Kosi ọjọ kan ti awọn ẹrusin yóò jí ní àárọ̀ ayaafi kí ó jasipe awọn malaika (iranṣẹ Ọlọhun) meji yoo sọkalẹ sí ọdọ ẹnikọọkan, ọkan ninu awọn mejeeji yóò máa ṣọ pe: "Irẹ Ọlọhun dakun bá mi ṣe irọpo owo fún ẹni tí n nawo rẹ, bẹẹ ni ikeji yóò máa ṣọ pe: "Bami fi iparun ati ibajẹ sinu owo ẹni tí ó kọ̀ lati ma na owo, tí ó wowọ́ mọ́n owo kankan
Lati ọdọ Abu Hurayrah, kí Ọlọhun bá wa yọnu si, o sọ pe: dájúdájú Anọbi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba - sọ bayi pe: Kosi ọjọ kan ti awọn ẹrusin yóò jí ní àárọ̀ ayaafi kí ó jasipe awọn malaika (iranṣẹ Ọlọhun) meji yoo sọkalẹ sí ọdọ ẹnikọọkan, ọkan ninu awọn mejeeji…

