Ẹyin ènìyàn, dajudaju mo ṣe eyi ki ẹ le tẹle mi ki ẹ si le kọ́ irun kiki mi”
Choose an available translation of this Hadeeth
Hadeeth text
Lati ọdọ Abu Haazim ọmọ Diinaar: Dajudaju awọn ọkunrin kan wa ba Sahl ọmọ Sahd As-Saa’idiyy, wọn ṣe iyemeji nipa minbari latara nnkan wo ni igi rẹ ti wa, ni wọn wa bi i leere nipa ìyẹn, ni o wa sọ pe: Mo fi Ọlọhun bura, mo mọ latara nnkan ti o ti wa, dajudaju mo ri i ni ọjọ akọkọ ti wọn gbe e kalẹ, ati ọjọ akọkọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- jokoo sori rẹ, ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ranṣẹ si lagbaja- obinrin kan ninu awọn Ansar ti Sahl si ti dárúkọ rẹ-: “Pa ọmọ-ọdọ rẹ ti o jẹ kafinta láṣẹ ki o kan awọn igi kan fun mi ti maa maa jokoo le wọn lori ti mọ ba fẹ ba awọn eniyan sọ̀rọ̀”, ni o wa pa a láṣẹ o si ṣe e latara igi TỌRFAAHU ti o maa n wa nínú igbó, lẹyin naa o gbe e wa, ni o wa ranṣẹ si ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o wa ni ki wọn gbe wọn kalẹ sí ibì kan, lẹyin naa ni mo ri ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o kirun lori rẹ, ti o si kabara nigba ti o wa lori rẹ, lẹyin naa o rukuu ti o si wa lori rẹ, lẹyin naa o sọkalẹ ti o n fi ẹyin rìn, ni o wa forikanlẹ sibi isalẹ minbari, lẹyin naa o ṣẹri pada, nigba ti o pari o doju kọ awọn eniyan, ni o wa sọ pe: “Ẹyin ènìyàn, dajudaju mo ṣe eyi ki ẹ le tẹle mi ki ẹ si le kọ́ irun kiki mi”.
Explanation
Benefits
Ṣíṣe kiki irun lori minbari lẹtọọ fun kikọni ni imọ, ati ṣíṣe ki imam ga ju ero ẹyin lọ ti a ba bukaata si i.
Ṣíṣe wiwa iranlọwọ awọn oniṣẹ-ọwọ lẹtọọ nibi awọn bukaata awọn Musulumi.
Ṣíṣe imira kekere lẹtọọ lori irun ti a ba bukaata si i.
Ṣíṣe ki ero ẹyin maa wo Imam rẹ lẹtọọ lori irun; lati le kọ ẹkọ lọdọ rẹ, ati pe dajudaju ìyẹn ko tako irẹlẹ lori irun.
Attribution
Categories
Share hadeeth
Sharing options · 0 Total shares

