يوسف

 

Yusuf

 

Joseph

1 - Yusuf (Joseph) - 001

الٓرۚ تِلۡكَ ءَايَٰتُ ٱلۡكِتَٰبِ ٱلۡمُبِينِ
’Alif lām rọ̄. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1] Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà tó yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá.
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:1.

2 - Yusuf (Joseph) - 002

إِنَّآ أَنزَلۡنَٰهُ قُرۡءَٰنًا عَرَبِيّٗا لَّعَلَّكُمۡ تَعۡقِلُونَ
Dájúdájú Àwa sọ̀ ọ́ kalẹ̀ ní n̄ǹkan kíké ní èdè Lárúbáwá nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè.

3 - Yusuf (Joseph) - 003

نَحۡنُ نَقُصُّ عَلَيۡكَ أَحۡسَنَ ٱلۡقَصَصِ بِمَآ أَوۡحَيۡنَآ إِلَيۡكَ هَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانَ وَإِن كُنتَ مِن قَبۡلِهِۦ لَمِنَ ٱلۡغَٰفِلِينَ
Àwa ń sọ ìtàn tó dára jùlọ fún ọ pẹ̀lú ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ (nínú ìmísí) al-Ƙur’ān yìí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣíwájú ìmísí náà ìwọ wà lára àwọn tí kò nímọ̀ (nípa rẹ̀).

4 - Yusuf (Joseph) - 004

إِذۡ قَالَ يُوسُفُ لِأَبِيهِ يَـٰٓأَبَتِ إِنِّي رَأَيۡتُ أَحَدَ عَشَرَ كَوۡكَبٗا وَٱلشَّمۡسَ وَٱلۡقَمَرَ رَأَيۡتُهُمۡ لِي سَٰجِدِينَ
(Rántí) nígbà tí (Ànábì) Yūsuf sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Bàbá mi, dájúdájú èmi (lálàá) rí àwọn ìràwọ̀ mọ́kànlá, òòrùn àti òṣùpá. Mo rí wọn tí wọ́n forí kanlẹ̀ fún mi.”

5 - Yusuf (Joseph) - 005

قَالَ يَٰبُنَيَّ لَا تَقۡصُصۡ رُءۡيَاكَ عَلَىٰٓ إِخۡوَتِكَ فَيَكِيدُواْ لَكَ كَيۡدًاۖ إِنَّ ٱلشَّيۡطَٰنَ لِلۡإِنسَٰنِ عَدُوّٞ مُّبِينٞ
Ó sọ pé: “Ọmọ mi, má ṣe rọ́ àlá rẹ fún àwọn ọbàkan rẹ kí wọ́n má baà déte sí ọ. Dájúdájú aṣ-Ṣaetọ̄n ni ọ̀tá pọ́nńbélé fún ènìyàn.

6 - Yusuf (Joseph) - 006

وَكَذَٰلِكَ يَجۡتَبِيكَ رَبُّكَ وَيُعَلِّمُكَ مِن تَأۡوِيلِ ٱلۡأَحَادِيثِ وَيُتِمُّ نِعۡمَتَهُۥ عَلَيۡكَ وَعَلَىٰٓ ءَالِ يَعۡقُوبَ كَمَآ أَتَمَّهَا عَلَىٰٓ أَبَوَيۡكَ مِن قَبۡلُ إِبۡرَٰهِيمَ وَإِسۡحَٰقَۚ إِنَّ رَبَّكَ عَلِيمٌ حَكِيمٞ
Báyẹn ni Olúwa rẹ yóò ṣe ṣà ọ́ lẹ́ṣà. Ó máa fi ìtúmọ̀ àlá mọ̀ ọ́. Ó sì máa pé ìdẹ̀ra Rẹ̀ fún ìwọ àti àwọn ẹbí Ya‘ƙūb, gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe pé e ṣíwájú fún àwọn bàbá rẹ méjèèjì, (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti ’Ishāƙ. Dájúdájú Olúwa rẹ ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.”

7 - Yusuf (Joseph) - 007

۞لَّقَدۡ كَانَ فِي يُوسُفَ وَإِخۡوَتِهِۦٓ ءَايَٰتٞ لِّلسَّآئِلِينَ
Dájúdájú àwọn àmì (àríwòye) ń bẹ fún àwọn oníbèéèrè nípa (ìtàn Ànábì) Yūsuf àti àwọn ọbàkan rẹ̀.

8 - Yusuf (Joseph) - 008

إِذۡ قَالُواْ لَيُوسُفُ وَأَخُوهُ أَحَبُّ إِلَىٰٓ أَبِينَا مِنَّا وَنَحۡنُ عُصۡبَةٌ إِنَّ أَبَانَا لَفِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٍ
(Rántí) nígbà tí wọ́n sọ pé: “Dájúdájú Yūsuf àti ọmọ-ìyá rẹ̀ ni bàbá wa nífẹ̀ẹ́ sí ju àwa. Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì ni àwa. Dájúdájú bàbá wa mà ti wà nínú àṣìṣe pọ́nńbélé.

9 - Yusuf (Joseph) - 009

ٱقۡتُلُواْ يُوسُفَ أَوِ ٱطۡرَحُوهُ أَرۡضٗا يَخۡلُ لَكُمۡ وَجۡهُ أَبِيكُمۡ وَتَكُونُواْ مِنۢ بَعۡدِهِۦ قَوۡمٗا صَٰلِحِينَ
Ẹ pa Yūsuf tàbí kí ẹ lọ gbé e jùnù sí ilẹ̀ kan nítorí kí bàbá yín lè rójú gbọ́ tiyín. Ẹ sì máa di ènìyàn rere lẹ́yìn rẹ̀.”

10 - Yusuf (Joseph) - 010

قَالَ قَآئِلٞ مِّنۡهُمۡ لَا تَقۡتُلُواْ يُوسُفَ وَأَلۡقُوهُ فِي غَيَٰبَتِ ٱلۡجُبِّ يَلۡتَقِطۡهُ بَعۡضُ ٱلسَّيَّارَةِ إِن كُنتُمۡ فَٰعِلِينَ
Òǹsọ̀rọ̀ kan nínú wọn sọ pé: “Ẹ má ṣe pa Yūsuf. Tí ó bá jẹ́ pé ẹ ṣá fẹ́ wá n̄ǹkan ṣe (sí ọ̀rọ̀ rẹ̀), ẹ gbé e jù sínú ìsàlẹ̀ẹ̀sàlẹ̀ kànǹga nítorí kí apá kan nínú àwọn onírìn-àjò lè he é lọ.”

