آل عمران

 

Ali 'Imran

 

Family of Imran

1 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 001

الٓمٓ
’Alif lām mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1]
1. Nítorí kí a lè mọ ìdí pàtàkì tí Allāhu ṣe fi sūrah yìí sọrí mọ̀lẹ́bí ‘Imrọ̄n, òbí Mọryam, ìyá Ànábì ‘Isā - kí ọlà Allāhu máa bá a -, ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Mọryam. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:1.

2 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 002

ٱللَّهُ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ٱلۡحَيُّ ٱلۡقَيُّومُ
Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun, Alààyè, Alámòjúútó-ẹ̀dá.

3 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 003

نَزَّلَ عَلَيۡكَ ٱلۡكِتَٰبَ بِٱلۡحَقِّ مُصَدِّقٗا لِّمَا بَيۡنَ يَدَيۡهِ وَأَنزَلَ ٱلتَّوۡرَىٰةَ وَٱلۡإِنجِيلَ
Ó sọ Tírà (al-Ƙur’ān) kalẹ̀ fún ọ pẹ̀lú òdodo, ó ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó wà ṣíwájú rẹ̀. Ó sì sọ at-Taorāh àti al-’Injīl kalẹ̀.

4 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 004

مِن قَبۡلُ هُدٗى لِّلنَّاسِ وَأَنزَلَ ٱلۡفُرۡقَانَۗ إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ لَهُمۡ عَذَابٞ شَدِيدٞۗ وَٱللَّهُ عَزِيزٞ ذُو ٱنتِقَامٍ
Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n jẹ́ ìmọ̀nà fún àwọn ènìyàn.[1] Ó tún sọ ọ̀rọ̀-ìpínyà (ọ̀rọ̀ tó ń ṣèpínyà láààrin òdodo àti irọ́) kalẹ̀.² Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, ìyà tó le ń bẹ fún wọn. Allāhu sì ni Alágbára, Olùgbẹ̀san.
1. Gbólóhùn yìí níí ṣepọ̀ pẹ̀lú ìjọ àti àsìkò. 2. Fún àlàyé lórí al-Furƙọ̄n, ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:53.

5 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 005

إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَخۡفَىٰ عَلَيۡهِ شَيۡءٞ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَلَا فِي ٱلسَّمَآءِ
Dájúdájú Allāhu, kò sí kiní kan tó pamọ́ fún Un nínú ilẹ̀ àti nínú sánmọ̀.

6 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 006

هُوَ ٱلَّذِي يُصَوِّرُكُمۡ فِي ٱلۡأَرۡحَامِ كَيۡفَ يَشَآءُۚ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ
Òun ni Ẹni tí Ó ń yàwòrán yín sínú àpòlùkẹ́ bí Ó ṣe fẹ́. Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun, Alágbára Ọlọ́gbọ́n.

7 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 007

هُوَ ٱلَّذِيٓ أَنزَلَ عَلَيۡكَ ٱلۡكِتَٰبَ مِنۡهُ ءَايَٰتٞ مُّحۡكَمَٰتٌ هُنَّ أُمُّ ٱلۡكِتَٰبِ وَأُخَرُ مُتَشَٰبِهَٰتٞۖ فَأَمَّا ٱلَّذِينَ فِي قُلُوبِهِمۡ زَيۡغٞ فَيَتَّبِعُونَ مَا تَشَٰبَهَ مِنۡهُ ٱبۡتِغَآءَ ٱلۡفِتۡنَةِ وَٱبۡتِغَآءَ تَأۡوِيلِهِۦۖ وَمَا يَعۡلَمُ تَأۡوِيلَهُۥٓ إِلَّا ٱللَّهُۗ وَٱلرَّـٰسِخُونَ فِي ٱلۡعِلۡمِ يَقُولُونَ ءَامَنَّا بِهِۦ كُلّٞ مِّنۡ عِندِ رَبِّنَاۗ وَمَا يَذَّكَّرُ إِلَّآ أُوْلُواْ ٱلۡأَلۡبَٰبِ
Òun ni Ẹni tí Ó sọ Tírà kalẹ̀ fún ọ; àwọn āyah aláìnípọ́n-na wà nínú rẹ̀ - àwọn sì ni ìpìlẹ̀ Tírà[1] -, onípọ́n-na sì ni ìyókù.² Ní ti àwọn tí ìgbúnrí kúrò níbi òdodo wà nínú ọkàn wọn, wọn yóò máa tẹ̀lé èyí tó ní pọ́n-na nínú rẹ̀ láti fi wá wàhálà àti láti fí wá ìtúmọ̀ (òdì) fún un. Kò sì sí ẹni tó nímọ̀ pàápàá ìtúmọ̀ rẹ̀ àfi Allāhu. Àwọn àgbà nínú ìmọ̀ ẹ̀sìn, wọ́n ń sọ pé: “A gbà á gbọ́. Láti ọ̀dọ̀ Olúwa wa ni gbogbo rẹ̀ (ti sọ̀kalẹ̀).” Kò sí ẹni tó ń lo ìrántí àyàfi àwọn onílàákàyè.
1. Ìyẹn ni pé, a óò máa fi àwọn āyah aláìnípọ́n-na yanjú àwọn āyah onípọ́n-na. 2. Pọ́n-na ni kí ìsọ tàbí ọ̀rọ̀ ṣe é túmọ̀ sí ọ̀pọ̀ ọ̀nà, yálà ìtúmọ̀ tí wọ́n gbà lérò tàbí ìtúmọ̀ tí wọn kò gbà lérò.

8 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 008

رَبَّنَا لَا تُزِغۡ قُلُوبَنَا بَعۡدَ إِذۡ هَدَيۡتَنَا وَهَبۡ لَنَا مِن لَّدُنكَ رَحۡمَةًۚ إِنَّكَ أَنتَ ٱلۡوَهَّابُ
Olúwa wa, má ṣe yí wa lọ́kàn padà lẹ́yìn tí O ti tọ́ wa sọ́nà. Ta wá lọ́rẹ ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Rẹ, dájúdájú Ìwọ gan-an ni Ọlọ́rẹ.

