القصص
Al-Qasas
The Stories
1 - Al-Qasas (The Stories) - 001
طسٓمٓ
Tọ̄ sīn mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1]
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:1.
2 - Al-Qasas (The Stories) - 002
تِلۡكَ ءَايَٰتُ ٱلۡكِتَٰبِ ٱلۡمُبِينِ
Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà tó ń yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá.
3 - Al-Qasas (The Stories) - 003
نَتۡلُواْ عَلَيۡكَ مِن نَّبَإِ مُوسَىٰ وَفِرۡعَوۡنَ بِٱلۡحَقِّ لِقَوۡمٖ يُؤۡمِنُونَ
À ń ké nínú ìró (Ànábì) Mūsā àti Fir‘aon fún ọ pẹ̀lú òdodo nítorí ìjọ tó gbàgbọ́ lódodo.
4 - Al-Qasas (The Stories) - 004
إِنَّ فِرۡعَوۡنَ عَلَا فِي ٱلۡأَرۡضِ وَجَعَلَ أَهۡلَهَا شِيَعٗا يَسۡتَضۡعِفُ طَآئِفَةٗ مِّنۡهُمۡ يُذَبِّحُ أَبۡنَآءَهُمۡ وَيَسۡتَحۡيِۦ نِسَآءَهُمۡۚ إِنَّهُۥ كَانَ مِنَ ٱلۡمُفۡسِدِينَ
Dájúdájú Fir‘aon ṣègbéraga lórí ilẹ̀. Ó ṣe àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ìjọ-ìjọ; Ó ń sọ igun kan nínú wọn di ọ̀lẹ, ó ń pa àwọn ọmọkùnrin wọn, ó sì ń dá àwọn obìnrin wọn sí. Dájúdájú ó wà nínú àwọn òbìlẹ̀jẹ́.
5 - Al-Qasas (The Stories) - 005
وَنُرِيدُ أَن نَّمُنَّ عَلَى ٱلَّذِينَ ٱسۡتُضۡعِفُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَنَجۡعَلَهُمۡ أَئِمَّةٗ وَنَجۡعَلَهُمُ ٱلۡوَٰرِثِينَ
A sì fẹ́ ṣèdẹ̀ra fún àwọn tí wọ́n sọ di ọ̀lẹ lórí ilẹ̀, A (fẹ́) ṣe wọ́n ní aṣíwájú. A sì (fẹ́) kí wọ́n jogún (ilẹ̀).
6 - Al-Qasas (The Stories) - 006
وَنُمَكِّنَ لَهُمۡ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَنُرِيَ فِرۡعَوۡنَ وَهَٰمَٰنَ وَجُنُودَهُمَا مِنۡهُم مَّا كَانُواْ يَحۡذَرُونَ
A (fẹ́) gbà wọ́n láàyè lórí ilẹ̀. Láti ara wọn, A sì (fẹ́) fi han Fir‘aon àti Hāmọ̄n pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun àwọn méjèèjì ohun tí wọ́n ń ṣọ́ra fún lára wọn.
7 - Al-Qasas (The Stories) - 007
وَأَوۡحَيۡنَآ إِلَىٰٓ أُمِّ مُوسَىٰٓ أَنۡ أَرۡضِعِيهِۖ فَإِذَا خِفۡتِ عَلَيۡهِ فَأَلۡقِيهِ فِي ٱلۡيَمِّ وَلَا تَخَافِي وَلَا تَحۡزَنِيٓۖ إِنَّا رَآدُّوهُ إِلَيۡكِ وَجَاعِلُوهُ مِنَ ٱلۡمُرۡسَلِينَ
A sì ránṣẹ́ sí ìyá (Ànábì) Mūsā pé: “Fún un ní ọmú mu. Tí o bá sì ń páyà lórí rẹ̀, jù ú sínú odò. Má ṣe bẹ̀rù. Má sì ṣe banújẹ́. Dájúdájú Àwa máa dá a padà sí ọ̀dọ̀ rẹ. A ó sì ṣe é ní ara àwọn Òjíṣẹ́.”
8 - Al-Qasas (The Stories) - 008
فَٱلۡتَقَطَهُۥٓ ءَالُ فِرۡعَوۡنَ لِيَكُونَ لَهُمۡ عَدُوّٗا وَحَزَنًاۗ إِنَّ فِرۡعَوۡنَ وَهَٰمَٰنَ وَجُنُودَهُمَا كَانُواْ خَٰطِـِٔينَ
Nígbà náà, àwọn ènìyàn Fir‘aon rí i he nítorí kí ó lè jẹ́ ọ̀tá àti ìbànújẹ́ fún wọn. Dájúdájú Fir‘aon, Hāmọ̄n àti àwọn ọmọ ogun àwọn méjèèjì, wọ́n jẹ́ aláṣìṣe.
9 - Al-Qasas (The Stories) - 009
وَقَالَتِ ٱمۡرَأَتُ فِرۡعَوۡنَ قُرَّتُ عَيۡنٖ لِّي وَلَكَۖ لَا تَقۡتُلُوهُ عَسَىٰٓ أَن يَنفَعَنَآ أَوۡ نَتَّخِذَهُۥ وَلَدٗا وَهُمۡ لَا يَشۡعُرُونَ
Ìyàwó Fir‘aon wí pé: “Ìtutù-ojú ni (ọmọ yìí) fún èmi àti ìwọ. Ẹ má ṣe pa á. Ó lè jẹ́ pé ó máa ṣe wá ní àǹfààní tàbí kí a fi ṣe ọmọ.” Wọn kò sì fura.
10 - Al-Qasas (The Stories) - 010
وَأَصۡبَحَ فُؤَادُ أُمِّ مُوسَىٰ فَٰرِغًاۖ إِن كَادَتۡ لَتُبۡدِي بِهِۦ لَوۡلَآ أَن رَّبَطۡنَا عَلَىٰ قَلۡبِهَا لِتَكُونَ مِنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ
Ọkàn ìyá (Ànábì) Mūsā pami (lórí ọ̀rọ̀ Mūsā, kò sì rí n̄ǹkan mìíràn rò mọ́ tayọ rẹ̀) ó kúkú fẹ́ẹ̀ ṣàfi hàn rẹ̀ (pé ọmọ òun ni nígbà tí wọ́n pè é dé ọ̀dọ̀ Fir‘aon) tí kò bá jẹ́ pé A kì í lọ́kàn nítorí kí ó lè wà nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
11 - Al-Qasas (The Stories) - 011
وَقَالَتۡ لِأُخۡتِهِۦ قُصِّيهِۖ فَبَصُرَتۡ بِهِۦ عَن جُنُبٖ وَهُمۡ لَا يَشۡعُرُونَ
Ó sì sọ fún arábìnrin rẹ̀ pé: “Tọ ipa rẹ̀ lọ.” Ó sì ń wò ó láti ibi tó jìnnà. Wọn kò sì fura (sí i).
