Mo fi Ọlọhun bura, ki Ọlọhun fi arákùnrin kan ṣoṣo mọna latara rẹ, o loore fun ẹ ju ki o ni ràkúnmí pupa lọ
Lati ọdọ Sahl ọmọ Sa'd- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ ni ọjọ́ Khaibar pé: Dajudaju maa fun arakunrin kan ni asia yii ni ọla ti Ọlọhun maa ti ipasẹ rẹ fun wa ni iṣẹgun, o nífẹ̀ẹ́ Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ, Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ…