9 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 009

رَبَّنَآ إِنَّكَ جَامِعُ ٱلنَّاسِ لِيَوۡمٖ لَّا رَيۡبَ فِيهِۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يُخۡلِفُ ٱلۡمِيعَادَ
Olúwa wa, dájúdájú Ìwọ l’O máa kó àwọn ènìyàn jọ ní ọjọ́ kan, tí kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Dájúdájú Allāhu kì í yẹ àdéhùn.

10 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 010

إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لَن تُغۡنِيَ عَنۡهُمۡ أَمۡوَٰلُهُمۡ وَلَآ أَوۡلَٰدُهُم مِّنَ ٱللَّهِ شَيۡـٔٗاۖ وَأُوْلَـٰٓئِكَ هُمۡ وَقُودُ ٱلنَّارِ
Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, àwọn dúkìá wọn àti àwọn ọmọ wọn kò níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kiní kan lọ́dọ̀ Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni n̄ǹkan ìkoná.

11 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 011

كَدَأۡبِ ءَالِ فِرۡعَوۡنَ وَٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡۚ كَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِنَا فَأَخَذَهُمُ ٱللَّهُ بِذُنُوبِهِمۡۗ وَٱللَّهُ شَدِيدُ ٱلۡعِقَابِ
(Ìṣesí wọn) dà bí ìṣesí àwọn ènìyàn Fir‘aon àti àwọn tó ṣíwájú wọn, tí wọ́n pe àwọn āyah Wa ní irọ́. Nítorí náà, Allāhu mú wọn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Allāhu sì le níbi ìyà.

12 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 012

قُل لِّلَّذِينَ كَفَرُواْ سَتُغۡلَبُونَ وَتُحۡشَرُونَ إِلَىٰ جَهَنَّمَۖ وَبِئۡسَ ٱلۡمِهَادُ
Sọ fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ pé: “Wọ́n máa ṣẹ́gun yín. Wọ́n sì máa ko yín jọ lọ sí iná Jahanamọ. Ibùgbé náà sì burú.”

13 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 013

قَدۡ كَانَ لَكُمۡ ءَايَةٞ فِي فِئَتَيۡنِ ٱلۡتَقَتَاۖ فِئَةٞ تُقَٰتِلُ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ وَأُخۡرَىٰ كَافِرَةٞ يَرَوۡنَهُم مِّثۡلَيۡهِمۡ رَأۡيَ ٱلۡعَيۡنِۚ وَٱللَّهُ يُؤَيِّدُ بِنَصۡرِهِۦ مَن يَشَآءُۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَعِبۡرَةٗ لِّأُوْلِي ٱلۡأَبۡصَٰرِ
Àmì kúkú wà fún yín níbi àwọn ìjọ méjì tí wọ́n pàdé (ara wọn lójú ogun). Ìjọ kan ń jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu (fún ààbò ẹ̀sìn). Aláìgbàgbọ́ sì ni ìjọ kejì tí ó ń rí ìjọ kìíní bí ìlọ́po méjì wọn ní rírí ojú.[1] Allāhu ń fi àrànṣe Rẹ̀ ṣe ìkúnlọ́wọ́ fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Dájúdájú àríwòye wà nínú ìyẹn fún àwọn olùríran.
1. Ìyẹn ní ojú ogun Badr.

14 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 014

زُيِّنَ لِلنَّاسِ حُبُّ ٱلشَّهَوَٰتِ مِنَ ٱلنِّسَآءِ وَٱلۡبَنِينَ وَٱلۡقَنَٰطِيرِ ٱلۡمُقَنطَرَةِ مِنَ ٱلذَّهَبِ وَٱلۡفِضَّةِ وَٱلۡخَيۡلِ ٱلۡمُسَوَّمَةِ وَٱلۡأَنۡعَٰمِ وَٱلۡحَرۡثِۗ ذَٰلِكَ مَتَٰعُ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَاۖ وَٱللَّهُ عِندَهُۥ حُسۡنُ ٱلۡمَـَٔابِ
Wọ́n ṣe é ní ọ̀ṣọ́ fún àwọn ènìyàn; ìfẹ́ ìgbádùn ara lára àwọn obìnrin, àwọn ọmọkùnrin, àwọn owó wúrà àti fàdákà púpọ̀ jaburata àti àwọn ẹṣin tí wọ́n ṣe ní ọ̀ṣọ́, àwọn ẹran-ọ̀sìn àti (n̄ǹkan) oko. Ìyẹn ni n̄ǹkan ìgbáyé-gbádùn. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni àbọ̀ rere wà.

15 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 015

۞قُلۡ أَؤُنَبِّئُكُم بِخَيۡرٖ مِّن ذَٰلِكُمۡۖ لِلَّذِينَ ٱتَّقَوۡاْ عِندَ رَبِّهِمۡ جَنَّـٰتٞ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَا وَأَزۡوَٰجٞ مُّطَهَّرَةٞ وَرِضۡوَٰنٞ مِّنَ ٱللَّهِۗ وَٱللَّهُ بَصِيرُۢ بِٱلۡعِبَادِ
Sọ pé: “Ṣé kí n̄g sọ n̄ǹkan tó dára ju ìyẹn lọ fún yín?” Àwọn Ọgbà tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀ ń bẹ fún àwọn tó bá bẹ̀rù (Allāhu) ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Àwọn ìyàwó mímọ́ àti ìyọ́nú láti ọ̀dọ̀ Allāhu (tún ń bẹ fún wọn). Allāhu sì ni Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn,

16 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 016

ٱلَّذِينَ يَقُولُونَ رَبَّنَآ إِنَّنَآ ءَامَنَّا فَٱغۡفِرۡ لَنَا ذُنُوبَنَا وَقِنَا عَذَابَ ٱلنَّارِ
Àwọn tó ń sọ pé: “Olúwa wa, dájúdájú àwa gbàgbọ́. Nítorí náà, forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jìn wá. Kí O sì ṣọ́ wa níbi ìyà Iná.”

