Fiforikanlẹ fun Ọlọhun lọpọlọpọ jẹ dandan fun ẹ, dajudaju o ko nii forikanlẹ fun Ọlọhun ni iforikanlẹ ẹẹkan, afi ki Ọlọhun fi gbé ẹ ga nipo, ki O si fi ba ẹ pa ẹṣẹ rẹ
Choose an available translation of this Hadeeth
Hadeeth text
Lati ọdọ Ma'daan ọmọ Abu Tolha Al-Ya'mariy o sọ pe: Mo pade Thaobaan ẹru ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- mo wa sọ pe: Fun mi ni iro nipa iṣẹ kan ti mo ba n ṣe e Ọlọhun maa fi mu mi wọnu alujanna? Tabi o sọ pe mo sọ pé: pẹlu eyi ti Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si julọ ninu awọn iṣẹ, o ba dakẹ. Lẹ́yìn naa mo bi i leere ni o ba dakẹ. Lẹ́yìn naa mo bi i leere ni ẹẹketa, o wa sọ pe: Mo beere nipa ìyẹn lọwọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o sọ pe: Fiforikanlẹ fun Ọlọhun lọpọlọpọ jẹ dandan fun ẹ, dajudaju o ko nii forikanlẹ fun Ọlọhun ni iforikanlẹ ẹẹkan, afi ki Ọlọhun fi gbé ẹ ga nipo, ki O si fi ba ẹ pa ẹṣẹ rẹ" Ma'daan sọ pe: Lẹyin naa mo pade Abu Dardaa mo si bi i leere, o si sọ fun mi: Iru nnkan ti Thaobaan sọ fun mi.
Explanation
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun olubeere pe: Dunni mọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ iforikanlẹ nibi irun, o ko nii forikanlẹ fun Ọlọhun ni iforikanlẹ kan afi ki O fi gbe ẹ ga nípò, ki O si fi i ṣe aforijin fun ẹ.
Benefits
Alaye agbọye ẹsin awọn saabe ati imọ wọn pe dajudaju alujanna wọn ko lee wọ ọ- lẹyin ikẹ Ọlọhun- afi pẹlu iṣẹ.
Iforikanlẹ nibi irun wa ninu eyi ti o tobi julọ ninu awọn okunfa igbe awọn ipo ga, ati aforijin àwọn ẹṣẹ.
Attribution
Categories
Share hadeeth
Sharing options · 0 Total shares