11 - Yusuf (Joseph) - 011

قَالُواْ يَـٰٓأَبَانَا مَا لَكَ لَا تَأۡمَ۬نَّا عَلَىٰ يُوسُفَ وَإِنَّا لَهُۥ لَنَٰصِحُونَ
Wọ́n sọ pé: “Bàbá wa, kí ni kò mú ọ fi ọkàn tán wa lórí Yūsuf. Dájúdájú àwa yóò máa tọ́jú rẹ̀ dáadáa.

12 - Yusuf (Joseph) - 012

أَرۡسِلۡهُ مَعَنَا غَدٗا يَرۡتَعۡ وَيَلۡعَبۡ وَإِنَّا لَهُۥ لَحَٰفِظُونَ
Jẹ́ kí ó bá wa lọ ní ọ̀la kí ó lè dára yá, kí ó sì lè ṣeré. Àti pé dájúdájú àwa yóò máa ṣọ́ ọ.”

13 - Yusuf (Joseph) - 013

قَالَ إِنِّي لَيَحۡزُنُنِيٓ أَن تَذۡهَبُواْ بِهِۦ وَأَخَافُ أَن يَأۡكُلَهُ ٱلذِّئۡبُ وَأَنتُمۡ عَنۡهُ غَٰفِلُونَ
Ó sọ pé: “Dájúdájú ó máa bà mí nínú jẹ́ pé kí ẹ mú u lọ. Mo sì ń páyà kí ìkokò má lọ pa á jẹ nígbà tí ẹ̀yin bá gbàgbé rẹ̀ (síbì kan).”

14 - Yusuf (Joseph) - 014

قَالُواْ لَئِنۡ أَكَلَهُ ٱلذِّئۡبُ وَنَحۡنُ عُصۡبَةٌ إِنَّآ إِذٗا لَّخَٰسِرُونَ
Wọ́n sọ pé: “Tí ìkokò bá fi pa á jẹ, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì ni wá, dájúdájú àwa nígbà náà ni ẹni òfò.”

15 - Yusuf (Joseph) - 015

فَلَمَّا ذَهَبُواْ بِهِۦ وَأَجۡمَعُوٓاْ أَن يَجۡعَلُوهُ فِي غَيَٰبَتِ ٱلۡجُبِّۚ وَأَوۡحَيۡنَآ إِلَيۡهِ لَتُنَبِّئَنَّهُم بِأَمۡرِهِمۡ هَٰذَا وَهُمۡ لَا يَشۡعُرُونَ
Nígbà tí wọ́n mú un lọ tán, wọ́n panupọ̀ pé kí àwọn jù ú sí ìsàlẹ̀ẹ̀sàlẹ̀ kànǹga. À si fí ìmísí ránṣẹ́ sí Yūsuf (níbẹ̀) pé: “Dájúdájú ìwọ yóò fún wọn ní ìró nípa ọ̀rọ̀ wọn yìí nígbà tí wọn kò níí fura.”

16 - Yusuf (Joseph) - 016

وَجَآءُوٓ أَبَاهُمۡ عِشَآءٗ يَبۡكُونَ
Wọ́n dé bá bàbá wọn ní àṣálẹ́, tí wọ́n ń sunkún.

17 - Yusuf (Joseph) - 017

قَالُواْ يَـٰٓأَبَانَآ إِنَّا ذَهَبۡنَا نَسۡتَبِقُ وَتَرَكۡنَا يُوسُفَ عِندَ مَتَٰعِنَا فَأَكَلَهُ ٱلذِّئۡبُۖ وَمَآ أَنتَ بِمُؤۡمِنٖ لَّنَا وَلَوۡ كُنَّا صَٰدِقِينَ
Wọ́n sọ pé: “Bàbá wa, àwa lọ díje eré sísá. A sì fi Yūsuf sílẹ̀ síbi àwọn ẹrù wa. Nígbà náà ni ìkokò pa á jẹ. Ìwọ kò sì níí gbà wá gbọ́, àwa ìbáà jẹ́ olódodo.”

18 - Yusuf (Joseph) - 018

وَجَآءُو عَلَىٰ قَمِيصِهِۦ بِدَمٖ كَذِبٖۚ قَالَ بَلۡ سَوَّلَتۡ لَكُمۡ أَنفُسُكُمۡ أَمۡرٗاۖ فَصَبۡرٞ جَمِيلٞۖ وَٱللَّهُ ٱلۡمُسۡتَعَانُ عَلَىٰ مَا تَصِفُونَ
Wọ́n dé pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ irọ́ lára ẹ̀wù rẹ̀. (Ànábì Ya‘ƙūb) sọ pé: “Rárá o, ẹ̀mí yín ló ṣe ọ̀ràn kan lọ́ṣọ̀ọ́ fún yín. Nítorí náà, sùúrù abiyì (lọ̀rọ̀ mi kàn). Allāhu sì ni Ẹni tí à ń wá ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀ lórí ohun tí ẹ̀ ń ròyìn (yìí).”

19 - Yusuf (Joseph) - 019

وَجَآءَتۡ سَيَّارَةٞ فَأَرۡسَلُواْ وَارِدَهُمۡ فَأَدۡلَىٰ دَلۡوَهُۥۖ قَالَ يَٰبُشۡرَىٰ هَٰذَا غُلَٰمٞۚ وَأَسَرُّوهُ بِضَٰعَةٗۚ وَٱللَّهُ عَلِيمُۢ بِمَا يَعۡمَلُونَ
Àwọn onírìn-àjò kan sì dé. Wọ́n rán apọnmi wọn (ní omi). Ó sì ju doro rẹ̀ sínú kànǹga. (Yūsuf sì dìrọ̀ mọ́ okùn doro bọ́ síta. Apọnmi sì) sọ pé: “Ire ìdùnnú rè é! Èyí ni ọmọdékùnrin.” Wọ́n sì fi pamọ́ fún títà (bí ọjà). Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

20 - Yusuf (Joseph) - 020

وَشَرَوۡهُ بِثَمَنِۭ بَخۡسٖ دَرَٰهِمَ مَعۡدُودَةٖ وَكَانُواْ فِيهِ مِنَ ٱلزَّـٰهِدِينَ
Wọ́n tà á ní ẹ̀dínwó pẹ̀lú owó diriham tó níye. Wọ́n kò sì wowọ́ mọ́ ọn.[1]
1. Ìyẹn ni pé, wọn kò tà á ní ọ̀wọ́n gógó.