12 - Al-Qasas (The Stories) - 012
۞وَحَرَّمۡنَا عَلَيۡهِ ٱلۡمَرَاضِعَ مِن قَبۡلُ فَقَالَتۡ هَلۡ أَدُلُّكُمۡ عَلَىٰٓ أَهۡلِ بَيۡتٖ يَكۡفُلُونَهُۥ لَكُمۡ وَهُمۡ لَهُۥ نَٰصِحُونَ
A kò sì jẹ́ kí ó mu ọyàn (mìíràn) ṣíwájú (tìyá rẹ̀.) (Arábìnrin rẹ̀ sì) wí pé: “Ṣé kí èmi júwe yín sí ará ilé kan tí ó máa gbà á tọ́ fún yín? Wọn yó sì jẹ́ olùtọ́jú rẹ̀.”
13 - Al-Qasas (The Stories) - 013
فَرَدَدۡنَٰهُ إِلَىٰٓ أُمِّهِۦ كَيۡ تَقَرَّ عَيۡنُهَا وَلَا تَحۡزَنَ وَلِتَعۡلَمَ أَنَّ وَعۡدَ ٱللَّهِ حَقّٞ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَهُمۡ لَا يَعۡلَمُونَ
A sì dá a padà sí ọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀ nítorí kí ojú rẹ̀ lè tutù (fún ìdùnnú) àti nítorí kí ó má baà banújẹ́. Àti pé nítorí kí ó lè mọ̀ pé dájúdájú àdéhùn Allāhu, òdodo ni, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.
14 - Al-Qasas (The Stories) - 014
وَلَمَّا بَلَغَ أَشُدَّهُۥ وَٱسۡتَوَىٰٓ ءَاتَيۡنَٰهُ حُكۡمٗا وَعِلۡمٗاۚ وَكَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُحۡسِنِينَ
Nígbà tí ó dàgbà dáadáa, tí ó di géńdé, A fún un ní ọgbọ́n àti ìmọ̀. Báyẹn ni A ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
15 - Al-Qasas (The Stories) - 015
وَدَخَلَ ٱلۡمَدِينَةَ عَلَىٰ حِينِ غَفۡلَةٖ مِّنۡ أَهۡلِهَا فَوَجَدَ فِيهَا رَجُلَيۡنِ يَقۡتَتِلَانِ هَٰذَا مِن شِيعَتِهِۦ وَهَٰذَا مِنۡ عَدُوِّهِۦۖ فَٱسۡتَغَٰثَهُ ٱلَّذِي مِن شِيعَتِهِۦ عَلَى ٱلَّذِي مِنۡ عَدُوِّهِۦ فَوَكَزَهُۥ مُوسَىٰ فَقَضَىٰ عَلَيۡهِۖ قَالَ هَٰذَا مِنۡ عَمَلِ ٱلشَّيۡطَٰنِۖ إِنَّهُۥ عَدُوّٞ مُّضِلّٞ مُّبِينٞ
Ó wọ inú ìlú nígbà tí àwọn ará ìlú ti gbàgbé (nípa ọ̀rọ̀ rẹ̀).[1] Ó rí àwọn ọkùnrin méjì kan tí wọ́n ń bara wọn jà. Èyí wá láti inú ìran rẹ̀. Èyí sì wá láti (inú ìran) ọ̀tá rẹ̀. Èyí tí ó wá láti inú ìran rẹ̀ wá ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ lórí èyí tí ó wá láti (inú ìran) ọ̀tá rẹ̀. Mūsā kàn án ní ẹ̀ṣẹ́. Ó sì pa á. Ó sọ pé: “Èyí wà nínú iṣẹ́ aṣ-ṣaetọ̄n. Dájúdájú (aṣ-ṣaetọ̄n) ni ọ̀tá aṣini-lọ́nà pọ́nńbélé.”
1. Ó ṣẹ̀ ní ààfin, ó sì yẹra nínú ilé fún Fir‘aon. Ó wá padà wọ inú ìlú lẹ́yìn ìgbà tí ọ̀rọ̀ náà ti kúregbé kúregbè.
16 - Al-Qasas (The Stories) - 016
قَالَ رَبِّ إِنِّي ظَلَمۡتُ نَفۡسِي فَٱغۡفِرۡ لِي فَغَفَرَ لَهُۥٓۚ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلۡغَفُورُ ٱلرَّحِيمُ
Ó sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú èmi ti ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara mi. Nítorí náà, foríjìn mí.” Ó sì foríjìn ín. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
17 - Al-Qasas (The Stories) - 017
قَالَ رَبِّ بِمَآ أَنۡعَمۡتَ عَلَيَّ فَلَنۡ أَكُونَ ظَهِيرٗا لِّلۡمُجۡرِمِينَ
Ó sọ pé: “Olúwa mi, fún wí pé O ti ṣe ìkẹ́ fún mi, èmi kò níí jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.”
18 - Al-Qasas (The Stories) - 018
فَأَصۡبَحَ فِي ٱلۡمَدِينَةِ خَآئِفٗا يَتَرَقَّبُ فَإِذَا ٱلَّذِي ٱسۡتَنصَرَهُۥ بِٱلۡأَمۡسِ يَسۡتَصۡرِخُهُۥۚ قَالَ لَهُۥ مُوسَىٰٓ إِنَّكَ لَغَوِيّٞ مُّبِينٞ
Nítorí náà, ó di ẹni tó ń bẹ̀rù nínú ìlú, ó sì ń retí (ẹ̀hónú ìran Fir‘aon). Nígbà náà ni ẹni tí ó wá ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ ní àná tún ń lọgun rẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ rẹ̀. Mūsā sọ fún un pé: “Dájúdájú ìwọ ni olùṣìnà pọ́nńbélé.”