17 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 017

ٱلصَّـٰبِرِينَ وَٱلصَّـٰدِقِينَ وَٱلۡقَٰنِتِينَ وَٱلۡمُنفِقِينَ وَٱلۡمُسۡتَغۡفِرِينَ بِٱلۡأَسۡحَارِ
(Ọgbà Ìdẹ̀ra yẹn wà fún) àwọn onísùúrù, àwọn olódodo, àwọn olùtẹ̀lé-àṣẹ Allāhu, àwọn olùnáwó-fẹ́sìn àti àwọn olùtọrọ-àforíjìn ní àsìkò sààrì.

18 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 018

شَهِدَ ٱللَّهُ أَنَّهُۥ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ وَٱلۡمَلَـٰٓئِكَةُ وَأُوْلُواْ ٱلۡعِلۡمِ قَآئِمَۢا بِٱلۡقِسۡطِۚ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ
Allāhu jẹ́rìí pé dájúdájú kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Àwọn mọlāika àti onímọ̀ ẹ̀sìn (tún jẹ́rìí bẹ́ẹ̀.), Allāhu ni Onídéédé. Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

19 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 019

إِنَّ ٱلدِّينَ عِندَ ٱللَّهِ ٱلۡإِسۡلَٰمُۗ وَمَا ٱخۡتَلَفَ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡكِتَٰبَ إِلَّا مِنۢ بَعۡدِ مَا جَآءَهُمُ ٱلۡعِلۡمُ بَغۡيَۢا بَيۡنَهُمۡۗ وَمَن يَكۡفُرۡ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ فَإِنَّ ٱللَّهَ سَرِيعُ ٱلۡحِسَابِ
Dájúdájú ẹ̀sìn tó wà lọ́dọ̀ Allāhu ni ’Islām. Àwọn tí A fún ní Tírà (àwọn yẹhudi àti nasọ̄rọ̄) kò yapa-ẹnu (lórí ẹ̀sìn náà) àfi lẹ́yìn tí ìmọ̀ dé bá wọn ní ti ìlara láààrin ara wọn (sí àwọn Ànábì - kí ọlà Allāhu máa bá wọn -). Ẹni tó bá ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, dájúdájú Allāhu ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́.

20 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 020

فَإِنۡ حَآجُّوكَ فَقُلۡ أَسۡلَمۡتُ وَجۡهِيَ لِلَّهِ وَمَنِ ٱتَّبَعَنِۗ وَقُل لِّلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡكِتَٰبَ وَٱلۡأُمِّيِّـۧنَ ءَأَسۡلَمۡتُمۡۚ فَإِنۡ أَسۡلَمُواْ فَقَدِ ٱهۡتَدَواْۖ وَّإِن تَوَلَّوۡاْ فَإِنَّمَا عَلَيۡكَ ٱلۡبَلَٰغُۗ وَٱللَّهُ بَصِيرُۢ بِٱلۡعِبَادِ
Tí wọ́n bá sì jà ọ́ níyàn, sọ pé: “Èmi àti ẹni tí ó tẹ̀lé mi juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ (mùsùlùmí ni wá) fún Allāhu.” Kí o sì sọ fún àwọn tí A fún ní Tírà àti àwọn aláìmọ̀ọ́nkọmọ̀ọ́nkà (aláìnítírà) pé: “Ṣé ẹ máa gba ’Islām?” Tí wọ́n bá gba ’Islām, wọ́n ti mọ̀nà. Tí wọ́n bá sì kẹ̀yìn (sí’Islām), ìkéde (ẹ̀sìn) nìkan ni ojúṣe tìrẹ. Allāhu sì ni Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn.

21 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 021

إِنَّ ٱلَّذِينَ يَكۡفُرُونَ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ وَيَقۡتُلُونَ ٱلنَّبِيِّـۧنَ بِغَيۡرِ حَقّٖ وَيَقۡتُلُونَ ٱلَّذِينَ يَأۡمُرُونَ بِٱلۡقِسۡطِ مِنَ ٱلنَّاسِ فَبَشِّرۡهُم بِعَذَابٍ أَلِيمٍ
Dájúdájú àwọn tó ń ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, wọ́n tún ń pa àwọn Ànábì láì lẹ́tọ̀ọ́, wọ́n tún ń pa àwọn ènìyàn tí ń pàṣẹ ṣíṣe déédé àti ẹ̀tọ́, fún wọn ní ìró ìyà ẹlẹ́ta-eléro.

22 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 022

أُوْلَـٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ حَبِطَتۡ أَعۡمَٰلُهُمۡ فِي ٱلدُّنۡيَا وَٱلۡأٓخِرَةِ وَمَا لَهُم مِّن نَّـٰصِرِينَ
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí iṣẹ́ wọn ti bàjẹ́ ní ilé ayé àti ní ọ̀run. Wọn kò sì níí rí àwọn olùrànlọ́wọ́.

23 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 023

أَلَمۡ تَرَ إِلَى ٱلَّذِينَ أُوتُواْ نَصِيبٗا مِّنَ ٱلۡكِتَٰبِ يُدۡعَوۡنَ إِلَىٰ كِتَٰبِ ٱللَّهِ لِيَحۡكُمَ بَيۡنَهُمۡ ثُمَّ يَتَوَلَّىٰ فَرِيقٞ مِّنۡهُمۡ وَهُم مُّعۡرِضُونَ
Ṣé ìwọ kò wòye sí àwọn tí A fún ní ìpín kan nínú Tírà, tí À ń pè wọ́n síbi Tírà Allāhu, nítorí kí ó lè ṣe ìdájọ́ láààrin wọn, lẹ́yìn náà tí ìjọ kan nínú wọn ń pẹ̀yìndà, tí wọ́n sì ń gbúnrí?

24 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 024

ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ قَالُواْ لَن تَمَسَّنَا ٱلنَّارُ إِلَّآ أَيَّامٗا مَّعۡدُودَٰتٖۖ وَغَرَّهُمۡ فِي دِينِهِم مَّا كَانُواْ يَفۡتَرُونَ
Ìyẹn nítorí pé dájúdájú wọ́n wí pé: “Iná kò lè jó wa tayọ àwọn ọjọ́ tó lóǹkà.” Ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́ sì tàn wọ́n jẹ nínú ẹ̀sìn wọn.