21 - Yusuf (Joseph) - 021

وَقَالَ ٱلَّذِي ٱشۡتَرَىٰهُ مِن مِّصۡرَ لِٱمۡرَأَتِهِۦٓ أَكۡرِمِي مَثۡوَىٰهُ عَسَىٰٓ أَن يَنفَعَنَآ أَوۡ نَتَّخِذَهُۥ وَلَدٗاۚ وَكَذَٰلِكَ مَكَّنَّا لِيُوسُفَ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَلِنُعَلِّمَهُۥ مِن تَأۡوِيلِ ٱلۡأَحَادِيثِۚ وَٱللَّهُ غَالِبٌ عَلَىٰٓ أَمۡرِهِۦ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَعۡلَمُونَ
Ẹni tí ó rà á ní (ìlú) Misrọ sọ fún aya rẹ̀ pé: “Ṣàpọ́nlé ibùgbé rẹ̀. Ó súnmọ́ kí ó wúlò fún wa tàbí kí á fi ṣọmọ.” Báyẹn ni A ṣe fi àyè gba Yūsuf lórí ilẹ̀. Àti pé kí Á tún lè fi ìtúmọ̀ àlá mọ̀ ọ́n. Allāhu ni Olùborí lórí àṣẹ Rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn ni kò mọ̀.

22 - Yusuf (Joseph) - 022

وَلَمَّا بَلَغَ أَشُدَّهُۥٓ ءَاتَيۡنَٰهُ حُكۡمٗا وَعِلۡمٗاۚ وَكَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُحۡسِنِينَ
Nígbà tí ó sì dàgbà dáadáa, A fún un ní ọgbọ́n ìjìnlẹ̀ àti ìmọ̀. Báyẹn ni A ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san rere.

23 - Yusuf (Joseph) - 023

وَرَٰوَدَتۡهُ ٱلَّتِي هُوَ فِي بَيۡتِهَا عَن نَّفۡسِهِۦ وَغَلَّقَتِ ٱلۡأَبۡوَٰبَ وَقَالَتۡ هَيۡتَ لَكَۚ قَالَ مَعَاذَ ٱللَّهِۖ إِنَّهُۥ رَبِّيٓ أَحۡسَنَ مَثۡوَايَۖ إِنَّهُۥ لَا يُفۡلِحُ ٱلظَّـٰلِمُونَ
Obìnrin tí Yūsuf wà nínú ilé rẹ̀ sì jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún eré ìfẹ́ lọ́dọ̀ rẹ̀. Ó sì ti àwọn ìlẹ̀kùn pa. Ó sọ pé: “Súnmọ́ mi.” (Yūsuf) sọ pé: “Mo sádi Allāhu. Dájúdájú ọkọ rẹ ni ọ̀gá mi. Ó sì ṣe ibùgbé mi dáadáa. Dájúdájú àwọn alábòsí kò níí jèrè.”

24 - Yusuf (Joseph) - 024

وَلَقَدۡ هَمَّتۡ بِهِۦۖ وَهَمَّ بِهَا لَوۡلَآ أَن رَّءَا بُرۡهَٰنَ رَبِّهِۦۚ كَذَٰلِكَ لِنَصۡرِفَ عَنۡهُ ٱلسُّوٓءَ وَٱلۡفَحۡشَآءَۚ إِنَّهُۥ مِنۡ عِبَادِنَا ٱلۡمُخۡلَصِينَ
(Obìnrin náà) kúkú gbèrò eré ìfẹ́ sí i. Òun náà gbèrò rẹ̀.[1] Tí kò bá jẹ́ pé ó rí ẹ̀rí Olúwa rẹ̀ (pé harāmu ni sìná, ìbá súnmọ́ ọn). Báyẹn ni (ọ̀rọ̀ náà rí) nítorí kí Á lè ṣẹ́rí aburú àti sìná ṣíṣe kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Dájúdájú ó wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà (fún ipò ànábì).”
1. Ànábì Yūsuf - kí ọlà Allāhu máa bá a - kò di ẹlẹ́ṣẹ̀ látara bí èròǹgbà ìyàwó ọ̀gá rẹ̀ ṣe tì í sínú èròkérò ní ìbámu sí hadīth ọmọ ‘Abbās - kí Allāhu yọ́nú sí àwọn méjèèjì -, láti ọ̀dọ̀ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - nínú ohun tí ó gbà lẹ́gbàwá làti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀ - tó ga jùlọ -. Ó sọ pé: “Dájúdájú Allāhu ti ṣe àkọsílẹ̀ àwọn iṣẹ́ rere àti àwọn iṣẹ́ ibi sínú kádàrá. Lẹ́yìn náà, Ó ṣàlàyé èyí (fún ẹ̀dá). Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbèrò iṣẹ́ rere kan, kò sì ṣe é, Allāhu yóò kọ ọ́ sílẹ̀ fún un lọ́dọ̀ Rẹ̀ ní iṣẹ́ rere tó pé pérépéré. Tí ó bá sì gbèrò rẹ̀, tí ó sì rí i ṣe, Allāhu yóò kọ ọ́ sílẹ̀ fún un lọ́dọ̀ Rẹ̀ ní iṣẹ́ rere mẹ́wàá, títí dé ọgọ́rùn-ún méje àdìpèlé, títí dé àdìpèlé lọ́pọ̀lọ́pọ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbèrò iṣẹ́ ibi kan, kò sì ṣe é, Allāhu yóò kọ ọ́ sílẹ̀ fún un lọ́dọ̀ Rẹ̀ ní iṣẹ́ rere tó pé pérépéré (fún gbígbé iṣẹ́ ibi jù sílẹ̀). Tí ó bá sì gbèrò rẹ̀, tí ó sì rí i ṣe, Allāhu yóò kọ ọ́ sílẹ̀ fún un lọ́dọ̀ Rẹ̀ ní iṣẹ́ ibi ẹyọ kan.” Bukāriy àti Muslim

25 - Yusuf (Joseph) - 025

وَٱسۡتَبَقَا ٱلۡبَابَ وَقَدَّتۡ قَمِيصَهُۥ مِن دُبُرٖ وَأَلۡفَيَا سَيِّدَهَا لَدَا ٱلۡبَابِۚ قَالَتۡ مَا جَزَآءُ مَنۡ أَرَادَ بِأَهۡلِكَ سُوٓءًا إِلَّآ أَن يُسۡجَنَ أَوۡ عَذَابٌ أَلِيمٞ
Àwọn méjèèjì sáré lọ síbi ìlẹ̀kùn. (Obìnrin yìí) sì fa ẹ̀wù (Yūsuf) ya lẹ́yìn. Àwọn méjèèjì sì bá ọ̀gá rẹ̀ lẹ́nu ọ̀nà. (Obìnrin yìí) sì sọ pé: “Kí ni ẹ̀san fún ẹni tí ó gbèrò aburú sí ará ilé rẹ bí kò ṣe pé kí wọ́n sọ ọ́ sínú ọgbà ẹ̀wọ̀n tàbí ìyà ẹlẹ́ta-eléro.”

