“Ọlọhun fi àkàwé kan lélẹ̀ nipa ojú ọ̀nà tààrà kan
Choose an available translation of this Hadeeth
Hadeeth text
Lati ọdọ An-Nawwaas ọmọ Sam’haan Al-Ansaariy- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pé: “Ọlọhun fi àkàwé kan lélẹ̀ nipa ojú ọ̀nà tààrà kan, ti ògiri méjì wa ni ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ojú ọ̀nà naa, ti àwọn ẹnu ọ̀nà ti wọn ṣí silẹ wa nibẹ, ti àwọn aṣọ ẹnu ọ̀nà ti wọn dà wálẹ̀ si n bẹ ni àwọn ẹnu ọ̀nà naa, olupepe kan n bẹ ni ẹnu ọ̀nà ojú ọ̀nà naa ti n sọ pé: Ẹ̀yin èèyàn, gbogbo yin ẹ ko sínú ọ̀nà naa, ẹ má ṣe wọ́, ati olupepe kan ti n pepe lati òkè ọ̀nà naa, ti o ba ti wa fẹ ṣí nǹkan kan ninu awọn ojú ọ̀nà yẹn, o maa sọ pé: Káì, ma ṣi i, ti o ba fi le ṣi i wàá wọ̀ ọ́, ojú ọ̀nà naa ni Isilaamu, àwọn ògiri méjèèjì naa ni: Awọn ààlà Ọlọhun, àwọn ẹnu ọ̀nà ti wọn ṣi silẹ ni: Awọn nǹkan ti Ọlọhun ṣe ni eewọ, ẹni tí n pepe ni orí ojú ọ̀nà naa ni: Tira Ọlọhun, ẹni tí n pepe ni òkè ojú ọ̀nà naa ni: Oníwàásù Ọlọhun ninu ọkàn gbogbo Musulumi”.
Explanation
Benefits
Dandan ni didunni mọ àwọn ààlà Ọlọhun ati nǹkan ti O ṣe ni ẹtọ ati nǹkan ti O ṣe ni eewọ, ati pe fífi ọwọ dẹngẹrẹ mu un maa fa ìparun.
Ọla ti n bẹ fun Kuraani, ati ṣisẹnilojukokoro lori ṣíṣe àmúlò rẹ, imọna wa ninu rẹ ati imọlẹ ati jijẹ èrè.
Aanu Ọlọhun si awọn ẹru Rẹ, ati si ohun ti O fi sinu ọkàn àwọn mumini ni ohun ti yoo kọ fun wọn ti o si maa ṣe iṣiti fun wọn ti wọn ko fi nii ko sinu ìparun.
Ninu aanu Ọlọhun ni pe O fun awọn ẹru ni àwọn ìdènà ti ko nii jẹ ki wọn ko sinu ẹṣẹ.
Ninu ọna ìkọ́ni ni ẹ̀kọ́ ni fifi àkàwé lélẹ̀ lati fi sun un mọ ati lati le ṣàlàyé.
Attribution
Categories
Share hadeeth
Sharing options · 0 Total shares

