Wọn pa mi laṣẹ ki n fi ori kan'lẹ lori oríkèé meje
Choose an available translation of this Hadeeth
Hadeeth text
Lati ọdọ ọmọ Abbās - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe: «Wọn pa mi laṣẹ ki n fi ori kan'lẹ lori oríkèé meje: Lori iwaju ori, o si na ọwọ rẹ si imu rẹ, ati ọwọ mejeeji, ati orunkun mejeeji, ati awọn ọmọ ika ẹsẹ mejeeji, ati pe ki a ma ka awọn aṣọ ati irun».
Explanation
Alakọkọọ: Iwaju ori: Oun ni: Alawẹ oju ti o wa ni oke imu ati oju mejeeji, Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a, fi ọwọ rẹ si imu rẹ, ti o fihan pe iwaju ati imu jẹ ọkan ninu awọn meje naa, o si tẹnumọ pe ẹni ti o n fi ori kan ilẹ maa fi kan ilẹ pẹlu imu rẹ.
Oríkèé kejì ati ìkẹta: Ọwọ mejeeji.
Ẹlẹẹkẹrin ati Ẹlẹẹkarun-un: Orunkun mejeeji.
Ẹlẹẹkẹfa ati Ẹlẹẹkeje: Awọn ọmọ ika ẹsẹ mejeeji.
O si tun pa wa laṣẹ ki a ma so awọn irun wa, ki a si ma ka awọn aṣọ wa papọ nibi iforikanlẹ lati fi da aabo bo o; bi ko ṣe pe a maa da a silẹ titi ti yio fi kan ilẹ, nitori naa yio le'lẹ pẹlu awọn orikee ara naa.
Benefits
Kikorira lilọ aṣọ ati irun papọ ni ori irun.
O jẹ dandan fun ẹni ti n kirun ki o fi ara balẹ ninu irun rẹ, iyẹn ni pe ki o gbe awọn oríkèé iforikanlẹ meje le ilẹ, ki o si fi ara balẹ lori rẹ titi ti yio fi mu iranti ti wọn ṣe lofin nibẹ wa.
Kikọ kuro nibi lilọ irun jẹ ẹsa fun awọn ọkunrin yatọ si awọn obinrin; nitori pe dajudaju wọn pa obinrin ni aṣẹ pẹlu bibo ara ni ori irun.
Attribution
Categories
Share hadeeth
Sharing options · 0 Total shares

