Ibẹru Ọlọhun dọwọ yín, ati gbigbọ ati itẹle, ko da ki o jẹ ẹru dúdú, ẹ maa pada ri iyapa ẹnu ti o le koko lẹyin mi, sunnah mi ati sunnah awọn arole ẹni imọna ti a ti fi wọn mọna dọwọ yin
Choose an available translation of this Hadeeth
Hadeeth text
Lati ọdọ 'Irbaad ọmọ Saariyah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- duro laaarin wa ni ọjọ kan, o wa ṣe waasu kan ti o de ògòńgó fun wa ti awọn ọkan ń gbọn riri latara rẹ, ti awọn oju n dami latara rẹ, wọn wa sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, o ṣe waasu idagbere fun wa, sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun wa. O sọ pe: "Ibẹru Ọlọhun dọwọ yín, ati gbigbọ ati itẹle, ko da ki o jẹ ẹru dúdú, ẹ maa pada ri iyapa ẹnu ti o le koko lẹyin mi, sunnah mi ati sunnah awọn arole ẹni imọna ti a ti fi wọn mọna dọwọ yin, ẹ di wọn mu pẹlu eyin ọgan, ẹ ṣọra fún awọn adadaalẹ, ati pe dajudaju gbogbo adadaalẹ anu ni".
Explanation
Benefits
Akolekan si awọn waasu ati rirọ awọn ọkan.
Pipaṣẹ pẹlu itẹle awọn arole ẹni imọna ti a fi wọn mọna mẹrẹẹrin lẹyin rẹ, awọn ni Abu Bakr, ati Umar, ati Uthman, ati Aliy- ki Ọlọhun yọnu si wọn-.
Kikọ kuro nibi adadaalẹ ninu ẹsin, ati pe dajudaju gbogbo adadaalẹ anu ni.
Gbigbọ ati itẹle fun ẹni ti o ba n dari alamọri awọn olugbagbọ ni ọna ti o yàtọ̀ si oju ọna ẹṣẹ.
Pataki ibẹru Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- ni gbogbo asiko ati iṣesi.
Iyapa jẹ nnkan ti o n ṣẹlẹ̀ ninu ijọ yìí, nigba ti o ba ṣẹlẹ̀, ṣiṣẹripada si sunnah ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ati ti awọn arole ẹni imọna maa jẹ dandan.
Attribution
Categories
Share hadeeth
Sharing options · 0 Total shares

