women) - 041
فَكَيۡفَ إِذَا جِئۡنَا مِن كُلِّ أُمَّةِۭ بِشَهِيدٖ وَجِئۡنَا بِكَ عَلَىٰ هَـٰٓؤُلَآءِ شَهِيدٗا
Báwo ni ọ̀rọ̀ wọn yóò ti rí nígbà tí A bá mú ẹlẹ́rìí jáde nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan, tí A sì mú ìwọ jáde ní ẹlẹ́rìí lórí àwọn wọ̀nyí?
42 - An-Nisa (The Women) - 042