Mo fi ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura, o maa ku díẹ̀ ki ọmọ Maryam sọkalẹ si aarin yin ni adajo oluṣedeedee, ti o maa run agbelebuu, ti o maa pa ẹlẹ́dẹ̀, ko nii jẹ ki wọn san isakọlẹ mọ, ti owo maa pọ̀ titi ẹni kankan ko fi nii gba a mọ
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Mo fi ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura, o maa ku díẹ̀ ki ọmọ Maryam sọkalẹ si aarin yin ni adajo oluṣedeedee, ti o maa run agbelebuu, ti o maa pa ẹlẹ́dẹ̀, ko nii…

