Ọrọ yẹn ninu ododo ti alujannu n ji gbọ ni o wa, yoo waa gbe e si eti aayo rẹ gẹgẹ bi adiyẹ ṣe maa n gbe ọrọ fun adiyẹ miran, nigba naa ni wọn o waa ro irọ to le ni ọgọrun-un mọ ọn
Choose an available translation of this Hadeeth
Hadeeth text
Lati ọdọ ‘Āisha – ki Ọlọhun yọnu si i– o sọ pe: Awọn eeyan kan bi Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – leere nipa awọn adagbigba, ni Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – wa sọ fun wọn pe: «Wọn o jẹ nkankan» wọn sọ pé: Irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, dajudaju wọn maa n sọ awọn nkan ni igba miran ti yio si jẹ ododo, ni Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – wa sọ pe: «Ọrọ yẹn ninu ododo ti alujannu n ji gbọ ni o wa, yoo waa gbe e si eti aayo rẹ gẹgẹ bi adiyẹ ṣe maa n gbe ọrọ fun adiyẹ miran, nigba naa ni wọn o waa ro irọ to le ni ọgọrun-un mọ ọn».
Explanation
Ni wọn wa sọ pe: Dajudaju ọrọ wọn maa n ṣe deedee nkan ti n ṣẹlẹ ni igba miran, gẹgẹ bii ti wọn ba sọ nipa iṣẹlẹ alamọri kọkọ kan ni oṣu bayii ni ọjọ bayii, ti yio si ṣẹlẹ ni ibamu si ọrọ wọn.
Ni o wa sọ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – pe: Dajudaju awọn alujannu maa n ji awọn iroyin sanmọ gbọ, nigba naa ni wọn yio wa sọkalẹ wa ba awọn aayo wọn ninu awọn adagbigba ti wọn o si fun wọn ni iro nkan ti wọn gbọ, lẹ́yìn naa ni adagbigba o fi irọ ọgọrun-un kun eyi ti o gbọ lati sanmọ.
Benefits
Wọn sọ sanmọ kuro lọwọ awọn eṣu pẹlu gbigbe Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – dide, kuro nibi mimaa gbọ nkankan ninu imisi tabi ohun ti o yatọ si i, ayaafi eyi ti o ba ji ọrọ gbọ ti o si la lọwọ ògúnná.
Awọn alujannu maa n mu awọn aayo ninu awọn eeyan.
Attribution
Categories
Share hadeeth
Sharing options · 0 Total shares

