Ṣé ki n tọka yin si nnkan ti Ọlọhun fi maa n pa awọn àṣìṣe rẹ, ti O si fi maa n gbe awọn ipo ga?
Choose an available translation of this Hadeeth
Hadeeth text
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Ṣé ki n tọka yin si nnkan ti Ọlọhun fi maa n pa awọn àṣìṣe rẹ, ti O si fi maa n gbe awọn ipo ga?" Wọn sọ pe bẹẹni irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, o sọ pe: "Ṣíṣe aluwala ni pípé lori ìnira, ati gbigbe igbẹsẹ pupọ lọ si mọsalasi, ati rireti irun lẹyin irun, ìyẹn ni ida ààbò bo ẹnu ààlà ìlú".
Explanation
Awọn saabe sọ pe: Bẹẹni a fẹ ìyẹn. O sọ pe:
Akọkọ: Kikari ati pipe aluwala lori inira; gẹgẹ bii otutu, ati kíkéré omi, ati inira ara, ati omi gbigbona.
Ikeji: Ọ̀pọ̀lọpọ̀ igbesẹ- oun ni nnkan ti o wa laaarin ẹsẹ mejeeji- lọ si awọn mọsalasi latara jijina ilé, ati ọ̀pọ̀lọpọ̀ pipaara.
Ikẹta: Rireti asiko irun, ati sisopọ ọkan mọ ọn, ati ìgbáradì fun un, ati jijokoo sinu mọsalasi fun ireti janmọọn, ti o ba ti ki i ki o maa reti irun miiran ni aaye ti o ti kirun.
Lẹyin naa, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju awọn àlámọ̀rí yii gan-an ni dida ààbò bo ẹnu ààlà ìlú; nitori pe o maa n kọdi awọn oju ọna èṣù lọ sọ́dọ̀ ẹmi, o si maa n bori ifẹ inu, ti o maa kọ fun un kuro nibi gbigba awọn royiroyi wọle, ti ijọ Ọlọhun fi maa bori awọn ọmọ ogun èṣù pẹlu rẹ; ìyẹn ni ijagun soju ọna Ọlọhun ti o tobi julọ, o waa wa ni ipo dida ààbò bo ẹnu ààlà ìlú ọ̀tá.
Benefits
Didaa agbekalẹ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ati mimu awọn saabe rẹ jẹ̀rán nigba ti o bẹ̀rẹ̀ fun wọn pẹlu ẹsan ti o tobi ni ọna ibeere, ati pe ọna yii wa ninu awọn ọna ikọnilẹkọọ.
Anfaani ti o n bẹ nibi ṣíṣe àfihàn ọ̀rọ̀ pẹlu ìbéèrè ati idahun ni: Ki ọrọ le wọni lọ́kàn gan-an nítorí kiko àìṣekedere pọ̀ mọ́ ìṣekedere.
An-nawawi- ki Ọlọhun kẹ ẹ- sọ pe: FAZAALIKUMU-R-RIBAAT n túmọ̀ si: Ribaat ti a fẹ́, ipilẹ ribaat si ni ki èèyàn di nǹkan mú ṣinṣin, bii ìgbà tí o de ẹ̀mí ara rẹ mọ́lẹ̀ fun itẹle aṣẹ yii, wọn sọ pé: Òun ni o daa julọ ninu awọn ribaat gẹgẹ bi wọn ṣe sọ pe: Ijagun soju ọna Ọlọhun ni jija ẹ̀mí lógun, o si tun le túmọ̀ si ribaat ti o rọrun, o n túmọ̀ si pe: O wa ninu awọn oríṣiríṣi ribaat.
Wọn paara gbolohun "Ar-Ribaat" wọn si so Alif ati Laam mọ́ ọn; ìyẹn jẹ igbetobi fun àlámọ̀rí awọn iṣẹ yìí.
Attribution
Categories
Share hadeeth
Sharing options · 0 Total shares