19 - Al-Qasas (The Stories) - 019
فَلَمَّآ أَنۡ أَرَادَ أَن يَبۡطِشَ بِٱلَّذِي هُوَ عَدُوّٞ لَّهُمَا قَالَ يَٰمُوسَىٰٓ أَتُرِيدُ أَن تَقۡتُلَنِي كَمَا قَتَلۡتَ نَفۡسَۢا بِٱلۡأَمۡسِۖ إِن تُرِيدُ إِلَّآ أَن تَكُونَ جَبَّارٗا فِي ٱلۡأَرۡضِ وَمَا تُرِيدُ أَن تَكُونَ مِنَ ٱلۡمُصۡلِحِينَ
Àmọ́ nígbà tí ó fẹ́ gbá ẹni tí ó jẹ́ ọ̀tá fún àwọn méjèèjì mú, ẹni náà wí pé: “Mūsā, ṣé o fẹ́ pa mí bí ó ṣe pa ẹnì kan ní àná? O ò gbèrò kan tayọ kí o jẹ́ aláìlójú-àánú lórí ilẹ̀; o ò sì gbèrò láti wà nínú àwọn alátùn-únṣe.”
20 - Al-Qasas (The Stories) - 020
وَجَآءَ رَجُلٞ مِّنۡ أَقۡصَا ٱلۡمَدِينَةِ يَسۡعَىٰ قَالَ يَٰمُوسَىٰٓ إِنَّ ٱلۡمَلَأَ يَأۡتَمِرُونَ بِكَ لِيَقۡتُلُوكَ فَٱخۡرُجۡ إِنِّي لَكَ مِنَ ٱلنَّـٰصِحِينَ
Ọkùnrin kan sáré dé láti òpin ìlú náà, ó wí pé: “Mūsā, dájúdájú àwọn ìjòyè ń dá ìmọ̀ràn lórí rẹ láti pa ọ́. Nítorí náà, jáde (kúrò nínú ìlú), dájúdájú èmi wà nínú àwọn onímọ̀ràn rere fún ọ.”
21 - Al-Qasas (The Stories) - 021
فَخَرَجَ مِنۡهَا خَآئِفٗا يَتَرَقَّبُۖ قَالَ رَبِّ نَجِّنِي مِنَ ٱلۡقَوۡمِ ٱلظَّـٰلِمِينَ
Ó sì jáde kúrò nínú (ìlú) pẹ̀lú ìpáyà, tí ó ń retí (ẹ̀hónú wọn), ó sì sọ pé: “Olúwa mi, là mí lọ́wọ́ ìjọ alábòsí.”
22 - Al-Qasas (The Stories) - 022
وَلَمَّا تَوَجَّهَ تِلۡقَآءَ مَدۡيَنَ قَالَ عَسَىٰ رَبِّيٓ أَن يَهۡدِيَنِي سَوَآءَ ٱلسَّبِيلِ
Nígbà tí ó sì dojú kọ ọ̀kánkán ìlú Mọdyan, ó sọ pé: “Ó súnmọ́ kí Olúwa mi fọ̀nà tààrà (sí ìlú Mọdyan) mọ̀ mí.”
23 - Al-Qasas (The Stories) - 023
وَلَمَّا وَرَدَ مَآءَ مَدۡيَنَ وَجَدَ عَلَيۡهِ أُمَّةٗ مِّنَ ٱلنَّاسِ يَسۡقُونَ وَوَجَدَ مِن دُونِهِمُ ٱمۡرَأَتَيۡنِ تَذُودَانِۖ قَالَ مَا خَطۡبُكُمَاۖ قَالَتَا لَا نَسۡقِي حَتَّىٰ يُصۡدِرَ ٱلرِّعَآءُۖ وَأَبُونَا شَيۡخٞ كَبِيرٞ
Nígbà tí ó dé ibi (kànǹga) omi (ìlú) Mọdyan, ó bá ìjọ ènìyàn kan níbẹ̀ tí wọ́n ń fún àwọn ẹran-ọ̀sìn wọn ní omi mu. Lẹ́yìn wọn, ó tún rí àwọn obìnrin méjì kan tí wọ́n ń fà sẹ́yìn (pẹ̀lú ẹran-ọ̀sìn wọn). Ó sọ pé: “Kí l’ó ṣe ẹ̀yin méjèèjì?” Wọ́n sọ pé: “A kò lè fún àwọn ẹran-ọ̀sìn wa ní omi mu títí àwọn adaran bá tó kó àwọn ẹran-ọ̀sìn wọn lọ. Àgbàlágbà arúgbó sì ni bàbá wa.”
24 - Al-Qasas (The Stories) - 024
فَسَقَىٰ لَهُمَا ثُمَّ تَوَلَّىٰٓ إِلَى ٱلظِّلِّ فَقَالَ رَبِّ إِنِّي لِمَآ أَنزَلۡتَ إِلَيَّ مِنۡ خَيۡرٖ فَقِيرٞ
Ó sì bá wọn fún (ẹran-ọ̀sìn) wọn ní omi mu. Lẹ́yìn náà, ó padà síbi ibòji, ó sì sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú èmi bùkátà sí ohun tí O bá sọ̀kalẹ̀ fún mi nínú oore.”
25 - Al-Qasas (The Stories) - 025
فَجَآءَتۡهُ إِحۡدَىٰهُمَا تَمۡشِي عَلَى ٱسۡتِحۡيَآءٖ قَالَتۡ إِنَّ أَبِي يَدۡعُوكَ لِيَجۡزِيَكَ أَجۡرَ مَا سَقَيۡتَ لَنَاۚ فَلَمَّا جَآءَهُۥ وَقَصَّ عَلَيۡهِ ٱلۡقَصَصَ قَالَ لَا تَخَفۡۖ نَجَوۡتَ مِنَ ٱلۡقَوۡمِ ٱلظَّـٰلِمِينَ
Ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì wá bá a, ó sì ń rìn pẹ̀lú ìtìjú, ó sọ pé: “Dájúdájú bàbá mi ń pè ọ́ nítorí kí ó lè san ọ́ ní ẹ̀san omi tí o fún (àwọn ẹran-ọ̀sìn) wa mu.” Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sọ ìtàn (ara rẹ̀) fún un. (Bàbá náà) sọ pé: “Má bẹ̀rù. O ti là lọ́wọ́ ìjọ alábòsí.”
26 - Al-Qasas (The Stories) - 026
قَالَتۡ إِحۡدَىٰهُمَا يَـٰٓأَبَتِ ٱسۡتَـٔۡجِرۡهُۖ إِنَّ خَيۡرَ مَنِ ٱسۡتَـٔۡجَرۡتَ ٱلۡقَوِيُّ ٱلۡأَمِينُ
Ọ̀kan nínú (àwọn ọmọbìnrin) méjèèjì sọ pé: “Bàbá mi o, gbà á síṣẹ́. Dájúdájú ẹni tó dára jùlọ tí o lè gbà síṣẹ́ ni alágbára, olùfọkàntán.”
