mo wa fi Ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura, ẹ o maa tẹle ilana awọn ti wọn ṣaaju yin
Choose an available translation of this Hadeeth
Hadeeth text
Lati ọdọ Abu Waaqid Al-Laythiy - ki Ọlọhun yọnu si i: Dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - nigba ti o jade lọ si Hunayn o rekọja nibi igi kan ti o jẹ ti awọn ọṣẹbọ ti wọn n pe e ni: Dhaatu anwaat ti wọn maa n fi awọn nkan ija wọn kọ ọ, ni wọn wa sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, ṣe dhaatu anwaat fun wa gẹgẹ bi wọn ṣe ni dhaatu anwaat, ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ pe: «Mimọ fun Ọlọhun! Eleyii da gẹgẹ bi nkan ti awọn ijọ Musa sọ {ṣe òrìṣà kan fún wa, gẹ́gẹ́ bí àwọn (wọ̀nyí) ṣe ní àwọn òrìṣà kan} [Al-'A‘roof: 138] mo wa fi Ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura, ẹ o maa tẹle ilana awọn ti wọn ṣaaju yin».
Explanation
Benefits
O tọ fun musulumi ki o ṣe afọmọ ki o si gbe titobi fun Ọlọhun nigba ti o ba gbọ nkan ti ko lẹtọọ ki wọn o maa sọ nipa ẹsin, ati nigba ti o ba n ṣe eemọ.
Ninu ẹbọ ni wiwa alubarika pẹlu awọn igi ati awọn okuta ati nkan ti o yatọ si i, ati pe alubarika ọdọ Ọlọhun ni a ti maa n beere fun un.
Okunfa jijọsin fun awọn oriṣa ni gbigbe wọn tobi, ati ṣiṣe atipo ni ọdọ wọn, ati wiwa alubarika pẹlu wọn.
Jijẹ dandan titi awọn ilẹkun ati awọn ọna ti o le gbe wa de ibi ẹbọ.
Nkan ti o wa ninu awọn ọrọ nipa bibu awọn Yahudi ati Nasaara ikilọ ni fun wa.
Kikọ kuro nibi imaa farajọ awọn ara igba aimọ ati awọn Juu ati Nasaara, ayaafi nkan ti ẹri ba wa fun un pe ninu ẹsin wa lo wa.
Attribution
Categories
Share hadeeth
Sharing options · 0 Total shares

