Awọn oru mẹwa Oun ni awọn oru oṣu Dhul-Hijjah Kini a fẹ fi pade awọn ọjọ wọnyi?
Awọn oru mẹwa Oun ni awọn oru oṣu Dhul-Hijjah Kini a fẹ fi pade awọn ọjọ wọnyi? Lati ọdọ Ibnu Abbas, o sọpe: Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa baa - sọ pe: Kò sí awọn ọjọ́ kan tí Ọlọ́hun nifẹ si iṣẹ́ rere ninu wọn ju àwọn ọjọ́ wọ̀nyii lọ. (Iyẹn awọn ọjọ mẹwa akọọkọ) Wọn sọ pe: Irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, ṣe koda ki o jẹ pe jijagun si oju ọna Ọlọhun ni iṣẹ naa? O sọ pe: beeni, koda ki o jẹ...
Awọn oru mẹwa Oun ni awọn oru oṣu Dhul-Hijjah Kini a fẹ fi pade awọn ọjọ wọnyi?
Awọn oru mẹwa
Oun ni awọn oru oṣu Dhul-Hijjah
Kini a fẹ fi pade awọn ọjọ wọnyi?
Lati ọdọ Ibnu Abbas, o sọpe: Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa baa - sọ pe:
Kò sí awọn ọjọ́ kan tí Ọlọ́hun nifẹ si iṣẹ́ rere ninu wọn ju àwọn ọjọ́ wọ̀nyii lọ. (Iyẹn awọn ọjọ mẹwa akọọkọ)
Wọn sọ pe: Irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, ṣe koda ki o jẹ pe jijagun si oju ọna Ọlọhun ni iṣẹ naa?
O sọ pe: beeni, koda ki o jẹ pe jijagun si oju ọna Ọlọhun ni iṣẹ naa, ayafi ọkunrin kan ti o jade pẹlu ẹmi rẹ ati owo rẹ lẹhinna ko pada sile pẹlu nkankan ninu ẹ.
Iṣẹ rere kó oriṣiriṣi awọn ijọsin sinu, gẹgẹ bii ãwẹ, irun, Hajj, zikiri, gbigbe Ọlọhun tobi, kika Al-Quraani, ati ninawo si awọn ọna oloore, ati bẹebẹe lọ.
Ninu awọn iṣẹ rere ti o fi ẹsẹ rinlẹ ni awọn ọjọ wọnyii ni:
1- Gbigba aawẹ ayafi ni ọjọ kewa.
Lati ọdọ awọn kan ninu awọn iyawo Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa baa -, wọn sọ pe: Anabi maa n gba aawẹ ọjọ mẹsan akọkọọ ninu ọṣu Dhul-Hijjah paapaa julọ ni ọjọ Arafat, eyiti gbigba aawẹ ni ọjọ naa maa n pa ẹṣẹ ọdun meji rẹ.
2- Ṣiṣe Hajj, oun ni iṣẹ t'oni ọla julọ ni awọn ọjọ mẹwa yii, ati pe Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ti sọ pe: Hajj ti eniyan se daadaa ko si ẹsan kankan fun ayafi Alujannah.
3- Pipa ẹran ileya, eleyi jẹ sunnah ti o kanpa, ẹnikẹni ti o ba si gbero lati pa ẹran ileya, ko ni ge irun ati eekanan rẹ lati ibẹrẹ oṣu Dhul-Hijjah titi yoo fi pa ẹran ileya rẹ.
4- Ṣiṣe ọpọlọpọ Laa ilaaha illah Allah ati Allahu Akbar ati Alhamdulillah.
Bi a ṣe maa maa wi ni pe: Allahu Akbar Allahu Akbar Allahu Akbar Laa ilaaha illah Allahu Allahu Akbar Allahu Akbar wa li Laahil hamd.
Awọn oru mẹwa Oun ni awọn oru oṣu Dhul-Hijjah Kini a fẹ fi pade awọn ọjọ wọnyi?
Scan QR Code | Use a QR Code Scanner to fast download directly to your mobile device