الكهف

 

Al-Kahf

 

The Cave

1 - Al-Kahf (The Cave) - 001

ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ ٱلَّذِيٓ أَنزَلَ عَلَىٰ عَبۡدِهِ ٱلۡكِتَٰبَ وَلَمۡ يَجۡعَل لَّهُۥ عِوَجَاۜ
Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí Ó sọ Tírà kalẹ̀ fún ẹrúsìn Rẹ̀. Kò sì dojú ọ̀rọ̀ kan rú nínú rẹ̀.

2 - Al-Kahf (The Cave) - 002

قَيِّمٗا لِّيُنذِرَ بَأۡسٗا شَدِيدٗا مِّن لَّدُنۡهُ وَيُبَشِّرَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ ٱلَّذِينَ يَعۡمَلُونَ ٱلصَّـٰلِحَٰتِ أَنَّ لَهُمۡ أَجۡرًا حَسَنٗا
(Ó ṣe é ni tírà) tó dúró déédé[1] nítorí kí (Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) lè fi ṣe ìkìlọ̀ ìyà líle láti ọ̀dọ̀ (Allāhu) àti nítorí kí ó lè fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo, àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ rere ní ìró ìdùnnú pé dájúdájú ẹ̀san rere ń bẹ fún wọn (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra);
1. Ìyẹn ni pé, al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé jẹ́ tírà tí kì í gbèfún ìbàjẹ́, irọ́, àbòsí àti ìsọkúsọ.

3 - Al-Kahf (The Cave) - 003

مَّـٰكِثِينَ فِيهِ أَبَدٗا
Wọn yóò máa gbé nínú rẹ̀ lọ títí láéláé.

4 - Al-Kahf (The Cave) - 004

وَيُنذِرَ ٱلَّذِينَ قَالُواْ ٱتَّخَذَ ٱللَّهُ وَلَدٗا
Àti nítorí kí ó lè ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn tó wí pé: “Allāhu mú ẹnì kan ní ọmọ.”

5 - Al-Kahf (The Cave) - 005

مَّا لَهُم بِهِۦ مِنۡ عِلۡمٖ وَلَا لِأٓبَآئِهِمۡۚ كَبُرَتۡ كَلِمَةٗ تَخۡرُجُ مِنۡ أَفۡوَٰهِهِمۡۚ إِن يَقُولُونَ إِلَّا كَذِبٗا
Kò sí ìmọ̀ kan kan fún àwọn àti bàbá wọn nípa rẹ̀. Ọ̀rọ̀ tó ń jáde lẹ́nu wọn tóbi. Dájúdájú wọn kò wí kiní kan bí kò ṣe irọ́.

6 - Al-Kahf (The Cave) - 006

فَلَعَلَّكَ بَٰخِعٞ نَّفۡسَكَ عَلَىٰٓ ءَاثَٰرِهِمۡ إِن لَّمۡ يُؤۡمِنُواْ بِهَٰذَا ٱلۡحَدِيثِ أَسَفًا
Nítorí náà, nítorí kí ni o ṣe máa fi ìbànújẹ́ para rẹ lórí ìgbésẹ̀ wọn pé wọn kò gba ọ̀rọ̀ (al-Ƙur’ān) yìí gbọ́.

7 - Al-Kahf (The Cave) - 007

إِنَّا جَعَلۡنَا مَا عَلَى ٱلۡأَرۡضِ زِينَةٗ لَّهَا لِنَبۡلُوَهُمۡ أَيُّهُمۡ أَحۡسَنُ عَمَلٗا
Dájúdájú Àwa ṣe ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ní ọ̀ṣọ́ fún ilẹ̀ náà nítorí kí Á lè dán wọn wò (pé) èwo nínú wọn ló máa dára jùlọ níbi iṣẹ́ ṣíṣe (nínú ẹ̀sìn).

8 - Al-Kahf (The Cave) - 008

وَإِنَّا لَجَٰعِلُونَ مَا عَلَيۡهَا صَعِيدٗا جُرُزًا
Àti pé dájúdájú Àwa máa sọ n̄ǹkan tí ń bẹ lórí (ilẹ̀) di erùpẹ̀ gbígbẹ tí kò níí hu irúgbìn.

9 - Al-Kahf (The Cave) - 009

أَمۡ حَسِبۡتَ أَنَّ أَصۡحَٰبَ ٱلۡكَهۡفِ وَٱلرَّقِيمِ كَانُواْ مِنۡ ءَايَٰتِنَا عَجَبًا
Tàbí o lérò pé dájúdájú àwọn ará inú ọ̀gbun àpáta àti wàláhà orúkọ wọn jẹ́ èèmọ̀ kan nínú àwọn àmì Wa?

10 - Al-Kahf (The Cave) - 010

إِذۡ أَوَى ٱلۡفِتۡيَةُ إِلَى ٱلۡكَهۡفِ فَقَالُواْ رَبَّنَآ ءَاتِنَا مِن لَّدُنكَ رَحۡمَةٗ وَهَيِّئۡ لَنَا مِنۡ أَمۡرِنَا رَشَدٗا
(Rántí) nígbà tí àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà wá ibùgbé sínú ọ̀gbun àpáta, wọ́n sọ pé: “Olúwa wa, fún wa ní ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Rẹ, kí O ṣe ìmọ̀nà ní ìrọ̀rùn fún wa nínú ọ̀rọ̀ wa.”

11 - Al-Kahf (The Cave) - 011

فَضَرَبۡنَا عَلَىٰٓ ءَاذَانِهِمۡ فِي ٱلۡكَهۡفِ سِنِينَ عَدَدٗا
A kùn wọ́n l’óorun àsùnpiyè nínú ọ̀gbun àpáta f’ọ́dún gbọọrọ.

12 - Al-Kahf (The Cave) - 012

ثُمَّ بَعَثۡنَٰهُمۡ لِنَعۡلَمَ أَيُّ ٱلۡحِزۡبَيۡنِ أَحۡصَىٰ لِمَا لَبِثُوٓاْ أَمَدٗا
Lẹ́yìn náà, A gbé wọn dìde nítorí kí Á lè ṣàfi hàn èwo nínú ìjọ méjèèjì ló mọ gbèdéke òǹkà ọdún tó lò (nínú ọ̀gbun àpáta náà).