25 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 025

فَكَيۡفَ إِذَا جَمَعۡنَٰهُمۡ لِيَوۡمٖ لَّا رَيۡبَ فِيهِ وَوُفِّيَتۡ كُلُّ نَفۡسٖ مَّا كَسَبَتۡ وَهُمۡ لَا يُظۡلَمُونَ
Nítorí náà, báwo ni (ó ṣe máa rí fún wọn) nígbà tí A bá kó wọn jọ ní ọjọ́ kan, tí kò sí iyèméjì nínú rẹ̀? Àti pé A máa san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ohun tí ó ṣe níṣẹ́ ní ẹ̀kún-rẹ́rẹ́. Wọn kò sì níí ṣàbòsí sí wọn.

26 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 026

قُلِ ٱللَّهُمَّ مَٰلِكَ ٱلۡمُلۡكِ تُؤۡتِي ٱلۡمُلۡكَ مَن تَشَآءُ وَتَنزِعُ ٱلۡمُلۡكَ مِمَّن تَشَآءُ وَتُعِزُّ مَن تَشَآءُ وَتُذِلُّ مَن تَشَآءُۖ بِيَدِكَ ٱلۡخَيۡرُۖ إِنَّكَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ
Sọ pé: “Allāhu, Olùkápá ìjọba, Ò ń fi ìjọba fún ẹni tí O bá fẹ́. Ò ń gba ìjọba lọ́wọ́ ẹni tí O bá fẹ́. Ò ń buyì kún ẹni tí O bá fẹ́. O sì ń tàbùkù ẹni tí O bá fẹ́. Ọwọ́ Rẹ ni oore wà. Dájúdájú Ìwọ ni Alágbárá lórí gbogbo n̄ǹkan.

27 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 027

تُولِجُ ٱلَّيۡلَ فِي ٱلنَّهَارِ وَتُولِجُ ٱلنَّهَارَ فِي ٱلَّيۡلِۖ وَتُخۡرِجُ ٱلۡحَيَّ مِنَ ٱلۡمَيِّتِ وَتُخۡرِجُ ٱلۡمَيِّتَ مِنَ ٱلۡحَيِّۖ وَتَرۡزُقُ مَن تَشَآءُ بِغَيۡرِ حِسَابٖ
Ò ń mú òru wọnú ọ̀sán.[1] Ò ń mú ọ̀sán wọnú òru.² Ò ń mú alààyè jáde lára òkú. Ò ń mú òkú jáde lára alààyè. O sì ń pèsè ìjẹ-ìmu àti ìgbádùn fún ẹni tí Ó bá fẹ́ láì níí ní ìṣírò.”³
1. Àsìkò ọ̀sán máa gùn, àsìkò òru sì máa kúrú. 2. Àsìkò ọ̀ru máa gùn, àsìkò ọ̀sán sì máa kúrú. 3. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:212.

28 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 028

لَّا يَتَّخِذِ ٱلۡمُؤۡمِنُونَ ٱلۡكَٰفِرِينَ أَوۡلِيَآءَ مِن دُونِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَۖ وَمَن يَفۡعَلۡ ذَٰلِكَ فَلَيۡسَ مِنَ ٱللَّهِ فِي شَيۡءٍ إِلَّآ أَن تَتَّقُواْ مِنۡهُمۡ تُقَىٰةٗۗ وَيُحَذِّرُكُمُ ٱللَّهُ نَفۡسَهُۥۗ وَإِلَى ٱللَّهِ ٱلۡمَصِيرُ
Àwọn onígbàgbọ́ òdodo kò gbọ́dọ̀ sọ àwọn aláìgbàgbọ́ di ọ̀rẹ́ àyò (ọ̀rẹ́ finúhannú) lẹ́yìn àwọn onígbàgbọ́ òdodo (ẹgbẹ́ wọn). Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe ìyẹn, kò sí kiní kan fún un mọ́ lọ́dọ̀ Allāhu.[1] Àfi tí ẹ bá ń (fi ọ̀rẹ́ orí ahọ́n) wá ìṣọ́ra lọ́dọ̀ wọn) dáadáa (lórí ìgbàgbọ́ yín).² Allāhu ń kìlọ̀ ara Rẹ̀ fún yín. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.
1. Ẹni tí ó sọ aláìgbàgbọ́ di ọ̀rẹ́ àyò tí yọwọ́ yọsẹ̀ kúrò nínú ọ̀rọ̀ Allāhu, Allāhu sì ti yọwọ́ yọsẹ̀ kúrò nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀. 2. Ìyẹn fún àwọn mùsùlùmí tí ń bẹ lábẹ́ àṣẹ àti ìdàrí àwọn aláìgbàgbọ́ bí ó bá la làlúrí lọ.

29 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 029

قُلۡ إِن تُخۡفُواْ مَا فِي صُدُورِكُمۡ أَوۡ تُبۡدُوهُ يَعۡلَمۡهُ ٱللَّهُۗ وَيَعۡلَمُ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۗ وَٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ
Sọ pé: “Tí ẹ bá fi ohun tí ń bẹ nínú ọkàn yín pamọ́ tàbí ẹ fi hàn, Allāhu mọ̀ ọ́n. Ó sì mọ ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.

30 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 030

يَوۡمَ تَجِدُ كُلُّ نَفۡسٖ مَّا عَمِلَتۡ مِنۡ خَيۡرٖ مُّحۡضَرٗا وَمَا عَمِلَتۡ مِن سُوٓءٖ تَوَدُّ لَوۡ أَنَّ بَيۡنَهَا وَبَيۡنَهُۥٓ أَمَدَۢا بَعِيدٗاۗ وَيُحَذِّرُكُمُ ٱللَّهُ نَفۡسَهُۥۗ وَٱللَّهُ رَءُوفُۢ بِٱلۡعِبَادِ
Ní ọjọ́ tí ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan yóò rí ohun tí ó ṣe nínú iṣẹ́ rere níwájú (rẹ̀) àti ohun tí ó ṣe nínú iṣẹ́ ibi, ó máa fẹ́ kí àkókò tó jìnnà wà láààrin òun àti iṣẹ́ ibi rẹ̀. Allāhu sì ń kìlọ̀ ara Rẹ̀ fún yín. Allāhu sì ni Aláàánú àwọn ẹrúsìn (Rẹ̀).

