“Ẹni tí ó bá ki irun asunbaa, onítọ̀hún ti wa nínú ààbò Ọlọhun
Choose an available translation of this Hadeeth
Hadeeth text
Láti ọ̀dọ̀ Jundub ọmọ Abdullahi Al-Qasriy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹni tí ó bá ki irun asunbaa, onítọ̀hún ti wa nínú ààbò Ọlọhun, nítorí náà ẹ ṣọ́ra ki Ọlọhun ma baa bi yin leere nǹkan kan ninu ààbò Rẹ̀; torí ẹni ti Ọlọhun ba bi leere nǹkan kan nínú ààbò Rẹ̀, yoo gba ẹsan lara rẹ, yoo si da ojú rẹ bo ilẹ̀ ninu ina Jahannama”.
Explanation
Lẹyin naa ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa ṣọ wa lara kúrò nibi títú àdéhùn naa ati biba a jẹ́, yálà pẹlu gbigbe irun alufajari ju silẹ ni, tabi ìkọlù ẹni ti n ki i, ẹni tí ó bá ṣe iyẹn ti ba ààbò yii jẹ́, o si ni ẹtọ si àdéhùn ìjìyà ti o le koko pẹ̀lú pe ki Ọlọhun bi i leere nípa ohun tí o ṣe àṣeètó nibẹ nibi ẹtọ Rẹ, ẹni tí Ọlọhun ba bi léèrè, yoo gba ẹsan lara rẹ, lẹ́yìn náà yoo da oju rẹ bo ilẹ̀ ninu iná.
Benefits
Ikilọ ti o le koko kuro nibi ṣíṣe aburú si ẹni ti o ba ki irun alufajari.
Ọlọhun ti ọla Rẹ ga maa n ba àwọn ẹrú Rẹ ti wọn jẹ ẹni rere gba ẹsan lara ẹni tí ó ba n dènà dè wọ́n.
Attribution
Categories
Share hadeeth
Sharing options · 0 Total shares