27 - Al-Qasas (The Stories) - 027
قَالَ إِنِّيٓ أُرِيدُ أَنۡ أُنكِحَكَ إِحۡدَى ٱبۡنَتَيَّ هَٰتَيۡنِ عَلَىٰٓ أَن تَأۡجُرَنِي ثَمَٰنِيَ حِجَجٖۖ فَإِنۡ أَتۡمَمۡتَ عَشۡرٗا فَمِنۡ عِندِكَۖ وَمَآ أُرِيدُ أَنۡ أَشُقَّ عَلَيۡكَۚ سَتَجِدُنِيٓ إِن شَآءَ ٱللَّهُ مِنَ ٱلصَّـٰلِحِينَ
Ó sọ pé: “Dájúdájú mo fẹ́ fi ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin mi méjèèjì wọ̀nyí fún ọ ní aya lórí (àdéhùn) pé o máa bá mi ṣiṣẹ́ fún ọdún mẹ́jọ. Ṣùgbọ́n tí o bá ṣe é pé ọdún mẹ́wàá, láti ọ̀dọ̀ rẹ nìyẹn. Èmi kò sì fẹ́ kó ìnira bá ọ. Tí Allāhu bá fẹ́, o máa rí mi pé mo wà nínú àwọn ẹni rere.”
28 - Al-Qasas (The Stories) - 028
قَالَ ذَٰلِكَ بَيۡنِي وَبَيۡنَكَۖ أَيَّمَا ٱلۡأَجَلَيۡنِ قَضَيۡتُ فَلَا عُدۡوَٰنَ عَلَيَّۖ وَٱللَّهُ عَلَىٰ مَا نَقُولُ وَكِيلٞ
(Mūsā) sọ pé: “(Àdéhùn) yìí wà láààrin èmi àti ìwọ. Èyíkéyìí tí mo bá mú ṣẹ nínú àdéhùn méjèèjì náà, ìwọ kò gbọdọ̀ ṣàbòsí sí mi. Allāhu sì ni Ẹlẹ́rìí lórí ohun tí à ń sọ (yìí).”
29 - Al-Qasas (The Stories) - 029
۞فَلَمَّا قَضَىٰ مُوسَى ٱلۡأَجَلَ وَسَارَ بِأَهۡلِهِۦٓ ءَانَسَ مِن جَانِبِ ٱلطُّورِ نَارٗاۖ قَالَ لِأَهۡلِهِ ٱمۡكُثُوٓاْ إِنِّيٓ ءَانَسۡتُ نَارٗا لَّعَلِّيٓ ءَاتِيكُم مِّنۡهَا بِخَبَرٍ أَوۡ جَذۡوَةٖ مِّنَ ٱلنَّارِ لَعَلَّكُمۡ تَصۡطَلُونَ
Nígbà tí Mūsā parí àkókò náà, ó mú ará ilé rẹ̀ rin (ìrìn-àjò). Ó sì rí iná kan ní ẹ̀bá àpáta. Ó sọ fún ará ilé rẹ̀ pé: “Ẹ dúró (síbí ná). Èmi rí iná kan. Ó ṣe é ṣe kí n̄g mú ìró kan wá ba yín láti ibẹ̀ tàbí (kí n̄g mú) ògúnná kan wá nítorí kí ẹ lè rí ohun yẹ́ná.”
30 - Al-Qasas (The Stories) - 030
فَلَمَّآ أَتَىٰهَا نُودِيَ مِن شَٰطِيِٕ ٱلۡوَادِ ٱلۡأَيۡمَنِ فِي ٱلۡبُقۡعَةِ ٱلۡمُبَٰرَكَةِ مِنَ ٱلشَّجَرَةِ أَن يَٰمُوسَىٰٓ إِنِّيٓ أَنَا ٱللَّهُ رَبُّ ٱلۡعَٰلَمِينَ
Nígbà tí ó dé ibẹ̀, A pè é níbi etí àfonífojì ní ọwọ́ ọ̀tún (rẹ̀) ní àyè ìbùkún láti ibi igi náà. (A sọ pé): “Mūsā, dájúdájú Èmi (tí Mò ń bá ọ sọ̀rọ̀), Èmi ni Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
31 - Al-Qasas (The Stories) - 031
وَأَنۡ أَلۡقِ عَصَاكَۚ فَلَمَّا رَءَاهَا تَهۡتَزُّ كَأَنَّهَا جَآنّٞ وَلَّىٰ مُدۡبِرٗا وَلَمۡ يُعَقِّبۡۚ يَٰمُوسَىٰٓ أَقۡبِلۡ وَلَا تَخَفۡۖ إِنَّكَ مِنَ ٱلۡأٓمِنِينَ
Ju ọ̀pá rẹ sílẹ̀.” (Ó sì jù ú sílẹ̀). Nígbà tí ó rí i tó ń mira bí ẹni pé ejò ni, Mūsā pẹ̀yìndà, ó ń sá lọ́, kò sì padà sẹ́yìn. (Allāhu sọ pé): “Mūsā, máa bọ̀ padà, má sì ṣe páyà. Dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn olùfàyàbalẹ̀.
32 - Al-Qasas (The Stories) - 032
ٱسۡلُكۡ يَدَكَ فِي جَيۡبِكَ تَخۡرُجۡ بَيۡضَآءَ مِنۡ غَيۡرِ سُوٓءٖ وَٱضۡمُمۡ إِلَيۡكَ جَنَاحَكَ مِنَ ٱلرَّهۡبِۖ فَذَٰنِكَ بُرۡهَٰنَانِ مِن رَّبِّكَ إِلَىٰ فِرۡعَوۡنَ وَمَلَإِيْهِۦٓۚ إِنَّهُمۡ كَانُواْ قَوۡمٗا فَٰسِقِينَ
Ti ọwọ́ rẹ bọ igbá-àyà ẹ̀wù rẹ, ó sì máa jáde ní funfun tí kì í ṣe ti aburú. Pa ọwọ́ rẹ mọ́ra níbi ẹ̀rù.[1] Nítorí náà, àwọn ẹ̀rí méjì nìwọ̀nyí láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ sí Fir‘aon àti àwọn ìjòyè rẹ̀. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.”