31 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 031

قُلۡ إِن كُنتُمۡ تُحِبُّونَ ٱللَّهَ فَٱتَّبِعُونِي يُحۡبِبۡكُمُ ٱللَّهُ وَيَغۡفِرۡ لَكُمۡ ذُنُوبَكُمۡۚ وَٱللَّهُ غَفُورٞ رَّحِيمٞ
Sọ pé: “Tí ẹ̀yin bá nífẹ̀ẹ́ Allāhu, ẹ tẹ̀lé mi, Allāhu máa nífẹ̀ẹ́ yín, Ó sì máa forí ẹ̀ṣẹ̀ yín jìn yín. Allāhu ni Aláforíjìn, Aláàánú.

32 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 032

قُلۡ أَطِيعُواْ ٱللَّهَ وَٱلرَّسُولَۖ فَإِن تَوَلَّوۡاْ فَإِنَّ ٱللَّهَ لَا يُحِبُّ ٱلۡكَٰفِرِينَ
Sọ pé: “Ẹ tẹ̀lé (ti) Allāhu àti Òjíṣẹ́. Tí ẹ bá sì pẹ̀yìn dà, dájúdájú Allāhu kò nífẹ̀ẹ́ àwọn aláìgbàgbọ́.

33 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 033

۞إِنَّ ٱللَّهَ ٱصۡطَفَىٰٓ ءَادَمَ وَنُوحٗا وَءَالَ إِبۡرَٰهِيمَ وَءَالَ عِمۡرَٰنَ عَلَى ٱلۡعَٰلَمِينَ
Dájúdájú Allāhu ṣa Ādam, Nūh, ará ilé ’Ibrọ̄hīm àti ará ilé ‘Imrọ̄n lẹ́ṣà lórí àwọn ẹ̀dá (àsìkò tiwọn).

34 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 034

ذُرِّيَّةَۢ بَعۡضُهَا مِنۢ بَعۡضٖۗ وَٱللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ
Wọ́n jẹ́ àrọ́mọdọ́mọ; apá kan wọn wá láti ara apá kan. Allāhu sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.

35 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 035

إِذۡ قَالَتِ ٱمۡرَأَتُ عِمۡرَٰنَ رَبِّ إِنِّي نَذَرۡتُ لَكَ مَا فِي بَطۡنِي مُحَرَّرٗا فَتَقَبَّلۡ مِنِّيٓۖ إِنَّكَ أَنتَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡعَلِيمُ
(Ẹ rántí) nígbà tí aya ‘Imrọ̄n sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú èmi fi ohun tí ń bẹ nínú ikùn mi jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Ọ (pé) mo máa yà á sọ́tọ̀ (fún ẹ̀sìn Rẹ). Nítorí náà, gbà á lọ́wọ́ mi, dájúdájú Ìwọ ni Olùgbọ́, Onímọ̀.”

36 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 036

فَلَمَّا وَضَعَتۡهَا قَالَتۡ رَبِّ إِنِّي وَضَعۡتُهَآ أُنثَىٰ وَٱللَّهُ أَعۡلَمُ بِمَا وَضَعَتۡ وَلَيۡسَ ٱلذَّكَرُ كَٱلۡأُنثَىٰۖ وَإِنِّي سَمَّيۡتُهَا مَرۡيَمَ وَإِنِّيٓ أُعِيذُهَا بِكَ وَذُرِّيَّتَهَا مِنَ ٱلشَّيۡطَٰنِ ٱلرَّجِيمِ
Nígbà tí ó bí i, ó sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú mo bí i ní obìnrin - Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ó bí – ọkùnrin kò sì dà bí obìnrin. Dájúdájú èmi sọ ọ́ ní Mọryam. Àti pé dájúdájú mò ń fi Ọ́ wá ààbò fún òun àti àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ lọ́dọ̀ aṣ-Ṣaetọ̄n ẹni ẹ̀kọ̀.”
Nígbà tí ó bí i, ó sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú mo bí i ní obìnrin - Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ó bí – ọkùnrin kò sì dà bí obìnrin. Dájúdájú èmi sọ ọ́ ní Mọryam. Àti pé dájúdájú mò ń fi Ọ́ wá ààbò fún òun àti àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ lọ́dọ̀ aṣ-Ṣaetọ̄n, ẹni ẹ̀kọ̀.”

37 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 037

فَتَقَبَّلَهَا رَبُّهَا بِقَبُولٍ حَسَنٖ وَأَنۢبَتَهَا نَبَاتًا حَسَنٗا وَكَفَّلَهَا زَكَرِيَّاۖ كُلَّمَا دَخَلَ عَلَيۡهَا زَكَرِيَّا ٱلۡمِحۡرَابَ وَجَدَ عِندَهَا رِزۡقٗاۖ قَالَ يَٰمَرۡيَمُ أَنَّىٰ لَكِ هَٰذَاۖ قَالَتۡ هُوَ مِنۡ عِندِ ٱللَّهِۖ إِنَّ ٱللَّهَ يَرۡزُقُ مَن يَشَآءُ بِغَيۡرِ حِسَابٍ
Olúwa rẹ̀ sì gba àdúà rẹ̀ ní gbígbà dáadáa. Ó sì mú ọmọ náà dàgbà ní ìdàgbà dáadáa. Ó sì fi Zakariyyā ṣe alágbàtọ́ rẹ̀. Ìgbàkígbà tí Zakariyyā bá wọlé tọ̀ ọ́ nínú ilé ìjọ́sìn, ó máa bá èsè (èso) lọ́dọ̀ rẹ̀. (Zakariyyā á) sọ pé: “Mọryam, báwo ni èyí ṣe jẹ́ tìrẹ?” (Mọryam á) sọ pé: “Ó wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ń pèsè ìjẹ-ìmu àti ìgbádùn fún ẹni tí Ó bá fẹ́ láì níí ní ìṣírò.”[1]
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:212.