13 - Al-Kahf (The Cave) - 013

نَّحۡنُ نَقُصُّ عَلَيۡكَ نَبَأَهُم بِٱلۡحَقِّۚ إِنَّهُمۡ فِتۡيَةٌ ءَامَنُواْ بِرَبِّهِمۡ وَزِدۡنَٰهُمۡ هُدٗى
Àwa ń sọ ìròyìn wọn fún ọ pẹ̀lú òdodo. Dájúdájú ọ̀dọ́kùnrin ni wọ́n. Wọ́n gbàgbọ́ nínú Olúwa wọn. A sì ṣàlékún ìmọ̀nà fún wọn.

14 - Al-Kahf (The Cave) - 014

وَرَبَطۡنَا عَلَىٰ قُلُوبِهِمۡ إِذۡ قَامُواْ فَقَالُواْ رَبُّنَا رَبُّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ لَن نَّدۡعُوَاْ مِن دُونِهِۦٓ إِلَٰهٗاۖ لَّقَدۡ قُلۡنَآ إِذٗا شَطَطًا
A sì kì wọ́n lọ́kàn nígbà tí wọ́n dìde, tí wọ́n sọ pé: “Olúwa wa ni Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. A ò sì níí pe ọlọ́hun kan lẹ́yìn Rẹ̀. (Tí a bá pe ọlọ́hun kan lẹ́yìn Rẹ̀) dájúdájú nígbà náà a ti sọ̀rọ̀ tó tayọ ẹnu-ààlà.

15 - Al-Kahf (The Cave) - 015

هَـٰٓؤُلَآءِ قَوۡمُنَا ٱتَّخَذُواْ مِن دُونِهِۦٓ ءَالِهَةٗۖ لَّوۡلَا يَأۡتُونَ عَلَيۡهِم بِسُلۡطَٰنِۭ بَيِّنٖۖ فَمَنۡ أَظۡلَمُ مِمَّنِ ٱفۡتَرَىٰ عَلَى ٱللَّهِ كَذِبٗا
Àwọn ìjọ wa wọ̀nyí sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu. Kí ni kò jẹ́ kí wọ́n mú ẹ̀rí tó yanjú wá nípa wọn? Nítorí náà, ta ni ó ṣe àbòsí ju ẹni tó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu?”

16 - Al-Kahf (The Cave) - 016

وَإِذِ ٱعۡتَزَلۡتُمُوهُمۡ وَمَا يَعۡبُدُونَ إِلَّا ٱللَّهَ فَأۡوُۥٓاْ إِلَى ٱلۡكَهۡفِ يَنشُرۡ لَكُمۡ رَبُّكُم مِّن رَّحۡمَتِهِۦ وَيُهَيِّئۡ لَكُم مِّنۡ أَمۡرِكُم مِّرۡفَقٗا
(Rántí nígbà tí àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà sọ fúnra wọn pé:) nígbà tí ẹ bá yẹra fún àwọn àti n̄ǹkan tí wọ́n ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu, kí ẹ wá ibùgbé sínú ọ̀gbun àpáta, Olúwa yín yóò tẹ́ nínú ìkẹ́ Rẹ̀ sílẹ̀ fún yín. Ó sì máa ṣe ọ̀rọ̀ yín ní ìrọ̀rùn fún yín.

17 - Al-Kahf (The Cave) - 017

۞وَتَرَى ٱلشَّمۡسَ إِذَا طَلَعَت تَّزَٰوَرُ عَن كَهۡفِهِمۡ ذَاتَ ٱلۡيَمِينِ وَإِذَا غَرَبَت تَّقۡرِضُهُمۡ ذَاتَ ٱلشِّمَالِ وَهُمۡ فِي فَجۡوَةٖ مِّنۡهُۚ ذَٰلِكَ مِنۡ ءَايَٰتِ ٱللَّهِۗ مَن يَهۡدِ ٱللَّهُ فَهُوَ ٱلۡمُهۡتَدِۖ وَمَن يُضۡلِلۡ فَلَن تَجِدَ لَهُۥ وَلِيّٗا مُّرۡشِدٗا
O máa rí òòrùn nígbà tí ó bá yọ, ó máa yẹ̀bá kúrò níbi ọ̀gbun wọn sí ọwọ́ ọ̀tún. Nígbà tí ó bá tún wọ̀, ó máa fi wọ́n sílẹ̀ sí ọwọ́ òsì. Wọ́n sì wà nínú àyè tí ó fẹjú nínú ọ̀gbun àpáta. Ìyẹn wà nínú àwọn àmì Allāhu. Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fi mọ̀nà (’Islām), òun ni olùmọ̀nà. Ẹnikẹ́ni tí Ó bá ṣì lọ́nà, o ò sì níí rí olùrànlọ́wọ́ atọ́ni-sọ́nà kan fún un.

18 - Al-Kahf (The Cave) - 018

وَتَحۡسَبُهُمۡ أَيۡقَاظٗا وَهُمۡ رُقُودٞۚ وَنُقَلِّبُهُمۡ ذَاتَ ٱلۡيَمِينِ وَذَاتَ ٱلشِّمَالِۖ وَكَلۡبُهُم بَٰسِطٞ ذِرَاعَيۡهِ بِٱلۡوَصِيدِۚ لَوِ ٱطَّلَعۡتَ عَلَيۡهِمۡ لَوَلَّيۡتَ مِنۡهُمۡ فِرَارٗا وَلَمُلِئۡتَ مِنۡهُمۡ رُعۡبٗا
(Tí o bá rí wọn), ó máa lérò pé wọ́n kò sí lójú oorun, ojú oorun ni wọ́n sì wà. A sì ń yí wọn ní ẹ̀gbẹ́ padà sí ọ̀tún àti sí òsì. Ajá wọn sì na apá rẹ̀ méjèèjì sílẹ̀ ní ẹnu-ọ̀nà. Tí ó bá jẹ́ pé o yọjú wò wọ́n ni, ìwọ ìbá pẹ̀yìndà láti họ fún wọn, ìwọ ìbá sì kún fún ìbẹ̀rù-bojo láti ara wọn.