1. Ìyẹn ni pé, tí ọpá rẹ bá yí padà, tó di ejò níwájú àwọn ọ̀tá rẹ, tí ẹ̀rù sì ń ba ìwọ náà, pa ọwọ́ rẹ mọ́ra láti fi yọ ẹ̀rù náà kúrò nínú ọkàn rẹ.
33 - Al-Qasas (The Stories) - 033
قَالَ رَبِّ إِنِّي قَتَلۡتُ مِنۡهُمۡ نَفۡسٗا فَأَخَافُ أَن يَقۡتُلُونِ
(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú èmi pa ẹnì kan nínú wọn. Nítorí náà, mò ń bẹ̀rù pé wọ́n máa pa mí.
34 - Al-Qasas (The Stories) - 034
وَأَخِي هَٰرُونُ هُوَ أَفۡصَحُ مِنِّي لِسَانٗا فَأَرۡسِلۡهُ مَعِيَ رِدۡءٗا يُصَدِّقُنِيٓۖ إِنِّيٓ أَخَافُ أَن يُكَذِّبُونِ
Àti pé arákùnrin mi Hārūn, ó dá láhọ́n jù mí lọ. Nítorí náà, rán an níṣẹ́ pẹ̀lú mi, kí ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ tí yóò máa jẹ́rìí sí òdodo ọ̀rọ̀ mi. Dájúdájú èmi ń bẹ̀rù pé wọ́n máa pè mí ní òpùrọ́.”
35 - Al-Qasas (The Stories) - 035
قَالَ سَنَشُدُّ عَضُدَكَ بِأَخِيكَ وَنَجۡعَلُ لَكُمَا سُلۡطَٰنٗا فَلَا يَصِلُونَ إِلَيۡكُمَا بِـَٔايَٰتِنَآۚ أَنتُمَا وَمَنِ ٱتَّبَعَكُمَا ٱلۡغَٰلِبُونَ
(Allāhu) sọ pé: “A máa fi arákùnrin rẹ kún ọ lọ́wọ́. A sì máa fún ẹ̀yin méjèèjì ní agbára, wọn kò níí lè dé ọ̀dọ̀ ẹ̀yin méjèèjì. Pẹ̀lú àwọn àmì Wa, ẹ̀yin méjèèjì àti àwọn tó bá tẹ̀lé ẹ̀yin méjèèjì l’ó máa borí.”
36 - Al-Qasas (The Stories) - 036
فَلَمَّا جَآءَهُم مُّوسَىٰ بِـَٔايَٰتِنَا بَيِّنَٰتٖ قَالُواْ مَا هَٰذَآ إِلَّا سِحۡرٞ مُّفۡتَرٗى وَمَا سَمِعۡنَا بِهَٰذَا فِيٓ ءَابَآئِنَا ٱلۡأَوَّلِينَ
Nígbà tí (Ànábì) Mūsā dé bá wọn pẹ̀lú àwọn àmì Wa tó yanjú, wọ́n wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe idán àdáhun. A kò gbọ́ èyí (rí) láààrin àwọn bàbá wa, àwọn ẹni àkọ́kọ́.”
37 - Al-Qasas (The Stories) - 037
وَقَالَ مُوسَىٰ رَبِّيٓ أَعۡلَمُ بِمَن جَآءَ بِٱلۡهُدَىٰ مِنۡ عِندِهِۦ وَمَن تَكُونُ لَهُۥ عَٰقِبَةُ ٱلدَّارِۚ إِنَّهُۥ لَا يُفۡلِحُ ٱلظَّـٰلِمُونَ
(Ànábì) Mūsā sì sọ pé: “Olúwa mi nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tí ó mú ìmọ̀nà wá láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ àti ẹni tí àtubọ̀tán ilé (ìkẹ́) máa jẹ́ tirẹ̀. Dájúdájú àwọn alábòsí kò níí jèrè.”
38 - Al-Qasas (The Stories) - 038
وَقَالَ فِرۡعَوۡنُ يَـٰٓأَيُّهَا ٱلۡمَلَأُ مَا عَلِمۡتُ لَكُم مِّنۡ إِلَٰهٍ غَيۡرِي فَأَوۡقِدۡ لِي يَٰهَٰمَٰنُ عَلَى ٱلطِّينِ فَٱجۡعَل لِّي صَرۡحٗا لَّعَلِّيٓ أَطَّلِعُ إِلَىٰٓ إِلَٰهِ مُوسَىٰ وَإِنِّي لَأَظُنُّهُۥ مِنَ ٱلۡكَٰذِبِينَ
Fir‘aon wí pé: “Ẹ̀yin ìjòyè, èmi kò mọ̀ pé ọlọ́hun kan tún wà lẹ́yìn mi fún yín! Nítorí náà, Hāmọ̄n, dá iná fún mi, kí o fi mọ amọ̀, kí o sì kọ́ ilé gíga kan fún mi nítorí kí èmi lè yọjú wo Ọlọ́hun Mūsā. (Nítorí pé) dájúdájú mò ń rò ó sí ara àwọn òpùrọ́.”
39 - Al-Qasas (The Stories) - 039
وَٱسۡتَكۡبَرَ هُوَ وَجُنُودُهُۥ فِي ٱلۡأَرۡضِ بِغَيۡرِ ٱلۡحَقِّ وَظَنُّوٓاْ أَنَّهُمۡ إِلَيۡنَا لَا يُرۡجَعُونَ
Òun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì ṣègbéraga lórí ilẹ̀ láì lẹ́tọ̀ọ́. Wọ́n sì rò pé dájúdájú A ò níí dá wọn padà sí ọ̀dọ̀ Wa.
40 - Al-Qasas (The Stories) - 040
فَأَخَذۡنَٰهُ وَجُنُودَهُۥ فَنَبَذۡنَٰهُمۡ فِي ٱلۡيَمِّۖ فَٱنظُرۡ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلظَّـٰلِمِينَ
Nítorí náà, A gbá òun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ mú; A jù wọ́n sínú agbami odò. Wo bí àtubọ̀tán àwọn alábòsí ti rí.
41 - Al-Qasas (The Stories) - 041
وَجَعَلۡنَٰهُمۡ أَئِمَّةٗ يَدۡعُونَ إِلَى ٱلنَّارِۖ وَيَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ لَا يُنصَرُونَ
A ṣe wọ́n ní aṣíwájú tó ń pèpè sínú Iná. Tí ó bá sì di Ọjọ́ Àjíǹde, A ò níí ràn wọ́n lọ́wọ́.