38 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 038

هُنَالِكَ دَعَا زَكَرِيَّا رَبَّهُۥۖ قَالَ رَبِّ هَبۡ لِي مِن لَّدُنكَ ذُرِّيَّةٗ طَيِّبَةًۖ إِنَّكَ سَمِيعُ ٱلدُّعَآءِ
Ibẹ̀yẹn ni Zakariyyā ti pe Olúwa rẹ̀. Ó sọ pé: “Olúwa mi, ta mí ní ọrẹ àrọ́mọdọ́mọ dáadáa láti ọ̀dọ̀ Rẹ. Dájúdájú Ìwọ ni Olùgbọ́-àdúà.”
- Ibẹ̀yẹn ni Zakariyyā ti pe Olúwa rẹ̀. Ó sọ pé: "Olúwa mi, ta mí ní ọrẹ àrọ́mọdọ́mọ dáadáa láti ọ̀dọ̀ Rẹ. Dájúdájú Ìwọ ni Olùgbọ́ àdúà." -

39 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 039

فَنَادَتۡهُ ٱلۡمَلَـٰٓئِكَةُ وَهُوَ قَآئِمٞ يُصَلِّي فِي ٱلۡمِحۡرَابِ أَنَّ ٱللَّهَ يُبَشِّرُكَ بِيَحۡيَىٰ مُصَدِّقَۢا بِكَلِمَةٖ مِّنَ ٱللَّهِ وَسَيِّدٗا وَحَصُورٗا وَنَبِيّٗا مِّنَ ٱلصَّـٰلِحِينَ
Nítorí náà, àwọn mọlāika pè é nígbà tí ó ń kírun lọ́wọ́ nínú ilé ìjọ́sìn, (wọ́n sọ pé): “Dájúdájú Allāhu ń fún ọ ní ìró ìdùnnú nípa (bíbí) Yahyā. Ó máa fi òdodo rinlẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu.[1] (Ó máa jẹ́) aṣíwájú, tí kò kúndùn obìnrin.² (Ó máa jẹ́) Ànábì. Ó sì wà nínú àwọn ẹni rere.”
1. “Ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu”, ìyẹn ni pé, ẹni tí Allāhu fi "kunfayakun" ṣẹ̀dá rẹ̀. 2. tàbí ẹni tí kò ju ẹ̀mí ara rẹ̀ sílẹ̀ fún ìfẹ́-inú àti yòdòyìndìn ayé.

40 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 040

قَالَ رَبِّ أَنَّىٰ يَكُونُ لِي غُلَٰمٞ وَقَدۡ بَلَغَنِيَ ٱلۡكِبَرُ وَٱمۡرَأَتِي عَاقِرٞۖ قَالَ كَذَٰلِكَ ٱللَّهُ يَفۡعَلُ مَا يَشَآءُ
(Zakariyyā) sọ pé: “Olúwa mi, báwo ni èmi yóò ṣe ní ọmọkùnrin; mo mà ti dàgbàlágbà, àgàn sì ni obìnrin mi?” Ó sọ pé: “Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣe ohun tí Ó bá fẹ́.”

41 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 041

قَالَ رَبِّ ٱجۡعَل لِّيٓ ءَايَةٗۖ قَالَ ءَايَتُكَ أَلَّا تُكَلِّمَ ٱلنَّاسَ ثَلَٰثَةَ أَيَّامٍ إِلَّا رَمۡزٗاۗ وَٱذۡكُر رَّبَّكَ كَثِيرٗا وَسَبِّحۡ بِٱلۡعَشِيِّ وَٱلۡإِبۡكَٰرِ
(Zakariyyā) sọ pé: “Olúwa mi, fún mi ní àmì kan.” Ó sọ pé: “Àmì rẹ ni pé ìwọ kò níí lè bá ènìyàn sọ̀rọ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta àyàfi títọ́ka (sí n̄ǹkan). Rántí Olúwa rẹ lọ́pọ̀lọ́pọ̀. Kí o sì ṣàfọ̀mọ́ (fún Un) ní àṣálẹ́ àti ní òwúrọ̀ kùtù.”

42 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 042

وَإِذۡ قَالَتِ ٱلۡمَلَـٰٓئِكَةُ يَٰمَرۡيَمُ إِنَّ ٱللَّهَ ٱصۡطَفَىٰكِ وَطَهَّرَكِ وَٱصۡطَفَىٰكِ عَلَىٰ نِسَآءِ ٱلۡعَٰلَمِينَ
(Ẹ rántí) nígbà tí àwọn mọlāika sọ pé: “Mọryam, dájúdájú Allāhu ṣà ọ́ lẹ́ṣà. Ó fọ̀ ọ́ mọ́. Ó sì ṣà ọ́ lẹ́ṣà lórí àwọn obìnrin ayé (àsìkò tìrẹ).[1]
1. “Àsìkò tirẹ̀” torí pé, àwọn obìnrin mìíran rí bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Kọdījah ọmọ Kuwaelid.

43 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 043

يَٰمَرۡيَمُ ٱقۡنُتِي لِرَبِّكِ وَٱسۡجُدِي وَٱرۡكَعِي مَعَ ٱلرَّـٰكِعِينَ
Mọryam, tẹ̀lé àṣẹ Olúwa rẹ. Forí kanlẹ̀ fún Un. Kí o sì dáwọ́tẹ orúnkún pẹ̀lú àwọn olùdáwọ́tẹ-orúnkún (lórí ìrun).

