Wọn bi ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere nipa nǹkan ti o maa mu awọn èèyàn wọ alujanna julọ, o sọ pe: “Ìpayà Ọlọhun ati iwa dáadáa
Choose an available translation of this Hadeeth
Hadeeth text
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Wọn bi ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere nipa nǹkan ti o maa mu awọn èèyàn wọ alujanna julọ, o sọ pe: “Ìpayà Ọlọhun ati iwa dáadáa”, wọn tun bi i leere nipa nnkan ti o maa mu awọn èèyàn wọ ina julọ, o sọ pe: “Ẹnu ati Abẹ”.
Explanation
Ipaya Ọlọhun ati iwa dáadáa.
Ìpayà Ọlọhun: Oun ni ki o fi aabo si aarin rẹ ati iya Ọlọhun, pẹ̀lú ṣíṣe àwọn nǹkan ti O pàṣẹ lati ṣe, ati jíjìnnà si awọn nǹkan ti O kọ̀.
Iwa dáadáa: O maa jẹ pẹlu títú ojú ká, ati ṣíṣe dáadáa, ati ki èèyàn ma jẹ ki suta kan ẹlòmíràn.
Eyi ti o tobi ju ninu awọn okùnfà ti yoo mu awọn èèyàn wọ ina meji ni, àwọn naa ni:
Ahọn ati Abẹ́.
Lara àwọn ẹṣẹ ahọ́n ni: Irọ́, ọ̀rọ̀-ẹ̀yìn, òfófó, ati awọn mìíràn.
Lara àwọn ẹṣẹ abẹ́ ni: Ṣìná, ati ibalopọ láàrin ọkùnrin si ọkùnrin, ati awọn mìíràn.
Benefits
Ewu ahọn fun ẹni tí ó ni ín, ati pe o wa ninu awọn okùnfà wíwọ iná.
Ewu ìfẹ́-adùn ati awọn ìwà ibajẹ fun ọmọniyan, ati pe wọn wa ninu awọn okùnfà ti o pọ julọ lati wọ iná .
Attribution
Categories
Share hadeeth
Sharing options · 0 Total shares