42 - Al-Qasas (The Stories) - 042
وَأَتۡبَعۡنَٰهُمۡ فِي هَٰذِهِ ٱلدُّنۡيَا لَعۡنَةٗۖ وَيَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ هُم مِّنَ ٱلۡمَقۡبُوحِينَ
Àti pé A fi ègún tẹ̀lé wọn ní ilé ayé yìí. Ní Ọjọ́ Àjíǹde, wọn yó sì wà nínú àwọn ẹni ìparun.
43 - Al-Qasas (The Stories) - 043
وَلَقَدۡ ءَاتَيۡنَا مُوسَى ٱلۡكِتَٰبَ مِنۢ بَعۡدِ مَآ أَهۡلَكۡنَا ٱلۡقُرُونَ ٱلۡأُولَىٰ بَصَآئِرَ لِلنَّاسِ وَهُدٗى وَرَحۡمَةٗ لَّعَلَّهُمۡ يَتَذَكَّرُونَ
Dájúdájú A ti fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà lẹ́yìn ìgbà tí A ti pa àwọn ìjọ àkọ́kọ́ rẹ́. (Tírà náà jẹ́) ìmọ̀ àmọ̀dájú àti ẹ̀rí fún àwọn ènìyàn, ìmọ̀nà àti ìkẹ́ nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí.
44 - Al-Qasas (The Stories) - 044
وَمَا كُنتَ بِجَانِبِ ٱلۡغَرۡبِيِّ إِذۡ قَضَيۡنَآ إِلَىٰ مُوسَى ٱلۡأَمۡرَ وَمَا كُنتَ مِنَ ٱلشَّـٰهِدِينَ
Ìwọ kò sí ní ẹ̀bá ìwọ̀-òòrùn nígbà tí A fi ọ̀rọ̀ náà ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā. Àti pé ìwọ kò sí nínú àwọn tó wà níbẹ̀.
45 - Al-Qasas (The Stories) - 045
وَلَٰكِنَّآ أَنشَأۡنَا قُرُونٗا فَتَطَاوَلَ عَلَيۡهِمُ ٱلۡعُمُرُۚ وَمَا كُنتَ ثَاوِيٗا فِيٓ أَهۡلِ مَدۡيَنَ تَتۡلُواْ عَلَيۡهِمۡ ءَايَٰتِنَا وَلَٰكِنَّا كُنَّا مُرۡسِلِينَ
Ṣùgbọ́n A ṣẹ̀dá àwọn ìran kan tí ẹ̀mí wọn gùn. O ò kúkú gbé láààrin ará ìlú Mọdyan, tí ò ń ké àwọn āyah Wa fún wọn, ṣùgbọ́n Àwa l’à ń rán àwọn Òjíṣẹ́ níṣẹ́.
46 - Al-Qasas (The Stories) - 046
وَمَا كُنتَ بِجَانِبِ ٱلطُّورِ إِذۡ نَادَيۡنَا وَلَٰكِن رَّحۡمَةٗ مِّن رَّبِّكَ لِتُنذِرَ قَوۡمٗا مَّآ أَتَىٰهُم مِّن نَّذِيرٖ مِّن قَبۡلِكَ لَعَلَّهُمۡ يَتَذَكَّرُونَ
Ìwọ kò sì sí ní ẹ̀bá àpáta náà, nígbà tí A pèpè, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ nítorí kí o lè ṣèkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn tí olùkìlọ̀ kan kò wá bá rí ṣíwájú rẹ nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí.[1]
1. Ànábì ’Ibrọ̄hīm - kí ọlà Allāhu máa bá a - àti àkọ́bí rẹ̀ Ànábì ’Ismā‘īl - kí ọlà Allāhu máa bá a - dé ìlú Mọkkah ṣíwájú Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, àmọ́ kì í ṣe pé Allāhu rán wọn níṣẹ́ sí ará ìlú Mọkkah.
47 - Al-Qasas (The Stories) - 047
وَلَوۡلَآ أَن تُصِيبَهُم مُّصِيبَةُۢ بِمَا قَدَّمَتۡ أَيۡدِيهِمۡ فَيَقُولُواْ رَبَّنَا لَوۡلَآ أَرۡسَلۡتَ إِلَيۡنَا رَسُولٗا فَنَتَّبِعَ ءَايَٰتِكَ وَنَكُونَ مِنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ
Tí ó bá jẹ́ pé àdánwò kan kàn wọ́n nítorí ohun tí wọ́n fi ọwọ́ wọn tì síwájú, wọn ìbá wí pé: “Olúwa wa, ti Ó bá jẹ́ pé O rán Òjíṣẹ́ kan sí wa ni, a à bá tẹ̀lé àwọn āyah Rẹ, a à bá sì wà nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.”
48 - Al-Qasas (The Stories) - 048
فَلَمَّا جَآءَهُمُ ٱلۡحَقُّ مِنۡ عِندِنَا قَالُواْ لَوۡلَآ أُوتِيَ مِثۡلَ مَآ أُوتِيَ مُوسَىٰٓۚ أَوَلَمۡ يَكۡفُرُواْ بِمَآ أُوتِيَ مُوسَىٰ مِن قَبۡلُۖ قَالُواْ سِحۡرَانِ تَظَٰهَرَا وَقَالُوٓاْ إِنَّا بِكُلّٖ كَٰفِرُونَ
Ṣùgbọ́n nígbà tí òdodo dé bá wọn láti ọ̀dọ̀ Wa, wọ́n wí pé: “Kí ni kò jẹ́ kí Wọ́n fún un ní irú ohun tí Wọ́n fún (Ànábì) Mūsā?” Ṣé wọn kò sì ṣàì gbàgbọ́ nínú ohun tí A fún (Ànábì) Mūsā ṣíwájú bí? Wọ́n wí pé: “Òpìdán méjì tó ń ranra wọn lọ́wọ́ (ni wọ́n).” Wọ́n sì tún wí pé: “Dájúdájú àwa jẹ́ aláìgbàgbọ́ nínú ìkọ̀ọ̀kan (wọn).”