44 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 044

ذَٰلِكَ مِنۡ أَنۢبَآءِ ٱلۡغَيۡبِ نُوحِيهِ إِلَيۡكَۚ وَمَا كُنتَ لَدَيۡهِمۡ إِذۡ يُلۡقُونَ أَقۡلَٰمَهُمۡ أَيُّهُمۡ يَكۡفُلُ مَرۡيَمَ وَمَا كُنتَ لَدَيۡهِمۡ إِذۡ يَخۡتَصِمُونَ
Ìyẹn wà nínú ìró ìkọ̀kọ̀ tí À ń fi ìmísí rẹ̀ ránṣẹ́ sí ọ. Ìwọ kò kúkú sí lọ́dọ̀ wọn nígbà tí wọ́n ń ju gègé wọn (sínú odò láti mọ) ta ni nínú wọn ni ó máa gba Mọryam wò.[1] Ìwọ kò sì sí lọ́dọ̀ wọn nígbà tí wọ́n ń ṣe ìfàn̄fà (lórí rẹ̀).
1. Olúkùlùkù wọn kọ orúkọ rẹ̀ sára gègé rẹ̀. Wọ́n dá gègé wọn jọ, wọ́n dà wọ́n sínú odò. Odò gbé gbogbo gègé wọn lọ àfi gègé ti Zakariyā’ - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Wọ́n sì gbé Mọryam fún Ànábì Zakariyā’ - kí ọlà Allāhu máa bá a - gẹ́gẹ́ bí alágbàwò rẹ̀.

45 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 045

إِذۡ قَالَتِ ٱلۡمَلَـٰٓئِكَةُ يَٰمَرۡيَمُ إِنَّ ٱللَّهَ يُبَشِّرُكِ بِكَلِمَةٖ مِّنۡهُ ٱسۡمُهُ ٱلۡمَسِيحُ عِيسَى ٱبۡنُ مَرۡيَمَ وَجِيهٗا فِي ٱلدُّنۡيَا وَٱلۡأٓخِرَةِ وَمِنَ ٱلۡمُقَرَّبِينَ
(Ẹ rántí) nígbà tí àwọn mọlāika [1] sọ pé: “Mọryam, dájúdájú Allāhu ń fún ọ ní ìró ìdùnnú (nípa dídá ẹ̀dá kan pẹ̀lú) ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Orúkọ rẹ̀ ni Mọsīh ‘Īsā ọmọ Mọryam. Ẹni iyì ni ní ayé àti ní ọ̀run.[1] Ó sì wà lára àwọn alásùn-únmọ́ (Allāhu).
1. Àwọn nasọ̄rọ̄ lérò pé, Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - nìkan ni “Ẹni iyì” ní ọ̀dọ̀ Allāhu. Ẹ wo sūrah al-’Ahzāb; 33:69.

46 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 046

وَيُكَلِّمُ ٱلنَّاسَ فِي ٱلۡمَهۡدِ وَكَهۡلٗا وَمِنَ ٱلصَّـٰلِحِينَ
Ó máa bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ lórí ìtẹ́ ní òpóǹló àti nígbà tó bá dàgbà.[1] Ó sì wà nínú àwọn ẹni rere.”
1. Gẹ́gẹ́ bí ọmọdé kan ní àsìkò Juraej àti ọmọdé kan mìíràn ṣe sọ̀rọ̀ lórí ìtẹ́ ní òpóǹló.”

47 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 047

قَالَتۡ رَبِّ أَنَّىٰ يَكُونُ لِي وَلَدٞ وَلَمۡ يَمۡسَسۡنِي بَشَرٞۖ قَالَ كَذَٰلِكِ ٱللَّهُ يَخۡلُقُ مَا يَشَآءُۚ إِذَا قَضَىٰٓ أَمۡرٗا فَإِنَّمَا يَقُولُ لَهُۥ كُن فَيَكُونُ
(Mọryam) sọ pé: “Olúwa mi báwo ni èmi yó ṣe ní ọmọkùnrin, (nígbà tí) abara kan kò fọwọ́ kàn mí.” Ó sọ pé: Báyẹn ni Allāhu ṣe ń dá ohun tí Ó bá fẹ́. Nígbà tí Ó bá (gbèrò) láti dá ẹ̀dá kan ohun tí Ó máa sọ fún un ni pé: “Jẹ́ bẹ́ẹ̀.” Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀.

48 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 048

وَيُعَلِّمُهُ ٱلۡكِتَٰبَ وَٱلۡحِكۡمَةَ وَٱلتَّوۡرَىٰةَ وَٱلۡإِنجِيلَ
(Allāhu) yóò fún un ní ìmọ̀ ìkọ̀wé, òye ìjìnlẹ̀, at-Taorāh àti al-’Injīl.

49 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 049

وَرَسُولًا إِلَىٰ بَنِيٓ إِسۡرَـٰٓءِيلَ أَنِّي قَدۡ جِئۡتُكُم بِـَٔايَةٖ مِّن رَّبِّكُمۡ أَنِّيٓ أَخۡلُقُ لَكُم مِّنَ ٱلطِّينِ كَهَيۡـَٔةِ ٱلطَّيۡرِ فَأَنفُخُ فِيهِ فَيَكُونُ طَيۡرَۢا بِإِذۡنِ ٱللَّهِۖ وَأُبۡرِئُ ٱلۡأَكۡمَهَ وَٱلۡأَبۡرَصَ وَأُحۡيِ ٱلۡمَوۡتَىٰ بِإِذۡنِ ٱللَّهِۖ وَأُنَبِّئُكُم بِمَا تَأۡكُلُونَ وَمَا تَدَّخِرُونَ فِي بُيُوتِكُمۡۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗ لَّكُمۡ إِن كُنتُم مُّؤۡمِنِينَ
(Ó sì jẹ́) Òjíṣẹ́ (tí A rán níṣẹ́) sí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl. (Ó sì máa sọ fún wọn pé) “Dájúdájú èmi ti mú àmì kan wá fún yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Dájúdájú èmi yóò mọ n̄ǹkan fún yín láti inú amọ̀ bí ìrísí ẹyẹ. Èmi yóò fẹ́ atẹ́gùn sínú rẹ̀. Ó sì máa di ẹyẹ pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Èmi yóò ṣe ìwòsàn fún afọ́jú àti adẹ́tẹ̀, mo sì máa sọ òkú di alààyè pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Èmi yóò máa fún yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń jẹ àti ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́ sínú ilé yín. Dájúdájú àmì kan wà nínú ìyẹn fún yín, tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.[1]
1. Ẹ wo ìtọsȩ̣̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Mọ̄’idah; 5:110.

