Ẹ jẹ́ iṣẹ mi koda bo ṣe pẹlu aayah kan, kí ẹ sì sọrọ nipa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kò sí aburu nibẹ, ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ̀ọ́mọ̀ parọ́ mọ́ mi, kí onitọhun yaa tètè mú ibùjókòó rẹ̀ nínú Iná
Lati ọdọ Abdullah ọmọ ‘Amr - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - ó ní dajudaju Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pé: "Ẹ jẹ́ iṣẹ mi koda bo ṣe pẹlu aayah kan, kí ẹ sì sọrọ nipa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kò sí aburu nibẹ, ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ̀ọ́mọ̀ parọ́ mọ́ mi,…

