Lọ ba a ki o si sọ fun un pe: Dajudaju irẹ ko si ninu awọn ọmọ ina, ṣugbọn o wa ninu awọn ọmọ alujanna
Choose an available translation of this Hadeeth
Hadeeth text
Lati ọdọ Anas ọmọ Mālik – ki Ọlọhun yọnu si i: Dajudaju Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe afẹku Thābit ọmọ Qaysi, ni arakunrin kan wa sọ pe: Irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, maa mu iro rẹ wa fun ọ, ni o ba wa ba a ti o si ba a ni ẹni ti o jokoo si inu ile rẹ, ti o da ori rẹ kodo, ni o wa sọ pe: Ki lo ṣe ẹ? O sọ pe: Aburu ni, o maa n gbe ohun rẹ soke tayọ ohun Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, nitori naa iṣẹ rẹ ti bajẹ, ati pe oun ti wa ninu awọn ọmọ ina, ni arakunrin naa ba pada wa ti o si fun un niroo wí pé o sọ bai bai, o tun wa pada wa ni igba ikẹhin pẹlu iro idunnu ti o tobi, nigba naa ni o wa sọ pe: «Lọ ba a ki o si sọ fun un pe: Dajudaju irẹ ko si ninu awọn ọmọ ina, ṣugbọn o wa ninu awọn ọmọ alujanna».
Explanation
Ni arakunrin naa wa pada si ọdọ Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – o si fun un niroo nipa iyẹn, ni Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – wa pa a laṣẹ ki o ṣẹri pada si ọdọ Thābit ki o si fun un ni iro idunnu wipe dajudaju ko si ninu awọn ọmọ ina, ṣugbọn o wa ninu awọn ọmọ alujanna, ati pe lilọ soke ohun rẹ iṣẹda rẹ ni, ati pe o jẹ agbẹnusọ fun Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – o si tun jẹ agbẹnusọ fun awọn An-soor.
Benefits
Akolekan Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – pẹlu awọn saabe ati bíbéèrè rẹ nípa wọn.
Ibẹru awọn saabe – ki Ọlọhun yọnu si wọn – ati ipaya wọn nipa pe ki awọn iṣẹ wọn o ma bajẹ.
Jijẹ dandan lilo ẹkọ nibi biba a – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọrọ ni igba aye rẹ, ati rirẹ ohun nilẹ nigba ti a ba n gbọ sunnah rẹ lẹyin iku rẹ.
Attribution
Categories
Share hadeeth
Sharing options · 0 Total shares