19 - Al-Kahf (The Cave) - 019

وَكَذَٰلِكَ بَعَثۡنَٰهُمۡ لِيَتَسَآءَلُواْ بَيۡنَهُمۡۚ قَالَ قَآئِلٞ مِّنۡهُمۡ كَمۡ لَبِثۡتُمۡۖ قَالُواْ لَبِثۡنَا يَوۡمًا أَوۡ بَعۡضَ يَوۡمٖۚ قَالُواْ رَبُّكُمۡ أَعۡلَمُ بِمَا لَبِثۡتُمۡ فَٱبۡعَثُوٓاْ أَحَدَكُم بِوَرِقِكُمۡ هَٰذِهِۦٓ إِلَى ٱلۡمَدِينَةِ فَلۡيَنظُرۡ أَيُّهَآ أَزۡكَىٰ طَعَامٗا فَلۡيَأۡتِكُم بِرِزۡقٖ مِّنۡهُ وَلۡيَتَلَطَّفۡ وَلَا يُشۡعِرَنَّ بِكُمۡ أَحَدًا
Báyẹn (ni wọ́n wà) tí A fi gbé wọn dìde padà nítorí kí wọ́n lè bi ara wọn léèrè ìbéèrè. Òǹsọ̀rọ̀ kan nínú wọn sọ pé: “Ìgbà wo lẹ ti wà níbí?” Wọ́n sọ pé: “A wà níbí fún ọjọ́ kan tàbí apá kan nínú ọjọ́.” Wọ́n sọ pé: “Olúwa yín lÓ nímọ̀ jùlọ nípa ìgbà tí ẹ ti wà níbí.” Nítorí náà, ẹ gbé ọ̀kan nínú yín dìde lọ sí inú ìlú pẹ̀lú owó fàdákà yín yìí. Kí ó wo èwó nínú oúnjẹ ìlú ló mọ́ jùlọ, kí ó sì mú àsè wá fún yín nínú rẹ̀. Kí ó ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, kò sì gbọdọ̀ jẹ́ kí ẹnì kan kan fura si yín.

20 - Al-Kahf (The Cave) - 020

إِنَّهُمۡ إِن يَظۡهَرُواْ عَلَيۡكُمۡ يَرۡجُمُوكُمۡ أَوۡ يُعِيدُوكُمۡ فِي مِلَّتِهِمۡ وَلَن تُفۡلِحُوٓاْ إِذًا أَبَدٗا
(Nítorí pé) dájúdájú tí wọ́n bá fi lè mọ̀ nípa yín, wọn yóò jù yín lókò tàbí kí wọ́n da yín padà sínú ẹ̀sìn wọn. (Tí ó bá sì fi rí bẹ́ẹ̀) nígbà náà, ẹ kò níí jèrè mọ́ láéláé.

21 - Al-Kahf (The Cave) - 021

وَكَذَٰلِكَ أَعۡثَرۡنَا عَلَيۡهِمۡ لِيَعۡلَمُوٓاْ أَنَّ وَعۡدَ ٱللَّهِ حَقّٞ وَأَنَّ ٱلسَّاعَةَ لَا رَيۡبَ فِيهَآ إِذۡ يَتَنَٰزَعُونَ بَيۡنَهُمۡ أَمۡرَهُمۡۖ فَقَالُواْ ٱبۡنُواْ عَلَيۡهِم بُنۡيَٰنٗاۖ رَّبُّهُمۡ أَعۡلَمُ بِهِمۡۚ قَالَ ٱلَّذِينَ غَلَبُواْ عَلَىٰٓ أَمۡرِهِمۡ لَنَتَّخِذَنَّ عَلَيۡهِم مَّسۡجِدٗا
Báyẹn ni A ṣe jẹ́ kí àwọn ènìyàn rí wọn nítorí kí wọ́n lè mọ̀ pé dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Àti pé dájúdájú Àkókò náà kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Rántí (nígbà tí àwọn ènìyàn) ń ṣe àríyànjiyàn láààrin ara wọn nípa ọ̀rọ̀ wọn. Wọ́n sọ pé: “Ẹ mọ ilé kan lé wọn lórí. Olúwa wọn lÓ nímọ̀ jùlọ nípa wọn.” Àwọn tó borí lórí ọ̀rọ̀ wọn sì wí pé: “Dájúdájú a máa sọ orí àpáta wọn di mọ́sálásí.”[1]
1. Āyah yìí kò sọ kíkọ́ mọ́sálásí sórí sàréè di ẹ̀tọ́ bí kò ṣe pé, ó ń sọ nípa ohun tí àwọn oníjàgídíjàgan kan ṣe lásìkò náà.

22 - Al-Kahf (The Cave) - 022

سَيَقُولُونَ ثَلَٰثَةٞ رَّابِعُهُمۡ كَلۡبُهُمۡ وَيَقُولُونَ خَمۡسَةٞ سَادِسُهُمۡ كَلۡبُهُمۡ رَجۡمَۢا بِٱلۡغَيۡبِۖ وَيَقُولُونَ سَبۡعَةٞ وَثَامِنُهُمۡ كَلۡبُهُمۡۚ قُل رَّبِّيٓ أَعۡلَمُ بِعِدَّتِهِم مَّا يَعۡلَمُهُمۡ إِلَّا قَلِيلٞۗ فَلَا تُمَارِ فِيهِمۡ إِلَّا مِرَآءٗ ظَٰهِرٗا وَلَا تَسۡتَفۡتِ فِيهِم مِّنۡهُمۡ أَحَدٗا
Wọ́n ń wí pé: “Mẹ́ta ni wọ́n. Ajá wọn ṣe ìkẹrin wọn.” Wọ́n tún ń wí pé: “Márùn-ún ni wọ́n. Ajá wọn ṣe ìkẹfà wọn.” Ọ̀rọ̀ tó pamọ́ fún wọn ni wọ́n ń sọ, (wọ́n ń dá àbá ni). Wọ́n tún ń wí pé: “Méje ni wọ́n. Ajá wọn ṣe ìkẹjọ wọn.” Sọ pé: “Olúwa mi lÓ nímọ̀ jùlọ nípa òǹkà wọn. Kò sí (ẹni tí) ó mọ (òǹkà) wọn àfi àwọn díẹ̀. Nítorí náà, má ṣe bá wọn ṣe àríyànjiyàn nípa (òǹkà) wọn àfi (kí o fi) àríyànjiyàn (náà tì síbi ẹ̀rí) tó yanjú (tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ yìí). Má sì ṣe bi ẹnì kan nínú wọn léèrè nípa (òǹkà) wọn.”

23 - Al-Kahf (The Cave) - 023

وَلَا تَقُولَنَّ لِشَاْيۡءٍ إِنِّي فَاعِلٞ ذَٰلِكَ غَدًا
Má ṣe sọ nípa kiní kan pé: “Dájúdájú èmi yóò ṣe ìyẹn ní ọ̀la.”