26 - Yusuf (Joseph) - 026

قَالَ هِيَ رَٰوَدَتۡنِي عَن نَّفۡسِيۚ وَشَهِدَ شَاهِدٞ مِّنۡ أَهۡلِهَآ إِن كَانَ قَمِيصُهُۥ قُدَّ مِن قُبُلٖ فَصَدَقَتۡ وَهُوَ مِنَ ٱلۡكَٰذِبِينَ
(Yūsuf) sọ pé: “Òun ló jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún eré ìfẹ́ lọ́dọ̀ mi.” Ẹlẹ́rìí kan nínú ará ile (obìnrin náà) sì jẹ́rìí pé: “Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n fa ẹ̀wù rẹ̀ ya níwájú, (obìnrin yìí) ló sọ òdodo, (Yūsuf) sì wà nínú àwọn òpùrọ́.

27 - Yusuf (Joseph) - 027

وَإِن كَانَ قَمِيصُهُۥ قُدَّ مِن دُبُرٖ فَكَذَبَتۡ وَهُوَ مِنَ ٱلصَّـٰدِقِينَ
Tí ó bá sì jẹ́ pé wọ́n fa ẹ̀wù rẹ̀ ya lẹ́yìn, (obìnrin yìí) ló parọ́, (Yūsuf) sì wà nínú àwọn olódodo.”[1]
1. Ẹlẹ́rìí yìí ni ọmọ òpóǹló tí Allāhu - Ọba mímọ́ jùlọ - fún lọ́rọ̀ sọ lórí ìtẹ́. Nítorí náà, kì í ṣe Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - nìkan ni ẹni tí ó sọ̀rọ̀ ní òpóǹló lórí ìtẹ́.

28 - Yusuf (Joseph) - 028

فَلَمَّا رَءَا قَمِيصَهُۥ قُدَّ مِن دُبُرٖ قَالَ إِنَّهُۥ مِن كَيۡدِكُنَّۖ إِنَّ كَيۡدَكُنَّ عَظِيمٞ
Nígbà tí (ọkọ) rí ẹ̀wù rẹ̀ tí wọ́n ti fà á ya lẹ́yìn, ó sọ pé: “Dájúdájú nínú ète ẹ̀yin obìnrin ni (èyí). Dájúdájú ète yín tóbi.

29 - Yusuf (Joseph) - 029

يُوسُفُ أَعۡرِضۡ عَنۡ هَٰذَاۚ وَٱسۡتَغۡفِرِي لِذَنۢبِكِۖ إِنَّكِ كُنتِ مِنَ ٱلۡخَاطِـِٔينَ
Yūsuf, ṣẹ́rí kúrò níbi èyí. Kí ìwọ (obìnrin yìí) sì tọrọ àforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. Dájúdájú ìwọ wà lára àwọn aláṣìṣe.”

30 - Yusuf (Joseph) - 030

۞وَقَالَ نِسۡوَةٞ فِي ٱلۡمَدِينَةِ ٱمۡرَأَتُ ٱلۡعَزِيزِ تُرَٰوِدُ فَتَىٰهَا عَن نَّفۡسِهِۦۖ قَدۡ شَغَفَهَا حُبًّاۖ إِنَّا لَنَرَىٰهَا فِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٖ
Àwọn obìnrin kan nínú ìlú sọ pé: “Ayaba ń jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún eré ìfẹ́ lọ́dọ̀ ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀; ìfẹ́ kúkú ti kó sí i lọ́kàn. Dájúdájú àwa ń rí òun pé ó wà nínú àṣìṣe pọ́nńbélé.”

31 - Yusuf (Joseph) - 031

فَلَمَّا سَمِعَتۡ بِمَكۡرِهِنَّ أَرۡسَلَتۡ إِلَيۡهِنَّ وَأَعۡتَدَتۡ لَهُنَّ مُتَّكَـٔٗا وَءَاتَتۡ كُلَّ وَٰحِدَةٖ مِّنۡهُنَّ سِكِّينٗا وَقَالَتِ ٱخۡرُجۡ عَلَيۡهِنَّۖ فَلَمَّا رَأَيۡنَهُۥٓ أَكۡبَرۡنَهُۥ وَقَطَّعۡنَ أَيۡدِيَهُنَّ وَقُلۡنَ حَٰشَ لِلَّهِ مَا هَٰذَا بَشَرًا إِنۡ هَٰذَآ إِلَّا مَلَكٞ كَرِيمٞ
Nígbà tí (ayaba) gbọ́ ète (ọ̀rọ̀) wọn (tí wọ́n ń sọ nípa rẹ̀), ó ránṣẹ́ sí wọn. Ó sì pèsè ohun jíjẹ tí wọ́n máa rọ̀gbọ̀kú jẹ lórí tìmùtìmù àti ìrọ̀rí sílẹ̀ fún wọn. Ó fún ìkọ̀ọ̀kan wọn ní ọ̀bẹ (tí ó máa fi jẹun). Ó sì sọ pé: “Jáde sí wọn, (Yūsuf).” Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n gbé e tóbi (fún ẹwà ara rẹ̀). Wọ́n sì rẹ́ra wọn lọ́wọ́ (fún ìyanu ẹwà ara rẹ̀). Wọ́n sì wí pé: “Mímọ́ ni fún Allāhu! Èyí kì í ṣe abara. Kí ni èyí bí kò ṣe mọlāika alápọ̀n-ọ́nlé.”

32 - Yusuf (Joseph) - 032

قَالَتۡ فَذَٰلِكُنَّ ٱلَّذِي لُمۡتُنَّنِي فِيهِۖ وَلَقَدۡ رَٰوَدتُّهُۥ عَن نَّفۡسِهِۦ فَٱسۡتَعۡصَمَۖ وَلَئِن لَّمۡ يَفۡعَلۡ مَآ ءَامُرُهُۥ لَيُسۡجَنَنَّ وَلَيَكُونٗا مِّنَ ٱلصَّـٰغِرِينَ
(Ayaba) sọ pé: “Ìyẹn ni ẹni tí ẹ bú mi fún. Dájúdájú mo jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún eré ìfẹ́ lọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wá ìṣọ́ra. Dájúdájú tí kò bá ṣe ohun tí mò ń pa láṣẹ fún un, wọ́n kúkú máa fi sínú ọgbà ẹ̀wọ̀n ni. Dájúdájú ó sì máa wà nínú àwọn ẹni yẹpẹrẹ.”