50 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 050

وَمُصَدِّقٗا لِّمَا بَيۡنَ يَدَيَّ مِنَ ٱلتَّوۡرَىٰةِ وَلِأُحِلَّ لَكُم بَعۡضَ ٱلَّذِي حُرِّمَ عَلَيۡكُمۡۚ وَجِئۡتُكُم بِـَٔايَةٖ مِّن رَّبِّكُمۡ فَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَأَطِيعُونِ
Mo sì ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó ṣíwájú mi nínú at-Taorāh nítorí kí èmi lè ṣe apá kan èyí tí wọ́n ṣe ní èèwọ̀ fún yín ní ẹ̀tọ́ fún yín. Mo ti mú àmì kan wá fún yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.

51 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 051

إِنَّ ٱللَّهَ رَبِّي وَرَبُّكُمۡ فَٱعۡبُدُوهُۚ هَٰذَا صِرَٰطٞ مُّسۡتَقِيمٞ
Dájúdájú Allāhu ni Olúwa mi àti Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Un. Èyí ni ọ̀nà tààrà.”

52 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 052

۞فَلَمَّآ أَحَسَّ عِيسَىٰ مِنۡهُمُ ٱلۡكُفۡرَ قَالَ مَنۡ أَنصَارِيٓ إِلَى ٱللَّهِۖ قَالَ ٱلۡحَوَارِيُّونَ نَحۡنُ أَنصَارُ ٱللَّهِ ءَامَنَّا بِٱللَّهِ وَٱشۡهَدۡ بِأَنَّا مُسۡلِمُونَ
Nígbà tí (Ànábì) ‘Īsā fura sí àìgbàgbọ́ lọ́dọ̀ wọn (pé wọ́n fẹ́ pa òun), ó sọ pé: “Ta ni olùrànlọ́wọ́ mi sí ọ̀dọ̀ Allāhu?” Àwọn ọmọlẹ́yìn (rẹ̀) sọ pé: “Àwa ni olùrànlọ́wọ́ fún (ẹ̀sìn) Allāhu. A gba Allāhu gbọ́. Kí o sì jẹ́rìí pé dájúdájú mùsùlùmí ni wá.

53 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 053

رَبَّنَآ ءَامَنَّا بِمَآ أَنزَلۡتَ وَٱتَّبَعۡنَا ٱلرَّسُولَ فَٱكۡتُبۡنَا مَعَ ٱلشَّـٰهِدِينَ
Olúwa wa, a gbàgbọ́ nínú ohun tí O sọ̀kalẹ̀. A sì tẹ̀lé Òjíṣẹ́. Nítorí náà, kọ wá mọ́ àwọn olùjẹ́rìí.”

54 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 054

وَمَكَرُواْ وَمَكَرَ ٱللَّهُۖ وَٱللَّهُ خَيۡرُ ٱلۡمَٰكِرِينَ
Wọ́n déte, Allāhu sì déte. Allāhu sì l’óore jùlọ nínú àwọn adéte.[1]
1. Kíyè sí i, Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - kì í ṣe adéte. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:15 àti ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah as-Sọ̄ffāt; 37:125.

55 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 055

إِذۡ قَالَ ٱللَّهُ يَٰعِيسَىٰٓ إِنِّي مُتَوَفِّيكَ وَرَافِعُكَ إِلَيَّ وَمُطَهِّرُكَ مِنَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَجَاعِلُ ٱلَّذِينَ ٱتَّبَعُوكَ فَوۡقَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ إِلَىٰ يَوۡمِ ٱلۡقِيَٰمَةِۖ ثُمَّ إِلَيَّ مَرۡجِعُكُمۡ فَأَحۡكُمُ بَيۡنَكُمۡ فِيمَا كُنتُمۡ فِيهِ تَخۡتَلِفُونَ
(Ẹ rántí) nígbà tí Allāhu sọ pé: “‘Īsā, dájúdájú Mo máa gbà ọ́ kúrò lọ́wọ́ wọn pátápátá.[1] Mo máa gbé ọ wá sókè lọ́dọ̀ Mi. Mo sì máa fọ̀ ọ́ mọ́ lọ́dọ̀ àwọn tó ṣàì gbàgbọ́.² Mo sì máa fi àwọn tó tẹ̀lé ọ borí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ títí di Ọjọ́ Àjíǹde. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Mi ni ibùpadàsí yín. Mo sì máa ṣe ìdájọ́ láààrin yín nípa ohun tí ẹ̀ ń yapa ẹnu sí.
1. Wọ́n ṣẹ̀dá “mutawaffi” láti ara “wafāt/wafāh.” Ìtúmọ̀ mẹ́ta ni wafāt/wafāh ní nínú al-Ƙur’ān, hadīth àti èdè Lárúbáwá. Àwọn ìtúmọ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà nìwọ̀nyí: “maot” ikú, “naom” oorun àti “ƙọbd” gbígba n̄ǹkan tàbí gbígba ẹnì kan kúrò lọ́wọ́ ẹnì kan pátápátá. 2. Lára àṣìṣe àwọn nasọ̄rọ̄ ni bí wọ́n ṣe lérò pé àwọn gan-an ni al-Ƙur’ān ń tọ́ka sí pẹ̀lú gbólóhùn “àwọn tó tẹ̀lé ọ”, ìyẹn àwọn tó tẹ̀lé ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ rárá torí pé ẹlẹ́sìn ’Islām ni àwọn tó tẹ̀lé ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a -.

56 - Ali 'Imran (Family of Imran) - 056

فَأَمَّا ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ فَأُعَذِّبُهُمۡ عَذَابٗا شَدِيدٗا فِي ٱلدُّنۡيَا وَٱلۡأٓخِرَةِ وَمَا لَهُم مِّن نَّـٰصِرِينَ
Ní ti àwọn tó ṣ

Scroll to Top