Mo fi Ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura, dajudaju emi ni irun mi jọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ju ninu yin, eleyii si ni irun rẹ titi o fi fi aye silẹ
Choose an available translation of this Hadeeth
Hadeeth text
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i-: O maa n kabara nibi gbogbo irun ninu eyi ti o jẹ ọran-anyan ati eyi ti o yatọ si i, ninu Ramadan ati oṣu ti o yatọ si i, o maa n kabara nigba ti o ba dìde, lẹyin naa o maa n kabara nigba ti o ba rukuu, lẹyin naa o maa n sọ pe: Sami’alloohu liman hamidaHu, lẹyin naa o maa n sọ pe: Robbanaa wa laKal hamdu, ṣíwájú ki o to forikanlẹ, lẹyin naa o maa n sọ pe: Allahu Akbar nigba ti o ba lọ silẹ ni ẹni ti o forikanlẹ, lẹyin naa o maa n kabara nigba ti o ba gbe ori dide lati iforikanlẹ, lẹyin naa o maa n kabara nigba ti o ba forikanlẹ, lẹyin naa o maa n kabara nigba ti o ba gbe ori dide lati iforikanlẹ, lẹyin naa o maa n kabara nigba ti o ba dide lati ijokoo nibi rakah meji naa; o maa n ṣe bẹẹ nibi gbogbo rakah, titi o maa fi pari irun, lẹyin naa o maa n sọ ti o ba ti n lọ pe : Mo fi Ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura, dajudaju emi ni irun mi jọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ju ninu yin, eleyii si ni irun rẹ titi o fi fi aye silẹ.
Explanation
Lẹyin naa Abu Huraira maa n sọ ti o ba ti pari irun pé: Mo fi Ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura, dajudaju ẹmi ni ìrun mi jọ irun ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- jù, bi o ṣe maa n kirun nìyí titi o fi fi aye silẹ.
Benefits
Iko akolekan awọn sahaabe lori kikọṣe Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ati ṣiṣọ sunnah rẹ.
Attribution
Categories
Share hadeeth
Sharing options · 0 Total shares