24 - Al-Kahf (The Cave) - 024

إِلَّآ أَن يَشَآءَ ٱللَّهُۚ وَٱذۡكُر رَّبَّكَ إِذَا نَسِيتَ وَقُلۡ عَسَىٰٓ أَن يَهۡدِيَنِ رَبِّي لِأَقۡرَبَ مِنۡ هَٰذَا رَشَدٗا
Àyàfi (kí o fi kún un pé) “tí Allāhu bá fẹ́.” Ṣe ìrántí Olúwa rẹ nígbà tí o bá gbàgbé (láti sọ bẹ́ẹ̀ lásìkò náà). Kí o sì sọ (fún wọn) pé: “Ó rọrùn kí Olúwa mi tọ́ mi sọ́nà lórí rẹ̀ pẹ̀lú èyí tí ó súnmọ́ jù èyí lọ ní ìmọ̀nà (fún yín).”[1]
1. Okùnfà āyah yìí ni pé, nígbà tí àwọn yẹhudi wá bi Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - léèrè nípa ọ̀rọ̀ àwọn ará inú ọ̀gbun àpáta pẹ̀lú èròǹgbà wọn pé tí ó bá jẹ́ Ànábì Ọlọ́hun ní ti òdodo, ó yẹ kí ó nímọ̀ nípa wọn, Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sì sọ fún wọn pé kí wọ́n wá gbọ́ ìtàn wọn ní ọjọ́ kejì pẹ̀lú èròǹgbà rẹ̀ pé Allāhu á ti fi ìmísí nípa wọn ránṣẹ́ sí òun. Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - kò sì sọ fún àwọn yẹhudi náà pé “tí Allāhu bá fẹ́.” Àmọ́ àì sọ bẹ́ẹ̀ rẹ̀ jẹ́ kí ọjọ́ àdéhùn tó ṣe fún wọn yẹ̀.

25 - Al-Kahf (The Cave) - 025

وَلَبِثُواْ فِي كَهۡفِهِمۡ ثَلَٰثَ مِاْئَةٖ سِنِينَ وَٱزۡدَادُواْ تِسۡعٗا
Wọ́n wà nínú ọ̀gbun àpáta wọn fún ọ̀ọ́dúnrún ọdún. Wọ́n tún lo àlékún ọdún mẹ́sàn-án.

26 - Al-Kahf (The Cave) - 026

قُلِ ٱللَّهُ أَعۡلَمُ بِمَا لَبِثُواْۖ لَهُۥ غَيۡبُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۖ أَبۡصِرۡ بِهِۦ وَأَسۡمِعۡۚ مَا لَهُم مِّن دُونِهِۦ مِن وَلِيّٖ وَلَا يُشۡرِكُ فِي حُكۡمِهِۦٓ أَحَدٗا
Sọ pé: “Allāhu lÓ nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n lò (nínú ọ̀gbun àpáta). TiRẹ̀ ni ìkọ̀kọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Kì ni kò rí tán, kì sí ni kò gbọ́ tán! Kò sí aláàbò kan fún wọn lẹ́yìn Rẹ̀. Kò sì fi ẹnì kan ṣe akẹgbẹ́ nínú ìdájọ́ Rẹ̀.”

27 - Al-Kahf (The Cave) - 027

وَٱتۡلُ مَآ أُوحِيَ إِلَيۡكَ مِن كِتَابِ رَبِّكَۖ لَا مُبَدِّلَ لِكَلِمَٰتِهِۦ وَلَن تَجِدَ مِن دُونِهِۦ مُلۡتَحَدٗا
Ké ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ nínú Tírà Olúwa rẹ. Kò sí ẹni tí ó lè yí àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀ padà. Ìwọ kò sì lè rí ibùsásí kan lẹ́yìn ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

28 - Al-Kahf (The Cave) - 028

وَٱصۡبِرۡ نَفۡسَكَ مَعَ ٱلَّذِينَ يَدۡعُونَ رَبَّهُم بِٱلۡغَدَوٰةِ وَٱلۡعَشِيِّ يُرِيدُونَ وَجۡهَهُۥۖ وَلَا تَعۡدُ عَيۡنَاكَ عَنۡهُمۡ تُرِيدُ زِينَةَ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَاۖ وَلَا تُطِعۡ مَنۡ أَغۡفَلۡنَا قَلۡبَهُۥ عَن ذِكۡرِنَا وَٱتَّبَعَ هَوَىٰهُ وَكَانَ أَمۡرُهُۥ فُرُطٗا
Ṣe sùúrù fún ẹ̀mí rẹ láti wà pẹ̀lú àwọn tó ń pe Olúwa wọn ní òwúrọ̀ àti ní àṣálẹ́, tí wọ́n ń wá Ojú rere Rẹ̀. Má ṣe fojú pa wọ́n rẹ́ láti wá ọ̀ṣọ́ ìṣẹ̀mí ayé (yìí). Má sì ṣe tẹ̀lé ẹni tí A mú ọkàn rẹ̀ gbàgbé ìrántí Wa. Ó tẹ̀lé ìfẹ́-inú rẹ̀; ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ àṣejù.[1]
1. Àwọn onisūfi lérò pé āyah yìí gbè fún àwọn. Ọ̀rọ̀ kò sì rí bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al- ’An‘ām; 6:52 fún àgbọ́yé āyah yìí.

29 - Al-Kahf (The Cave) - 029

وَقُلِ ٱلۡحَقُّ مِن رَّبِّكُمۡۖ فَمَن شَآءَ فَلۡيُؤۡمِن وَمَن شَآءَ فَلۡيَكۡفُرۡۚ إِنَّآ أَعۡتَدۡنَا لِلظَّـٰلِمِينَ نَارًا أَحَاطَ بِهِمۡ سُرَادِقُهَاۚ وَإِن يَسۡتَغِيثُواْ يُغَاثُواْ بِمَآءٖ كَٱلۡمُهۡلِ يَشۡوِي ٱلۡوُجُوهَۚ بِئۡسَ ٱلشَّرَابُ وَسَآءَتۡ مُرۡتَفَقًا
Sọ pé: “Òdodo (nìyí) láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó gbàgbọ́ ní òdodo. Ẹni tí ó bá sì fẹ́ kí ó ṣàì gbàgbọ́. Dájúdájú Àwa pèsè Iná sílẹ̀ de àwọn alábòsí, tí ọgbà rẹ̀ yóò yí wọn po. Tí wọ́n bá ń tọrọ omi mímu, A óò fún wọn ní omi mímu kan tó dà bí ògéré epo gbígbóná, tí (ìgbóná rẹ̀) yó sì máa ṣe àwọn ojú. Ohun mímu náà burú. Ó sì burú ní ibùkójọ.

30 - Al-Kahf (The Cave) - 030

إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّـٰلِحَٰتِ إِنَّا لَا نُضِيعُ أَجۡرَ مَنۡ أَحۡسَنَ عَمَلًا
Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, dájúdájú Àwa kò níí fi ẹ̀san ẹni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere ráre.