33 - Yusuf (Joseph) - 033

قَالَ رَبِّ ٱلسِّجۡنُ أَحَبُّ إِلَيَّ مِمَّا يَدۡعُونَنِيٓ إِلَيۡهِۖ وَإِلَّا تَصۡرِفۡ عَنِّي كَيۡدَهُنَّ أَصۡبُ إِلَيۡهِنَّ وَأَكُن مِّنَ ٱلۡجَٰهِلِينَ
(Yūsuf) sọ pé: “Olúwa (Ẹlẹ́dàá) mi, ọgbà ẹ̀wọ̀n ni mo nífẹ̀ẹ́ sí ju ohun tí wọ́n ń pè mí sí. Tí O ò bá sì ṣẹ́rí ète wọn kúrò lọ́dọ̀ mi, èmi yóò kó sínú ète wọn, èmi yó sì wà lára àwọn aláìmọ̀kan.”

34 - Yusuf (Joseph) - 034

فَٱسۡتَجَابَ لَهُۥ رَبُّهُۥ فَصَرَفَ عَنۡهُ كَيۡدَهُنَّۚ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡعَلِيمُ
Nítorí náà, Olúwa rẹ̀ jẹ́pè rẹ̀. Ó sì ṣẹ́rí ète wọn kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgbọ́, Onímọ̀.

35 - Yusuf (Joseph) - 035

ثُمَّ بَدَا لَهُم مِّنۢ بَعۡدِ مَا رَأَوُاْ ٱلۡأٓيَٰتِ لَيَسۡجُنُنَّهُۥ حَتَّىٰ حِينٖ
Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti rí àwọn àmì (pé Yūsuf kò jẹ̀bi ẹ̀sùn), lẹ́yìn náà, ó hàn sí wọn pé àwọn gbọ́dọ̀ sọ ọ́ sínú ọgbà ẹ̀wọ̀n títí di àsìkò kan ná.

36 - Yusuf (Joseph) - 036

وَدَخَلَ مَعَهُ ٱلسِّجۡنَ فَتَيَانِۖ قَالَ أَحَدُهُمَآ إِنِّيٓ أَرَىٰنِيٓ أَعۡصِرُ خَمۡرٗاۖ وَقَالَ ٱلۡأٓخَرُ إِنِّيٓ أَرَىٰنِيٓ أَحۡمِلُ فَوۡقَ رَأۡسِي خُبۡزٗا تَأۡكُلُ ٱلطَّيۡرُ مِنۡهُۖ نَبِّئۡنَا بِتَأۡوِيلِهِۦٓۖ إِنَّا نَرَىٰكَ مِنَ ٱلۡمُحۡسِنِينَ
Àwọn ọ̀dọ́kùnrin méjì kan wọ inú ọgbà ẹ̀wọ̀n pẹ̀lú rẹ̀. Ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì sọ pé: “Èmi lálàá rí ara mi pé mò ń fún ọtí.” Ẹnì kejì sọ pé: “Dájúdájú èmi lálàá rí ara mi pé mo gbé búrẹ́dì rù sórí mi, ẹyẹ sì ń jẹ nínú rẹ̀.” Sọ ìtúmọ̀ rẹ̀ fún wa. Dájúdájú àwa ń rí ọ pé o wà nínú àwọn ẹni rere.

37 - Yusuf (Joseph) - 037

قَالَ لَا يَأۡتِيكُمَا طَعَامٞ تُرۡزَقَانِهِۦٓ إِلَّا نَبَّأۡتُكُمَا بِتَأۡوِيلِهِۦ قَبۡلَ أَن يَأۡتِيَكُمَاۚ ذَٰلِكُمَا مِمَّا عَلَّمَنِي رَبِّيٓۚ إِنِّي تَرَكۡتُ مِلَّةَ قَوۡمٖ لَّا يُؤۡمِنُونَ بِٱللَّهِ وَهُم بِٱلۡأٓخِرَةِ هُمۡ كَٰفِرُونَ
Ó sọ pé: “Oúnjẹ tí wọ́n ń pèsè fún ẹ̀yin méjèèjì kò ní tí ì dé ba yín, àfi kí èmi ti sọ ìtúmọ̀ rẹ̀ fún ẹ̀yin méjèèjì ṣíwájú kí ó tó dé ba yín. Ìyẹn wà nínú n̄ǹkan tí Olúwa mi fi mọ̀ mí. Dájúdájú èmi fi ẹ̀sìn àwọn ènìyàn tí kò gbàgbọ́ nínú Allāhu sílẹ̀. Àwọn sì ni aláìgbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.

38 - Yusuf (Joseph) - 038

وَٱتَّبَعۡتُ مِلَّةَ ءَابَآءِيٓ إِبۡرَٰهِيمَ وَإِسۡحَٰقَ وَيَعۡقُوبَۚ مَا كَانَ لَنَآ أَن نُّشۡرِكَ بِٱللَّهِ مِن شَيۡءٖۚ ذَٰلِكَ مِن فَضۡلِ ٱللَّهِ عَلَيۡنَا وَعَلَى ٱلنَّاسِ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَشۡكُرُونَ
Mo sì tẹ̀lé ẹ̀sìn àwọn bàbá mi, (àwọn Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ishāƙ àti Ya‘ƙūb. Kò tọ́ sí wa pé kí á sọ n̄ǹkan kan di akẹgbẹ́ fún Allāhu. Ìyẹn wà nínú oore àjùlọ Allāhu lórí àwa àti lórí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kì í dúpẹ́ (fún Allāhu).

39 - Yusuf (Joseph) - 039

يَٰصَٰحِبَيِ ٱلسِّجۡنِ ءَأَرۡبَابٞ مُّتَفَرِّقُونَ خَيۡرٌ أَمِ ٱللَّهُ ٱلۡوَٰحِدُ ٱلۡقَهَّارُ
Ẹ̀yin akẹgbẹ́ mi méjéèjì nínú ẹ̀wọ̀n, ṣé àwọn olúwa ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló lóore jùlọ (láti jọ́sìn fún) tàbí Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí?

40 - Yusuf (Joseph) - 040

مَا تَعۡبُدُونَ مِن دُونِهِۦٓ إِلَّآ أَسۡمَآءٗ سَمَّيۡتُمُوهَآ أَنتُمۡ وَءَابَآؤُكُم مَّآ أَنزَلَ ٱللَّهُ بِهَا مِن سُلۡطَٰنٍۚ إِنِ ٱلۡحُكۡمُ إِلَّا لِلَّهِ أَمَرَ أَلَّا تَعۡبُدُوٓاْ إِلَّآ إِيَّاهُۚ ذَٰلِكَ ٱلدِّينُ ٱلۡقَيِّمُ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَعۡلَمُونَ
Kò sí ohun kan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Rẹ̀ bí kò ṣe àwọn orúkọ kan tí ẹ sọ wọ́n - ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín - Allāhu kò sọ ẹ̀rí kan kalẹ̀ fún un. Ìdájọ́ (ta ni a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo) kò sí fún ẹnì kan àyàfi Allāhu. Ó sì ti pàṣẹ pé ẹ má ṣe jọ́sìn fún kiní kan àyàfi Òun nìkan. Ìyẹn ni ẹ̀sìn tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀.

