Mumini alagbara ni oore o si tun jẹ ẹni ti Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si ju Mumini ọlẹ lọ, ọkọọkan wọn si ni oore wa lara rẹ,
Choose an available translation of this Hadeeth
Hadeeth text
Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Mumini alagbara ni oore o si tun jẹ ẹni ti Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si ju Mumini ọlẹ lọ, ọkọọkan wọn si ni oore wa lara rẹ, maa ṣe ojukokoro lori nkan ti yio ṣe ọ ni anfaani, ki o si tun wa iranlọwọ pẹlu Ọlọhun, má si kagara, ati pe ti nkankan ba ṣẹlẹ si ọ, o ko wa gbọdọ sọ pe kani mo ṣe báyìí nkan báyìí báyìí ni ko ba jẹ, ṣugbọn sọ pe kọdarullāh wa maa sha'a fa‘al "akọsilẹ Ọlọhun ni, nkan ti O si fẹ ni O ṣe", tori pe (lao) "kani" o maa ṣina iṣẹ satani»
Explanation
Benefits
Nini ìfẹ́ si agbara nibi awọn iṣẹ; torí pé dajudaju yio maa ṣẹlẹ pẹlu rẹ anfaani ti ko le ṣẹlẹ pẹlu ikọlẹ.
Ọmọniyan gbọdọ maa ṣe ojukokoro lori nkan ti yio ṣe e ni anfaani, ki o si fi nkan ti ko nii ṣe e ni anfaani silẹ.
O jẹ dandan fun Mumuni ki o wa ikunlọwọ Ọlọhun nibi gbogbo alamọri rẹ, ki o si ma gbarale ara rẹ.
Fifi akọsilẹ ati kadara rinlẹ, ati pe dajudaju ko tako ṣiṣe awọn okunfa ati gbigbiyanju nibi wiwa awọn nkan daadaa.
Kikọ kuro nibi sisọ gbolohun «kani» ní ti ibinu nigba ti adanwo ba sọkalẹ, ati ṣiṣe ni eewọ titako idajọ ati akọsilẹ ti Ọlọhun.
Attribution
Categories
Share hadeeth
Sharing options · 0 Total shares