31 - Al-Kahf (The Cave) - 031

أُوْلَـٰٓئِكَ لَهُمۡ جَنَّـٰتُ عَدۡنٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهِمُ ٱلۡأَنۡهَٰرُ يُحَلَّوۡنَ فِيهَا مِنۡ أَسَاوِرَ مِن ذَهَبٖ وَيَلۡبَسُونَ ثِيَابًا خُضۡرٗا مِّن سُندُسٖ وَإِسۡتَبۡرَقٖ مُّتَّكِـِٔينَ فِيهَا عَلَى ٱلۡأَرَآئِكِۚ نِعۡمَ ٱلثَّوَابُ وَحَسُنَتۡ مُرۡتَفَقٗا
Àwọn wọ̀nyẹn, tiwọn ni àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra ‘Adn, tí àwọn odò yóò máa ṣàn ní ìsàlẹ̀ wọn. Wọn máa ṣe wọ́n ní ọ̀ṣọ́ nínú rẹ̀ pẹ̀lú àwọn n̄ǹkan ọwọ́ látara wúrà. Wọn yóò máa wọ aṣọ àrán aláwọ̀ ewéko (èyí tí ó) fẹ́lẹ́ àti (èyí tí) ó nípọn. Wọn yó sì máa rọ̀gbọ̀kú lórí ibùsùn ọlá nínú (Ọgbà Ìdẹ̀ra). Ẹ̀san náà dára. Ó sì dára ní ibùkójọ.

32 - Al-Kahf (The Cave) - 032

۞وَٱضۡرِبۡ لَهُم مَّثَلٗا رَّجُلَيۡنِ جَعَلۡنَا لِأَحَدِهِمَا جَنَّتَيۡنِ مِنۡ أَعۡنَٰبٖ وَحَفَفۡنَٰهُمَا بِنَخۡلٖ وَجَعَلۡنَا بَيۡنَهُمَا زَرۡعٗا
Fi àwọn ọkùnrin méjì kan ṣe àpẹ̀ẹrẹ fún wọn; A fún ọ̀kan nínú wọn ní ọgbà èso àjàrà méjì. A sì fi àwọn igi dàbínù yí wọn ká. A tún fi àwọn igi eléso là wọ́n láààrin.

33 - Al-Kahf (The Cave) - 033

كِلۡتَا ٱلۡجَنَّتَيۡنِ ءَاتَتۡ أُكُلَهَا وَلَمۡ تَظۡلِم مِّنۡهُ شَيۡـٔٗاۚ وَفَجَّرۡنَا خِلَٰلَهُمَا نَهَرٗا
Ìkíní kejì àwọn ọgbà èso méjèèjì ń so èso wọn. Àwọn èso rẹ̀ kì í pẹ̀ dín. A sì jẹ́ kí odò ṣàn kọjá láààrin oko méjèèjì.

34 - Al-Kahf (The Cave) - 034

وَكَانَ لَهُۥ ثَمَرٞ فَقَالَ لِصَٰحِبِهِۦ وَهُوَ يُحَاوِرُهُۥٓ أَنَا۠ أَكۡثَرُ مِنكَ مَالٗا وَأَعَزُّ نَفَرٗا
Ó ní èso (sẹ́). Ó sì sọ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ nígbà tí ó ń bá a jiyàn (báyìí) pé: “Èmi ní dúkìá lọ́wọ́ jù ọ́ lọ. Mo tún fi àwọn ènìyàn ní agbára jù ọ́ lọ.”

35 - Al-Kahf (The Cave) - 035

وَدَخَلَ جَنَّتَهُۥ وَهُوَ ظَالِمٞ لِّنَفۡسِهِۦ قَالَ مَآ أَظُنُّ أَن تَبِيدَ هَٰذِهِۦٓ أَبَدٗا
Ó wọ inú oko rẹ̀ ní ẹni tí ó ń ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara rẹ̀, ó wí pé: “Èmi kò lérò pé èyí máa parun láéláé.

36 - Al-Kahf (The Cave) - 036

وَمَآ أَظُنُّ ٱلسَّاعَةَ قَآئِمَةٗ وَلَئِن رُّدِدتُّ إِلَىٰ رَبِّي لَأَجِدَنَّ خَيۡرٗا مِّنۡهَا مُنقَلَبٗا
Èmi kò sì lérò pé Àkókò (àjíǹde) náà máa ṣẹlẹ̀. Àti pé tí wọ́n bá tiẹ̀ dá mi padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa mi, dájúdájú mo tún máa rí ibùdésí tó dára ju èyí lọ.”

37 - Al-Kahf (The Cave) - 037

قَالَ لَهُۥ صَاحِبُهُۥ وَهُوَ يُحَاوِرُهُۥٓ أَكَفَرۡتَ بِٱلَّذِي خَلَقَكَ مِن تُرَابٖ ثُمَّ مِن نُّطۡفَةٖ ثُمَّ سَوَّىٰكَ رَجُلٗا
Ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ fún un nígbà tí ó ń jà á níyàn (báyìí) pé: “Ṣé o máa ṣàì gbàgbọ́ nínú Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá rẹ láti inú erùpẹ̀, lẹ́yìn náà, láti inú àtọ̀. Lẹ́yìn náà, Ó ṣe ọ́ ní ọkùnrin tó pé ní ẹ̀dá.

38 - Al-Kahf (The Cave) - 038

لَّـٰكِنَّا۠ هُوَ ٱللَّهُ رَبِّي وَلَآ أُشۡرِكُ بِرَبِّيٓ أَحَدٗا
Ṣùgbọ́n ní tèmi, Olúwa mi, Òun ni Allāhu. Èmi kò sì níí sọ ẹnì kan di akẹgbẹ́ fún Olúwa mi.

39 - Al-Kahf (The Cave) - 039

وَلَوۡلَآ إِذۡ دَخَلۡتَ جَنَّتَكَ قُلۡتَ مَا شَآءَ ٱللَّهُ لَا قُوَّةَ إِلَّا بِٱللَّهِۚ إِن تَرَنِ أَنَا۠ أَقَلَّ مِنكَ مَالٗا وَوَلَدٗا
Nígbà tí o wọ inú ọgbà oko rẹ, kí ni kò mú ọ sọ pé: “Ohun tí Allāhu bá fẹ́! Kò sí agbára kan bí kò ṣe pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Tí o bá sì rí èmi pé mo kéré sí ọ ní dúkìá àti ọmọ,

40 - Al-Kahf (The Cave) - 040

فَعَسَىٰ رَبِّيٓ أَن يُؤۡتِيَنِ خَيۡرٗا مِّن جَنَّتِكَ وَيُرۡسِلَ عَلَيۡهَا حُسۡبَانٗا مِّنَ ٱلسَّمَآءِ فَتُصۡبِحَ صَعِيدٗا زَلَقًا
ó súnmọ́ kí Olúwa mi fún èmi náà ní oore kan tí ó máa dára ju ọgbà oko tìrẹ. (Ó sì súnmọ́) kí Ó sọ ìyà kan kalẹ̀ sínú ọgbà oko rẹ láti sánmọ̀; ó sì máa di ilẹ̀ aṣálẹ̀.