49 - Al-Qasas (The Stories) - 049
قُلۡ فَأۡتُواْ بِكِتَٰبٖ مِّنۡ عِندِ ٱللَّهِ هُوَ أَهۡدَىٰ مِنۡهُمَآ أَتَّبِعۡهُ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ
Sọ pé: “Nítorí náà, ẹ mú tírà kan wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu, tó ń tọ́ ni sí ọ̀nà ju ti àwọn méjèèjì lọ, mo sì máa tẹ̀lé e, tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”
50 - Al-Qasas (The Stories) - 050
فَإِن لَّمۡ يَسۡتَجِيبُواْ لَكَ فَٱعۡلَمۡ أَنَّمَا يَتَّبِعُونَ أَهۡوَآءَهُمۡۚ وَمَنۡ أَضَلُّ مِمَّنِ ٱتَّبَعَ هَوَىٰهُ بِغَيۡرِ هُدٗى مِّنَ ٱللَّهِۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَهۡدِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلظَّـٰلِمِينَ
Tí wọn kò bá jẹ́pè rẹ, mọ̀ pé wọ́n kàn ń tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn ni. Ta l’ó sì ṣìnà ju ẹni tó tẹ̀lé ìfẹ́-inú rẹ̀, láì sí ìmọ̀nà (fún un) láti ọ̀dọ̀ Allāhu! Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí.
51 - Al-Qasas (The Stories) - 051
۞وَلَقَدۡ وَصَّلۡنَا لَهُمُ ٱلۡقَوۡلَ لَعَلَّهُمۡ يَتَذَكَّرُونَ
Àti pé dájúdájú A ti ṣe àlàyé ọ̀rọ̀ náà fún wọn nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí.
52 - Al-Qasas (The Stories) - 052
ٱلَّذِينَ ءَاتَيۡنَٰهُمُ ٱلۡكِتَٰبَ مِن قَبۡلِهِۦ هُم بِهِۦ يُؤۡمِنُونَ
Àwọn tí A fún ní Tírà ṣíwájú rẹ̀, wọ́n gbàgbọ́ nínú al-Ƙur’ān.
53 - Al-Qasas (The Stories) - 053
وَإِذَا يُتۡلَىٰ عَلَيۡهِمۡ قَالُوٓاْ ءَامَنَّا بِهِۦٓ إِنَّهُ ٱلۡحَقُّ مِن رَّبِّنَآ إِنَّا كُنَّا مِن قَبۡلِهِۦ مُسۡلِمِينَ
Àti pé nígbà tí wọ́n bá ń ké e fún wọn, wọ́n á sọ pé: “A gbà á gbọ́. Dájúdájú òdodo ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa wa. Dájúdájú àwa ti jẹ́ mùsùlùmí ṣíwájú rẹ̀.”[1]
1. Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni àwọn tí wọ́n tì wà ní ipò mùsùlùmí lórí sunnah Ànábì ‘Īsā - kí ọlà Allāhu máa bá a - , tí Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - tún dé bá wọn láyé, tí wọ́n sì gbà fún sunnah tirẹ̀ náà. Wọ́n sì di ọmọlẹ́yìn rẹ̀.
54 - Al-Qasas (The Stories) - 054
أُوْلَـٰٓئِكَ يُؤۡتَوۡنَ أَجۡرَهُم مَّرَّتَيۡنِ بِمَا صَبَرُواْ وَيَدۡرَءُونَ بِٱلۡحَسَنَةِ ٱلسَّيِّئَةَ وَمِمَّا رَزَقۡنَٰهُمۡ يُنفِقُونَ
Àwọn wọ̀nyẹn ni A máa fún wọn ní ẹ̀san wọn ní ẹ̀ẹ̀ mejì nítorí pé wọ́n ṣe sùúrù, wọ́n sì ń fi dáadáa ti àìdaa dànù. Àti pé wọ́n ń ná nínú ohun tí A pèsè fún wọn.
55 - Al-Qasas (The Stories) - 055
وَإِذَا سَمِعُواْ ٱللَّغۡوَ أَعۡرَضُواْ عَنۡهُ وَقَالُواْ لَنَآ أَعۡمَٰلُنَا وَلَكُمۡ أَعۡمَٰلُكُمۡ سَلَٰمٌ عَلَيۡكُمۡ لَا نَبۡتَغِي ٱلۡجَٰهِلِينَ
Àti pé nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ọ̀rọ̀ burúkú, wọ́n á ṣẹ́rí kúrò níbẹ̀, wọ́n á sì sọ pé: “Tiwa ni àwọn iṣẹ́ wa. Tiyín sì ni àwọn iṣẹ́ yín. Kí àlàáfíà máa ba yín. A kò wá àwọn aláìmọ̀kan (ní alábàáṣepọ̀).”
56 - Al-Qasas (The Stories) - 056
إِنَّكَ لَا تَهۡدِي مَنۡ أَحۡبَبۡتَ وَلَٰكِنَّ ٱللَّهَ يَهۡدِي مَن يَشَآءُۚ وَهُوَ أَعۡلَمُ بِٱلۡمُهۡتَدِينَ
Dájúdájú ìwọ kò lè fi ọ̀nà mọ ẹni tí o fẹ́ràn, ṣùgbọ́n Allāhu l’Ó ń fi ọ̀nà mọ ẹni tí Ó bá fẹ́.[1] Àti pé Ó nímọ̀ jùlọ nípa àwọn olùmọ̀nà.
1. “Hidāyah” túmọ̀ sí ìwọ̀nyí: (1) Ìfẹsẹ̀rinlẹ̀ nínú ẹ̀sìn ’Islām, ṣíṣí ọkàn ẹ̀dá payá fún gbígba ẹ̀sìn ’Islām, fífi al-Ƙur’ān àti sunnah ṣàlàyé ìmọ̀nà sí ọ̀nà tààrà ’Islām àti títọ́ka ènìyàn sí ibì kan tàbí fífi ojú-ọ̀nà kan mọ ènìyàn.
57 - Al-Qasas (The Stories) - 057
وَقَالُوٓاْ إِن نَّتَّبِعِ ٱلۡهُدَىٰ مَعَكَ نُتَخَطَّفۡ مِنۡ أَرۡضِنَآۚ أَوَلَمۡ نُمَكِّن لَّهُمۡ حَرَمًا ءَامِنٗا يُجۡبَىٰٓ إِلَيۡهِ ثَمَرَٰتُ كُلِّ شَيۡءٖ رِّزۡقٗا مِّن لَّدُنَّا وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَهُمۡ لَا يَعۡلَمُونَ
Wọ́n wí pé: “Tí a bá (fi lè) tẹ̀lé ìmọ̀nà pẹ̀lú rẹ, àwọn ọ̀ṣẹbọ yóò kó wa kúrò lórí ilẹ̀ wa.” Ṣé A ò fún wọn ní ibùgbé (tí ó jẹ́) àyè ọ̀wọ̀ ìfọ̀kànbalẹ̀, tí wọ́n sì ń kó àwọn èso gbogbo n̄ǹkan wá síbẹ̀, tí ó jẹ́ èsè láti ọ̀dọ̀ Wa? Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.