41 - Yusuf (Joseph) - 041

يَٰصَٰحِبَيِ ٱلسِّجۡنِ أَمَّآ أَحَدُكُمَا فَيَسۡقِي رَبَّهُۥ خَمۡرٗاۖ وَأَمَّا ٱلۡأٓخَرُ فَيُصۡلَبُ فَتَأۡكُلُ ٱلطَّيۡرُ مِن رَّأۡسِهِۦۚ قُضِيَ ٱلۡأَمۡرُ ٱلَّذِي فِيهِ تَسۡتَفۡتِيَانِ
Ẹ̀yin akẹgbẹ́ mi méjéèjì nínú ẹ̀wọ̀n, ní ti ẹnì kan nínú yín, ó máa fún ọ̀gá rẹ̀ ní ọtí mu. Ní ti ẹnì kejì, wọn yóò kàn án mọ́ igi àgbélébùú, ẹyẹ yó sì máa jẹ nínú orí rẹ̀. Wọ́n ti parí ọ̀rọ̀ tí ẹ̀yin méjèèjì ń ṣe ìbéèrè nípa rẹ̀.”

42 - Yusuf (Joseph) - 042

وَقَالَ لِلَّذِي ظَنَّ أَنَّهُۥ نَاجٖ مِّنۡهُمَا ٱذۡكُرۡنِي عِندَ رَبِّكَ فَأَنسَىٰهُ ٱلشَّيۡطَٰنُ ذِكۡرَ رَبِّهِۦ فَلَبِثَ فِي ٱلسِّجۡنِ بِضۡعَ سِنِينَ
Ó sì sọ fún ẹni tí ó rò pé ó máa là nínú àwọn méjèèjì pé: “Rántí mi lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ.” Aṣ-ṣaetọ̄n sì mú ọ̀dọ́kùnrin náà gbàgbé láti sọ̀rọ̀ (Yūsuf) lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀. Nítorí náà, ó wà nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n fún àwọn ọdún díẹ̀.

43 - Yusuf (Joseph) - 043

وَقَالَ ٱلۡمَلِكُ إِنِّيٓ أَرَىٰ سَبۡعَ بَقَرَٰتٖ سِمَانٖ يَأۡكُلُهُنَّ سَبۡعٌ عِجَافٞ وَسَبۡعَ سُنۢبُلَٰتٍ خُضۡرٖ وَأُخَرَ يَابِسَٰتٖۖ يَـٰٓأَيُّهَا ٱلۡمَلَأُ أَفۡتُونِي فِي رُءۡيَٰيَ إِن كُنتُمۡ لِلرُّءۡيَا تَعۡبُرُونَ
Ọbá sọ pé: “Dájúdájú èmi lálàá rí màálù méje tó sanra. Àwọn màálù méje tó rù sì ń jẹ wọ́n. (Mo tún lálàá rí) ṣiri méje tutù àti òmíràn gbígbẹ. Ẹ̀yin ìjòyè, ẹ fún mi ní àlàyé ìtúmọ̀ àlá mi tí ẹ bá jẹ́ ẹni tó máa ń túmọ̀ àlá.”

44 - Yusuf (Joseph) - 044

قَالُوٓاْ أَضۡغَٰثُ أَحۡلَٰمٖۖ وَمَا نَحۡنُ بِتَأۡوِيلِ ٱلۡأَحۡلَٰمِ بِعَٰلِمِينَ
Wọ́n sọ pé: “Àwọn àlá tí ó lọ́pọ̀ mọ́ra wọn tí kò ní ìtúmọ̀ (nìyí). Àti pé àwa kì í ṣe onímọ̀ nípa ìtúmọ̀ àwọn àlá.”

45 - Yusuf (Joseph) - 045

وَقَالَ ٱلَّذِي نَجَا مِنۡهُمَا وَٱدَّكَرَ بَعۡدَ أُمَّةٍ أَنَا۠ أُنَبِّئُكُم بِتَأۡوِيلِهِۦ فَأَرۡسِلُونِ
Ẹni tí ó là nínú àwọn (ẹlẹ́wọ̀n) méjèèjì sọ pé, - ó rántí (Yūsuf) lẹ́yìn ìgbà pípẹ́ -: “Èmi yóò fún yín ní ìró nípa ìtúmọ̀ rẹ̀. Nítorí náà, ẹ fi iṣẹ́ rán mi ná (kí n̄g lọ ṣe ìwádìí rẹ̀).”

46 - Yusuf (Joseph) - 046

يُوسُفُ أَيُّهَا ٱلصِّدِّيقُ أَفۡتِنَا فِي سَبۡعِ بَقَرَٰتٖ سِمَانٖ يَأۡكُلُهُنَّ سَبۡعٌ عِجَافٞ وَسَبۡعِ سُنۢبُلَٰتٍ خُضۡرٖ وَأُخَرَ يَابِسَٰتٖ لَّعَلِّيٓ أَرۡجِعُ إِلَى ٱلنَّاسِ لَعَلَّهُمۡ يَعۡلَمُونَ
Yūsuf, ìwọ olódodo, fún wa ní àlàyé ìtúmọ̀ àlá (yìí): màálù méje tó sanra. Àwọn màálù méje tó rù sì ń jẹ wọ́n. Àti ṣiri méje tutù àti òmíràn gbígbẹ. (Kí ni ìtúmọ̀ rẹ̀) nítorí kí n̄g lè fi àbọ̀ sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn àti nítorí kí wọ́n lè mọ (ìtúmọ̀ rẹ̀).

47 - Yusuf (Joseph) - 047

قَالَ تَزۡرَعُونَ سَبۡعَ سِنِينَ دَأَبٗا فَمَا حَصَدتُّمۡ فَذَرُوهُ فِي سُنۢبُلِهِۦٓ إِلَّا قَلِيلٗا مِّمَّا تَأۡكُلُونَ
Ó sọ pé: “Ẹ̀yin yóò gbin n̄ǹkan ọ̀gbìn fún ọdún méje gbáko (gẹ́gẹ́ bí) ìṣe (yín). Ohunkòhun tí ẹ bá kó lérè oko, kí ẹ fi sílẹ̀ sínú ṣiri rẹ̀ àfi díẹ̀ tí ẹ máa jẹ nínú rẹ̀.