41 - Al-Kahf (The Cave) - 041

أَوۡ يُصۡبِحَ مَآؤُهَا غَوۡرٗا فَلَن تَسۡتَطِيعَ لَهُۥ طَلَبٗا
Tàbí kí omi rẹ̀ gbẹ. O ò sì níí lè wá omi kàn.”

42 - Al-Kahf (The Cave) - 042

وَأُحِيطَ بِثَمَرِهِۦ فَأَصۡبَحَ يُقَلِّبُ كَفَّيۡهِ عَلَىٰ مَآ أَنفَقَ فِيهَا وَهِيَ خَاوِيَةٌ عَلَىٰ عُرُوشِهَا وَيَقُولُ يَٰلَيۡتَنِي لَمۡ أُشۡرِكۡ بِرَبِّيٓ أَحَدٗا
Wọ́n sì pa èso rẹ̀ run pátápátá. Ó sì di ẹni tó ń fí ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lura wọn pẹ́ẹ́pẹ́[1] nípa ohun tí ó ti ná sórí rẹ̀. (Àwọn ilé rẹ̀) dàwó lulẹ̀ tòrùlé-tòrùlé wọn. Ó sì ń wí pé: “Yéè! Èmi ìbá tí sọ ẹnì kan kan di akẹgbẹ́ fún Olúwa mi. (Èmi ìbá má ṣẹbọ)”
1. “ó ń fí ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lura wọn pẹ́ẹ́pẹ́” ó ń ká àbámọ̀.

43 - Al-Kahf (The Cave) - 043

وَلَمۡ تَكُن لَّهُۥ فِئَةٞ يَنصُرُونَهُۥ مِن دُونِ ٱللَّهِ وَمَا كَانَ مُنتَصِرًا
Kò ní ìjọ kan tí ó máa ràn án lọ́wọ́ mọ́ lẹ́yìn Allāhu. Kò sì lè ran ara rẹ̀ lọ́wọ́.

44 - Al-Kahf (The Cave) - 044

هُنَالِكَ ٱلۡوَلَٰيَةُ لِلَّهِ ٱلۡحَقِّۚ هُوَ خَيۡرٞ ثَوَابٗا وَخَيۡرٌ عُقۡبٗا
Níbẹ̀ yẹn, ti Allāhu, Ọba Òdodo ni àrànṣe. Ó lóore jùlọ ní ẹ̀san, Ó sì lóore jùlọ ní ìkángun (rere).

45 - Al-Kahf (The Cave) - 045

وَٱضۡرِبۡ لَهُم مَّثَلَ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا كَمَآءٍ أَنزَلۡنَٰهُ مِنَ ٱلسَّمَآءِ فَٱخۡتَلَطَ بِهِۦ نَبَاتُ ٱلۡأَرۡضِ فَأَصۡبَحَ هَشِيمٗا تَذۡرُوهُ ٱلرِّيَٰحُۗ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ مُّقۡتَدِرًا
Ṣe àkàwé ilé ayé fún wọn; ó dà bí omi tí A sọ̀kalẹ̀ láti sánmọ̀. Lẹ́yìn náà, ó ròpọ̀ mọ́ irúgbìn ilẹ̀. Lẹ́yìn náà, (irúgbìn) di gbígbẹ, tí atẹ́gùn ń fọ́nká. Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.

46 - Al-Kahf (The Cave) - 046

ٱلۡمَالُ وَٱلۡبَنُونَ زِينَةُ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَاۖ وَٱلۡبَٰقِيَٰتُ ٱلصَّـٰلِحَٰتُ خَيۡرٌ عِندَ رَبِّكَ ثَوَابٗا وَخَيۡرٌ أَمَلٗا
Ọ̀ṣọ́ ìṣẹ̀mí ayé ni dúkìá àti àwọn ọmọ. Àwọn iṣẹ́ rere tó máa wà títí láéláé lóore jùlọ ní ẹ̀san lọ́dọ̀ Olúwa rẹ, ó sì lóore jùlọ ní ìrètí.

47 - Al-Kahf (The Cave) - 047

وَيَوۡمَ نُسَيِّرُ ٱلۡجِبَالَ وَتَرَى ٱلۡأَرۡضَ بَارِزَةٗ وَحَشَرۡنَٰهُمۡ فَلَمۡ نُغَادِرۡ مِنۡهُمۡ أَحَدٗا
(Rántí) ọjọ́ tí A máa mú àwọn àpáta rìn (kúrò ní àyè wọn). O sì máa rí ilẹ̀ tí ó máa fojú hàn (tí kò níí sí n̄ǹkan kan mọ́ lórí rẹ̀). A máa kó wọn jọ. A ò sì níí fi ẹnì kan sílẹ̀ nínú wọn.

48 - Al-Kahf (The Cave) - 048

وَعُرِضُواْ عَلَىٰ رَبِّكَ صَفّٗا لَّقَدۡ جِئۡتُمُونَا كَمَا خَلَقۡنَٰكُمۡ أَوَّلَ مَرَّةِۭۚ بَلۡ زَعَمۡتُمۡ أَلَّن نَّجۡعَلَ لَكُم مَّوۡعِدٗا
Wọn yó sì kó wọn wá síwájú Olúwa rẹ ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. Dájúdájú ẹ ti wá bá Wa (báyìí) gẹ́gẹ́ bí A ṣe da yín nígbà àkọ́kọ́. Àmọ́ ẹ sọ láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́ pé A ò níí mú ọjọ́ àdéhùn ṣẹ fún yín.

