Wọn sọ ìmísí kalẹ fun ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nígbà tí o pe ọmọ ogójì ọdún
Láti ọ̀dọ̀ Ibnu Abbaas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Wọn sọ ìmísí kalẹ fun ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nígbà tí o pe ọmọ ogójì ọdún, o lo ọdún mẹtala ni ìlú Makkah, lẹyin naa ni wọn pa a láṣẹ ki o ṣe hijra, o wa ṣe hijra lọ sí ìlú Madina…