58 - Al-Qasas (The Stories) - 058
وَكَمۡ أَهۡلَكۡنَا مِن قَرۡيَةِۭ بَطِرَتۡ مَعِيشَتَهَاۖ فَتِلۡكَ مَسَٰكِنُهُمۡ لَمۡ تُسۡكَن مِّنۢ بَعۡدِهِمۡ إِلَّا قَلِيلٗاۖ وَكُنَّا نَحۡنُ ٱلۡوَٰرِثِينَ
Mélòó mélòó nínú ìlú tí A parẹ́, tí wọ́n yọ àyọ̀pọ̀rọ́ ayé-jíjẹ nínú ìlú. Ìwọ̀nyẹn ni àwọn ibùgbé wọn, tí A kò jẹ́ kí ẹnì kan kan gbé ibẹ̀ lẹ́yìn wọn bí kò ṣe fún ìgbà díẹ̀. Àwa sì jẹ́ Olùjogún.
59 - Al-Qasas (The Stories) - 059
وَمَا كَانَ رَبُّكَ مُهۡلِكَ ٱلۡقُرَىٰ حَتَّىٰ يَبۡعَثَ فِيٓ أُمِّهَا رَسُولٗا يَتۡلُواْ عَلَيۡهِمۡ ءَايَٰتِنَاۚ وَمَا كُنَّا مُهۡلِكِي ٱلۡقُرَىٰٓ إِلَّا وَأَهۡلُهَا ظَٰلِمُونَ
Olúwa rẹ kò sì níí pa àwọn ìlú run (ní àsìkò tìrẹ yìí) títí Ó fi máa gbé Òjíṣẹ́ kan dìde nínú Olú-ìlú-ayé (ìyẹn, ìlú Mọkkah, ẹni tí) yóò máa ké àwọn āyah Wa fún wọn. (Ó sì ti ṣe bẹ́ẹ̀.) A ò sì níí pa àwọn ìlú (yìí) run sẹ́ àfi kí àwọn ara ibẹ̀ jẹ́ alábòsí.
60 - Al-Qasas (The Stories) - 060
وَمَآ أُوتِيتُم مِّن شَيۡءٖ فَمَتَٰعُ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا وَزِينَتُهَاۚ وَمَا عِندَ ٱللَّهِ خَيۡرٞ وَأَبۡقَىٰٓۚ أَفَلَا تَعۡقِلُونَ
Kò sí ohun tí A fún yín bí kò ṣe nítorí ìgbádùn ayé àti ọ̀ṣọ́ rẹ̀. Ohun tó ń bẹ lọ́dọ̀ Allāhu lóore jùlọ, ó sì máa wà títí láéláé. Nítorí náà, ṣé ẹ kò níí ṣe làákàyè ni?
61 - Al-Qasas (The Stories) - 061
أَفَمَن وَعَدۡنَٰهُ وَعۡدًا حَسَنٗا فَهُوَ لَٰقِيهِ كَمَن مَّتَّعۡنَٰهُ مَتَٰعَ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا ثُمَّ هُوَ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ مِنَ ٱلۡمُحۡضَرِينَ
Ǹjẹ́ ẹni tí A bá ṣàdéhùn ní àdéhùn tó dára, tí ó sì máa pàdé rẹ̀, dà bí ẹni tí A fún ní ìgbádùn ìṣẹ̀mí ayé bí, lẹ́yìn náà ní Ọjọ́ Àjíǹde tí ó máa wà nínú àwọn tí wọn yóò mú wá (fún ìyà Iná)?
62 - Al-Qasas (The Stories) - 062
وَيَوۡمَ يُنَادِيهِمۡ فَيَقُولُ أَيۡنَ شُرَكَآءِيَ ٱلَّذِينَ كُنتُمۡ تَزۡعُمُونَ
(Rántí) ọjọ́ tí (Allāhu) yóò pè wọ́n, Ó sì máa sọ pé: “Níbo ni àwọn akẹgbẹ́ Mi tí ẹ̀ ń sọ nípa wọn láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́ wà?”
63 - Al-Qasas (The Stories) - 063
قَالَ ٱلَّذِينَ حَقَّ عَلَيۡهِمُ ٱلۡقَوۡلُ رَبَّنَا هَـٰٓؤُلَآءِ ٱلَّذِينَ أَغۡوَيۡنَآ أَغۡوَيۡنَٰهُمۡ كَمَا غَوَيۡنَاۖ تَبَرَّأۡنَآ إِلَيۡكَۖ مَا كَانُوٓاْ إِيَّانَا يَعۡبُدُونَ
Àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kò lé lórí wí pé: “Olúwa wa, àwọn wọ̀nyí tí a kó ṣìnà, a kó wọn ṣìnà gẹ́gẹ́ bí àwa náà ṣe ṣìnà. A yọwọ́ yọsẹ̀ (nínú ọ̀rọ̀ wọn) níwájú Rẹ (báyìí); kì í ṣe àwa ni wọ́n ń jọ́sìn fún.”
64 - Al-Qasas (The Stories) - 064
وَقِيلَ ٱدۡعُواْ شُرَكَآءَكُمۡ فَدَعَوۡهُمۡ فَلَمۡ يَسۡتَجِيبُواْ لَهُمۡ وَرَأَوُاْ ٱلۡعَذَابَۚ لَوۡ أَنَّهُمۡ كَانُواْ يَهۡتَدُونَ
A sọ (fún wọn) pé: “Ẹ pe àwọn òrìṣà yín.” Wọ́n sì pè wọ́n, ṣùgbọ́n wọn kò dá wọn lóhùn. Wọ́n ti rí Iná. Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú wọ́n jẹ́ olùmọ̀nà ni (ìyà ìbá tí jẹ wọ́n.)
65 - Al-Qasas (The Stories) - 065
وَيَوۡمَ يُنَادِيهِمۡ فَيَقُولُ مَاذَآ أَجَبۡتُمُ ٱلۡمُرۡسَلِينَ
(Rántí) ọjọ́ tí (Allāhu) yóò pè wọ́n, Ó sì máa sọ pé: “Kí ni ẹ fọ̀ ní èsì fún àwọn Òjíṣẹ́?”
66 - Al-Qasas (The Stories) - 066