49 - Al-Kahf (The Cave) - 049

وَوُضِعَ ٱلۡكِتَٰبُ فَتَرَى ٱلۡمُجۡرِمِينَ مُشۡفِقِينَ مِمَّا فِيهِ وَيَقُولُونَ يَٰوَيۡلَتَنَا مَالِ هَٰذَا ٱلۡكِتَٰبِ لَا يُغَادِرُ صَغِيرَةٗ وَلَا كَبِيرَةً إِلَّآ أَحۡصَىٰهَاۚ وَوَجَدُواْ مَا عَمِلُواْ حَاضِرٗاۗ وَلَا يَظۡلِمُ رَبُّكَ أَحَدٗا
A máa gbé ìwé iṣẹ́ ẹ̀dá kalẹ̀ (fún wọn). Nígbà náà, o máa rí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí wọn yóò máa bẹ̀rù nípa ohun tí ń bẹ nínú ìwé iṣẹ́ wọn. Wọn yóò wí pé: “Ègbé wa! Kí ló mú ìwé yìí ná; kò fi ohun kékeré àti ńlá kan sílẹ̀ láì kọ ọ́ sílẹ̀?” Wọ́n sì bá ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ níbẹ̀. Olúwa rẹ kò sì níí ṣàbòsí sí ẹnì kan.

50 - Al-Kahf (The Cave) - 050

وَإِذۡ قُلۡنَا لِلۡمَلَـٰٓئِكَةِ ٱسۡجُدُواْ لِأٓدَمَ فَسَجَدُوٓاْ إِلَّآ إِبۡلِيسَ كَانَ مِنَ ٱلۡجِنِّ فَفَسَقَ عَنۡ أَمۡرِ رَبِّهِۦٓۗ أَفَتَتَّخِذُونَهُۥ وَذُرِّيَّتَهُۥٓ أَوۡلِيَآءَ مِن دُونِي وَهُمۡ لَكُمۡ عَدُوُّۢۚ بِئۡسَ لِلظَّـٰلِمِينَ بَدَلٗا
(Rántí) nígbà tí A sọ fún àwọn mọlāika pé: “Ẹ forí kanlẹ̀ kí (Ànábì) Ādam.” Wọ́n sì forí kanlẹ̀ kí i àfi ’Iblīs, (tí) ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn àlùjànnú. Ó sì yapa sí àṣẹ Olúwa rẹ̀. Nítorí náà, ṣé ẹ máa mú òun àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ ní aláfẹ̀yìntì lẹ́yìn Mi ni, ọ̀tá yín sì ni wọ́n. Pàṣípààrọ̀ tó burú ni fún àwọn alábòsí.[1]
1. Ìyẹn ni pé, aburú ni fún ẹni tí ó mú aṣ-ṣaetọ̄n ní aláfẹ̀yìntì rẹ̀ dípò Allāhu.

51 - Al-Kahf (The Cave) - 051

۞مَّآ أَشۡهَدتُّهُمۡ خَلۡقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَلَا خَلۡقَ أَنفُسِهِمۡ وَمَا كُنتُ مُتَّخِذَ ٱلۡمُضِلِّينَ عَضُدٗا
Èmi kò fi wọ́n ṣe ẹlẹ́rìí sí ìṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, àti ìṣẹ̀dá àwọn gan-an alára. Èmi kò sì mú àwọn aṣinilọ́nà ní olùrànlọ́wọ́.[1]
1. Ó ṣe wá jẹ́ tí ẹ̀ ń sọ wọ́n di akẹgbẹ́ Mi?

52 - Al-Kahf (The Cave) - 052

وَيَوۡمَ يَقُولُ نَادُواْ شُرَكَآءِيَ ٱلَّذِينَ زَعَمۡتُمۡ فَدَعَوۡهُمۡ فَلَمۡ يَسۡتَجِيبُواْ لَهُمۡ وَجَعَلۡنَا بَيۡنَهُم مَّوۡبِقٗا
(Rántí) ọjọ́ tí (Allāhu) yóò sọ pé: “Ẹ pe àwọn akẹgbẹ́ Mi tí ẹ sọ nípa wọn láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́ (pé olùṣìpẹ̀ ni wọ́n).” Wọ́n pè wọ́n. Wọn kò sì dá wọn lóhùn. A sì ti fi àyè ìparun sáààrin wọn.

53 - Al-Kahf (The Cave) - 053

وَرَءَا ٱلۡمُجۡرِمُونَ ٱلنَّارَ فَظَنُّوٓاْ أَنَّهُم مُّوَاقِعُوهَا وَلَمۡ يَجِدُواْ عَنۡهَا مَصۡرِفٗا
Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sì rí Iná. Wọ́n sì mọ̀ dájúdájú pé àwọn yóò kó sínú rẹ̀. Wọn kò sì rí ibùsásí kan kúrò nínú rẹ̀.

54 - Al-Kahf (The Cave) - 054

وَلَقَدۡ صَرَّفۡنَا فِي هَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانِ لِلنَّاسِ مِن كُلِّ مَثَلٖۚ وَكَانَ ٱلۡإِنسَٰنُ أَكۡثَرَ شَيۡءٖ جَدَلٗا
Dájúdájú A ti ṣe àlàyé oníran-ànran sínú al-Ƙur’ān fún àwọn ènìyàn pẹ̀lú gbogbo àkàwé. Ènìyàn sì jẹ́ olùjiyàn ju ohunkóhun lọ.

55 - Al-Kahf (The Cave) - 055

وَمَا مَنَعَ ٱلنَّاسَ أَن يُؤۡمِنُوٓاْ إِذۡ جَآءَهُمُ ٱلۡهُدَىٰ وَيَسۡتَغۡفِرُواْ رَبَّهُمۡ إِلَّآ أَن تَأۡتِيَهُمۡ سُنَّةُ ٱلۡأَوَّلِينَ أَوۡ يَأۡتِيَهُمُ ٱلۡعَذَابُ قُبُلٗا
Kò sí ohun tó dí àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti gbàgbọ́ ní òdodo nígbà tí ìmọ̀nà dé bá wọn, (kò sì sí ohun tó dí wọn lọ́wọ́ láti) tọrọ àforíjìn Olúwa wọn, bí kò ṣe pé (wọ́n fẹ́) kí ìṣe (Allāhu nípa ìparun) àwọn ẹni àkọ́kọ́ dé bá àwọn náà tàbí kí ìyà dé bá wọn ní ojúkojú.

56 - Al-Kahf (The Cave) - 056

وَمَا نُرۡسِلُ ٱلۡمُرۡسَلِينَ إِلَّا مُبَشِّرِينَ وَمُنذِرِينَۚ وَيُجَٰدِلُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بِٱلۡبَٰطِلِ لِيُدۡحِضُواْ بِهِ ٱلۡحَقَّۖ وَٱتَّخَذُوٓاْ ءَايَٰتِي وَمَآ أُنذِرُواْ هُزُوٗا
Àti pé A kò rán àwọn Òjíṣẹ́ níṣẹ́ (lásán) àfi kí wọ́n jẹ́ oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀. Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ sì ń fi irọ́ ṣàtakò nítorí kí wọ́n lè fi ba òdodo jẹ́. Wọ́n sì sọ àwọn āyah Mi àti ohun tí A fi ṣèkìlọ̀ fún wọn di yẹ̀yẹ́.

