🌸 Obinrin Ninu Islam

المرأة في الإسلام
اللغة يوربا

🌸 Obinrin Ninu Islam

Obinrin jẹ ẹni apọnle ati aabo, o ni apọnle ọmọniyan ti o pe perepere, pẹlu fifi rinlẹ pe gbogbo ọkunrin ati gbogbo obinrin ni wọn ni adamọ ọtọọtọ ti a ṣalẹṣa fun ẹni kọọkan wọn.

⚖️ Awọn obinrin ni awọn ẹtọ ti o foju han, ti o si fọkanbalẹ:

• 🎓 Kikọ imọ: Wiwa imọ jẹ ọranyan ati ẹtọ ipinlẹ fun wọn.

• 💰 Ohun-ini: Etọ ni fun wọn lati ṣakoso dukia wọn funra wọn pẹlu ominira pipe lati na owo wọn funra wọn.

• 💼 Iṣẹ: kikọpa ninu idagbasoke awujọ ni awọn ọna ti o ba adamọ wọn mu.

• 💍 Yiyan ọkọ: Wọn ni ominira ati agbara lati yan bi wọn se fẹ se eto igbesi aye lọkọlaya wọn.

❤️ Ipo Iya ati Asọtẹlẹ Anabi:

Islam gbe ipo awọn Iya ga pupọ, o si se sise daada si wọn ni ọkan ninu awọn iṣẹ ti o tobi lati fi sun mọ Ọlọhun.

Anabi Muhammad (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a) sọ pe: “Ẹ maa tọju awọn obinrin daadaa”.

Ó tún sọ pé: “Ènìyàn kan ko ni pọn awọn obinrin le ayaafi ki onitọhun jẹ ẹni apọnle, eniyan kan ko si nii yẹpẹrẹ wọn ayaafi ki o jẹ ẹni burúkú.”

📖 Ninu awọn apọnle ti Al-Qur'an se fun awọn Obinrin:

• Odindi suurah kan ni o sọ ni "Suratu An-Nisa" (Suura awọn Obinrin).

• Ko si obinrin kankan ti wọn darukọ rẹ pọrọngọndọn ninu Al-Qur’an ayaafi Maryam.

• Odindi suurah kan ni wọn sọ orukọ rẹ ni “Suratu Maryam,” ki o maa jẹ apọnle fun un, ati nitori iwa mimọ rẹ ati igbagbọ rẹ.

✨ Awọn Apẹẹrẹ pataki ti o ti di itan ti yoo maa bẹ titi laelae:

• Aasia: ti o gba Ọlọhun gbọ, o si tọju Anabi Musa (ki ikẹ Ọlọhun maa ba a).

• Maryam ọmọ Imran: Iya Anabi Isa (ki alaafia Ọlọhun maa ba a), apẹẹrẹ awokọse ni o jẹ ninu iwa mimọ ati igbagbọ.

🌱 Obinrin ati Awujọ:

Awọn obinrin jẹ olutọju awọn iran ati oluwuwa ti o niye lori, wọ́n jẹ́ ẹni ti wọ́n ni òmìnira, iwa mímọ́ ati apọnle, tí wọ́n dáàbò bo ara wọn, tí wọ́n sì n sọ iyì ara wọn.

• Hijab: jẹ ijọsin ati ọna lati fi apọnle fun eniyan, kii se irisi eniyan lasan, o si jẹ isafihan igbagbọ ati itiju.

• Idile: Eto kan ni ti o da lori aanu, deede, ati ifọwọsowọpọ.

• Agbara: Agbara obinrin wa ninu igbagbọ rẹ, itiju rẹ, suuru rẹ, ati oripa rẹ ninu idagbasoke awujọ.

Islam se e ni eewọ pe ki a maa se abosi fun awọn obinrin, o si pasẹ pe ki a maa se daada si wọn.

Yoo dun mọwa ninu lati rí awọn ibeere yin nipa ipo awọn obinrin ninu Islam.

🌐 sarhaan.com

#Obinrin #Islam #Ẹtọ Awọn Obinrin #Ẹbi #Iwa mimọ

Shopping Basket