48 - Yusuf (Joseph) - 048

ثُمَّ يَأۡتِي مِنۢ بَعۡدِ ذَٰلِكَ سَبۡعٞ شِدَادٞ يَأۡكُلۡنَ مَا قَدَّمۡتُمۡ لَهُنَّ إِلَّا قَلِيلٗا مِّمَّا تُحۡصِنُونَ
Lẹ́yìn náà, ọdún méje tó le (fún ọ̀dá òjò) yóò dé lẹ́yìn ìyẹn, (àwọn ará ìlú) yó sì lè jẹ ohun tí ẹ ti (kó lérè oko) ṣíwájú àfi díẹ̀ tí ẹ máa fi pamọ́ (fún gbígbìn).

49 - Yusuf (Joseph) - 049

ثُمَّ يَأۡتِي مِنۢ بَعۡدِ ذَٰلِكَ عَامٞ فِيهِ يُغَاثُ ٱلنَّاسُ وَفِيهِ يَعۡصِرُونَ
Lẹ́yìn náà, ọdún kan tí Wọn yóò rọ̀jò fún àwọn ènìyàn yóò dé lẹ́yìn ìyẹn. Àwọn ènìyàn yó sì máa fún èso àti wàrà mu nínú ọdún náà.

50 - Yusuf (Joseph) - 050

وَقَالَ ٱلۡمَلِكُ ٱئۡتُونِي بِهِۦۖ فَلَمَّا جَآءَهُ ٱلرَّسُولُ قَالَ ٱرۡجِعۡ إِلَىٰ رَبِّكَ فَسۡـَٔلۡهُ مَا بَالُ ٱلنِّسۡوَةِ ٱلَّـٰتِي قَطَّعۡنَ أَيۡدِيَهُنَّۚ إِنَّ رَبِّي بِكَيۡدِهِنَّ عَلِيمٞ
Ọba sọ pé: “Ẹ mú (Yūsuf) wá fún mi.” Nígbà tí ìránṣẹ́ náà dé ọ̀dọ̀ rẹ. (Yūsuf) sọ pé: “Padà sọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ, kí o bi í léèrè pé, kí ni ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn obìnrin tí wọ́n rẹ́ ọwọ́ ara wọn. Dájúdájú Olúwa mi ni Onímọ̀ nípa ète wọn.”

51 - Yusuf (Joseph) - 051

قَالَ مَا خَطۡبُكُنَّ إِذۡ رَٰوَدتُّنَّ يُوسُفَ عَن نَّفۡسِهِۦۚ قُلۡنَ حَٰشَ لِلَّهِ مَا عَلِمۡنَا عَلَيۡهِ مِن سُوٓءٖۚ قَالَتِ ٱمۡرَأَتُ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡـَٰٔنَ حَصۡحَصَ ٱلۡحَقُّ أَنَا۠ رَٰوَدتُّهُۥ عَن نَّفۡسِهِۦ وَإِنَّهُۥ لَمِنَ ٱلصَّـٰدِقِينَ
(Ọba) sọ pé: “Kí ni ọ̀rọ̀ tiyín ti jẹ́ tí ẹ fi jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún eré ìfẹ́ lọ́dọ̀ Yūsuf?” Wọ́n sọ pé: “Mímọ́ ni fún Allāhu. àwa kò mọ aburú kan mọ Yūsuf.” Ayaba sọ pé: “Nísinsìn yìí ni òdodo fojú hàn. Èmi ni mo jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún eré ìfẹ́ lọ́dọ̀ rẹ̀. Dájúdájú ó wà nínú àwọn olódodo.”

52 - Yusuf (Joseph) - 052

ذَٰلِكَ لِيَعۡلَمَ أَنِّي لَمۡ أَخُنۡهُ بِٱلۡغَيۡبِ وَأَنَّ ٱللَّهَ لَا يَهۡدِي كَيۡدَ ٱلۡخَآئِنِينَ
(Yūsuf sọ pé): “Ìyẹn nítorí kí ọba lè mọ̀ pé dájúdájú èmi kò jàǹbá rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀. Àti pé dájúdájú Allāhu kò níí fi ìmọ̀nà síbi ète àwọn oníjàǹbá.

53 - Yusuf (Joseph) - 053

۞وَمَآ أُبَرِّئُ نَفۡسِيٓۚ إِنَّ ٱلنَّفۡسَ لَأَمَّارَةُۢ بِٱلسُّوٓءِ إِلَّا مَا رَحِمَ رَبِّيٓۚ إِنَّ رَبِّي غَفُورٞ رَّحِيمٞ
Èmi kò sì fọra mi mọ́ (níbi èròkérò); dájúdájú ẹ̀mí kúkú ń pàṣẹ èròkérò (fún ẹ̀dá) ni àfi ẹni tí Olúwa mi bá kẹ́. Dájúdájú Olúwa mi ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.”

54 - Yusuf (Joseph) - 054

وَقَالَ ٱلۡمَلِكُ ٱئۡتُونِي بِهِۦٓ أَسۡتَخۡلِصۡهُ لِنَفۡسِيۖ فَلَمَّا كَلَّمَهُۥ قَالَ إِنَّكَ ٱلۡيَوۡمَ لَدَيۡنَا مَكِينٌ أَمِينٞ
Ọba sọ pé: “Ẹ mú (Yūsuf) wá fún mi. Èmi yóò ṣe é ní ẹni ẹ̀ṣà lọ́dọ̀ mi.” Nígbà tí ọba bá a sọ̀rọ̀ tán, ó sọ pé: “Lọ́dọ̀ wa ní òní dájúdájú ìwọ ni ẹni pàtàkì, olùfọkàntán.”

55 - Yusuf (Joseph) - 055

قَالَ ٱجۡعَلۡنِي عَلَىٰ خَزَآئِنِ ٱلۡأَرۡضِۖ إِنِّي حَفِيظٌ عَلِيمٞ
(Yūsuf) sọ pé: “Fi mí ṣe aláṣẹ lórí àwọn ọrọ̀ ìlú, dájúdájú alámòjúútó onímọ̀ ni mí.”

56 - Yusuf (Joseph) - 056

وَكَذَٰلِكَ مَكَّنَّا لِيُوسُفَ فِي ٱلۡأَرۡضِ يَتَبَوَّأُ مِنۡهَا حَيۡثُ يَشَآءُۚ نُصِيبُ بِرَحۡمَتِنَا مَن نَّشَآءُۖ وَلَا نُضِيعُ أَجۡرَ ٱلۡمُحۡسِنِينَ
Báyẹn ni A ṣe fún Yūsuf ní ipò àti ibùgbé lórí ilẹ̀. Ó sì ń gbé ní ibi tí ó bá fẹ́. Àwa ń mú ìkẹ́ Wa bá ẹnikẹ́ni tí A bá fẹ́. A ò sì níí fi ẹ̀san àwọn olùṣe-rere ráre.