57 - Al-Kahf (The Cave) - 057

وَمَنۡ أَظۡلَمُ مِمَّن ذُكِّرَ بِـَٔايَٰتِ رَبِّهِۦ فَأَعۡرَضَ عَنۡهَا وَنَسِيَ مَا قَدَّمَتۡ يَدَاهُۚ إِنَّا جَعَلۡنَا عَلَىٰ قُلُوبِهِمۡ أَكِنَّةً أَن يَفۡقَهُوهُ وَفِيٓ ءَاذَانِهِمۡ وَقۡرٗاۖ وَإِن تَدۡعُهُمۡ إِلَى ٱلۡهُدَىٰ فَلَن يَهۡتَدُوٓاْ إِذًا أَبَدٗا
Ta sì ló ṣàbòsí ju ẹni tí wọ́n fi àwọn āyah Olúwa rẹ̀ ṣèrántí fún, tí ó gbúnrí kúrò níbẹ̀, tí ó sì gbàgbé ohun tí ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì tì síwájú? Dájúdájú Àwa fi èbìbò bo ọkàn wọn nítorí kí wọ́n má baà gbọ́ ọ yé. A sì fi èdídí sínú etí wọn. Tí ìwọ bá pè wọ́n síbi ìmọ̀nà, nígbà náà wọn kò sì níí mọ̀nà láéláé.

58 - Al-Kahf (The Cave) - 058

وَرَبُّكَ ٱلۡغَفُورُ ذُو ٱلرَّحۡمَةِۖ لَوۡ يُؤَاخِذُهُم بِمَا كَسَبُواْ لَعَجَّلَ لَهُمُ ٱلۡعَذَابَۚ بَل لَّهُم مَّوۡعِدٞ لَّن يَجِدُواْ مِن دُونِهِۦ مَوۡئِلٗا
Olúwa rẹ ni Aláforíjìn, Oníkẹ̀ẹ́. Bí ó bá jẹ́ pé Ó máa fi ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ mú wọn ni, ìbá tètè mú ìyà wá fún wọn. Ṣùgbọ́n àkókò àdéhùn (àjíǹde) wà fún wọn. Wọn kò sì níí rí ibùsásí kan lẹ́yìn rẹ̀.

59 - Al-Kahf (The Cave) - 059

وَتِلۡكَ ٱلۡقُرَىٰٓ أَهۡلَكۡنَٰهُمۡ لَمَّا ظَلَمُواْ وَجَعَلۡنَا لِمَهۡلِكِهِم مَّوۡعِدٗا
Ìwọ́nyí ni àwọn ìlú tí A ti parẹ́ nígbà tí wọ́n ṣàbòsí. A sì fún wọn ní (àkókò) àdéhùn fún ìparun wọn.

60 - Al-Kahf (The Cave) - 060

وَإِذۡ قَالَ مُوسَىٰ لِفَتَىٰهُ لَآ أَبۡرَحُ حَتَّىٰٓ أَبۡلُغَ مَجۡمَعَ ٱلۡبَحۡرَيۡنِ أَوۡ أَمۡضِيَ حُقُبٗا
(Rántí) nígbà tí (Ànábì) Mūsā sọ fún ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé: “Èmi kò níí yé rìn títí mo máa fi dé ibi tí odò méjì ti papọ̀ tàbí (títí) mo máa fi lo ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọdún.”

61 - Al-Kahf (The Cave) - 061

فَلَمَّا بَلَغَا مَجۡمَعَ بَيۡنِهِمَا نَسِيَا حُوتَهُمَا فَٱتَّخَذَ سَبِيلَهُۥ فِي ٱلۡبَحۡرِ سَرَبٗا
Nígbà tí àwọn méjèèjì sì dé ibi tí odò méjèèjì ti papọ̀, wọ́n gbàgbé ẹja wọn. (Ẹja náà) sì sọ ojú ọ̀nà rẹ̀ di poro ọ̀nà nínú odò.

62 - Al-Kahf (The Cave) - 062

فَلَمَّا جَاوَزَا قَالَ لِفَتَىٰهُ ءَاتِنَا غَدَآءَنَا لَقَدۡ لَقِينَا مِن سَفَرِنَا هَٰذَا نَصَبٗا
Nígbà tí àwọn méjèèjì ré kọjá (àyè náà), ó sọ fún ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé: “Fún wa ní oúnjẹ ọ̀sán wa. Dájúdájú a ti ko wàhálà nínú ìrìn-àjò wa yìí.”

63 - Al-Kahf (The Cave) - 063

قَالَ أَرَءَيۡتَ إِذۡ أَوَيۡنَآ إِلَى ٱلصَّخۡرَةِ فَإِنِّي نَسِيتُ ٱلۡحُوتَ وَمَآ أَنسَىٰنِيهُ إِلَّا ٱلشَّيۡطَٰنُ أَنۡ أَذۡكُرَهُۥۚ وَٱتَّخَذَ سَبِيلَهُۥ فِي ٱلۡبَحۡرِ عَجَبٗا
(Ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀) sọ pé: “Ṣé o rí i! Nígbà tí a wà níbi àpáta (fún ìsinmi), dájúdájú mo ti gbàgbé ẹja náà (síbẹ̀)? Kò sì sí ohun tí ó mú mi gbàgbé rẹ̀ bí kò ṣe aṣ-ṣaetọ̄n, tí kò jẹ́ kí n̄g rántí rẹ̀. (Ẹja náà) sì ti mú ọ̀nà rẹ̀ tọ̀ lọ nínú odò ní ọ̀nà ìyanu.”

64 - Al-Kahf (The Cave) - 064

قَالَ ذَٰلِكَ مَا كُنَّا نَبۡغِۚ فَٱرۡتَدَّا عَلَىٰٓ ءَاثَارِهِمَا قَصَصٗا
(Ànábì Mūsā) sọ pé: “(Ibi tí ẹja ti lọ) yẹn ni ohun tí à ń wá.”[1] Àwọn méjèèjì sì padà sẹ́yìn láti tọ orípa ẹsẹ̀ wọn bí wọ́n ti ṣe tọ̀ ọ́ wá.

Scroll to Top