57 - Yusuf (Joseph) - 057

وَلَأَجۡرُ ٱلۡأٓخِرَةِ خَيۡرٞ لِّلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَكَانُواْ يَتَّقُونَ
Dájúdájú ẹ̀san ti ọ̀run lóore jùlọ fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ń bẹ̀rù (Allāhu).

58 - Yusuf (Joseph) - 058

وَجَآءَ إِخۡوَةُ يُوسُفَ فَدَخَلُواْ عَلَيۡهِ فَعَرَفَهُمۡ وَهُمۡ لَهُۥ مُنكِرُونَ
Àwọn ọbàkan (Ànábì) Yūsuf dé, wọ́n sì wọlé tọ̀ ọ́. Ó dá wọn mọ̀. Àwọn kò sì mọ̀ ọ́n mọ́.

59 - Yusuf (Joseph) - 059

وَلَمَّا جَهَّزَهُم بِجَهَازِهِمۡ قَالَ ٱئۡتُونِي بِأَخٖ لَّكُم مِّنۡ أَبِيكُمۡۚ أَلَا تَرَوۡنَ أَنِّيٓ أُوفِي ٱلۡكَيۡلَ وَأَنَا۠ خَيۡرُ ٱلۡمُنزِلِينَ
Nígbà tí ó sì fún wọn ní ẹrù oúnjẹ wọn tán, ó sọ pé: “Ẹ lọ mú ọbàkan yín wá láti ọ̀dọ̀ bàbá yín. Ṣé ẹ kò rí i pé dájúdájú mò ń wọn kóńgò ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́ ni? Èmi sì dára jùlọ nínú àwọn olùgbàlejò.

60 - Yusuf (Joseph) - 060

فَإِن لَّمۡ تَأۡتُونِي بِهِۦ فَلَا كَيۡلَ لَكُمۡ عِندِي وَلَا تَقۡرَبُونِ
Tí ẹ ò bá sì mú un wá, kò sí (ẹrù oúnjẹ) wíwọ̀n fún yín lọ́dọ̀ mi. Kí ẹ sì má ṣe súnmọ́ mi.”

61 - Yusuf (Joseph) - 061

قَالُواْ سَنُرَٰوِدُ عَنۡهُ أَبَاهُ وَإِنَّا لَفَٰعِلُونَ
Wọ́n sọ pé: “A máa jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún bàbá rẹ̀ láti gbà á lọ́wọ́ rẹ̀. Dájúdájú àwa máa ṣe bẹ́ẹ̀.”

62 - Yusuf (Joseph) - 062

وَقَالَ لِفِتۡيَٰنِهِ ٱجۡعَلُواْ بِضَٰعَتَهُمۡ فِي رِحَالِهِمۡ لَعَلَّهُمۡ يَعۡرِفُونَهَآ إِذَا ٱنقَلَبُوٓاْ إِلَىٰٓ أَهۡلِهِمۡ لَعَلَّهُمۡ يَرۡجِعُونَ
Ó sì sọ fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé: “Ẹ fi owó-ọjà wọn sínú ẹrù (oúnjẹ) wọn nítorí kí wọ́n lè mọ̀ nígbà tí wọ́n bá padà dé ọ̀dọ̀ ará ilé wọ́n (pé a ti dá a padà fún wọn), wọn yó sì lè padà wá.”

63 - Yusuf (Joseph) - 063

فَلَمَّا رَجَعُوٓاْ إِلَىٰٓ أَبِيهِمۡ قَالُواْ يَـٰٓأَبَانَا مُنِعَ مِنَّا ٱلۡكَيۡلُ فَأَرۡسِلۡ مَعَنَآ أَخَانَا نَكۡتَلۡ وَإِنَّا لَهُۥ لَحَٰفِظُونَ
Nígbà tí wọ́n padà dé ọ̀dọ̀ bàbá wọn, wọ́n sọ pé: “Bàbá wa, wọ́n kọ̀ láti wọn oúnjẹ fún wa. Nítorí náà, jẹ́ kí ọbàkan wa bá wa lọ nítorí kí á lè rí oúnjẹ wọ̀n (wálé). Dájúdájú àwa yóò máa ṣọ́ ọ.”

64 - Yusuf (Joseph) - 064

قَالَ هَلۡ ءَامَنُكُمۡ عَلَيۡهِ إِلَّا كَمَآ أَمِنتُكُمۡ عَلَىٰٓ أَخِيهِ مِن قَبۡلُ فَٱللَّهُ خَيۡرٌ حَٰفِظٗاۖ وَهُوَ أَرۡحَمُ ٱلرَّـٰحِمِينَ
Ó sọ pé: “Ṣé kí n̄g gbà yín gbọ́ lórí rẹ̀ bí kò ṣe bí mó ṣe gbà yín gbọ́ ní ìṣaájú lórí ọmọ-ìyá rẹ̀? Nítorí náà, Allāhu lóore jùlọ ní Olùṣọ́. Òun sì ni Aláàánú-jùlọ nínú àwọn aláàánú.”

65 - Yusuf (Joseph) - 065

وَلَمَّا فَتَحُواْ مَتَٰعَهُمۡ وَجَدُواْ بِضَٰعَتَهُمۡ رُدَّتۡ إِلَيۡهِمۡۖ قَالُواْ يَـٰٓأَبَانَا مَا نَبۡغِيۖ هَٰذِهِۦ بِضَٰعَتُنَا رُدَّتۡ إِلَيۡنَاۖ وَنَمِيرُ أَهۡلَنَا وَنَحۡفَظُ أَخَانَا وَنَزۡدَادُ كَيۡلَ بَعِيرٖۖ ذَٰلِكَ كَيۡلٞ يَسِيرٞ
Nígbà tí wọ́n tú ẹrù oúnjẹ wọn, wọ́n rí i pé wọ́n ti dá owó-ọjà wọn padà fún wọn. Wọ́n sọ pé: “Bàbá wa, kí ni a tún ń fẹ́? Owó-ọjà wa nìyí tí wọ́n ti dá padà fún wa. A ó si tún fi wá oúnjẹ rà fún àwọn ẹbí wa. A ó sì dáàbò bo ọbàkan wa. A sì máa rí àlékún ẹrù oúnjẹ (tí) ràkúnmí kan lè rù sí i. Ìwọ̀n oúnjẹ kékeré sì nìyẹn (lọ́dọ̀ ọba).”

66 - Yusuf (Joseph) - 066

قَالَ لَنۡ أُرۡسِلَهُۥ مَعَكُمۡ حَتَّىٰ تُؤۡتُونِ مَوۡثِقٗا مِّنَ ٱللَّهِ لَتَأۡتُنَّنِي بِهِۦٓ إِلَّآ أَن

Scroll to Top