Dajudaju ẹmi mọ gbólóhùn kan, ti o ba le wi i ni, nkan ti nbi ninu yóò sakuro lọdọ rẹ "ti o ba le sọ pé: "mo wa iṣọ lọdọ Ọlọhun nipa aburu èṣù" (Satani), ibinu ti nbi náà yóò lọ
Lati ọdọ Sulaiman ọmọ Suradin - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ bayi pe: Mo wa lori ijoko pẹlu Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) nigbati awọn arakunrin meji nbu arawọn, ojú ọkan nínú àwọn mejeeji pọ́n kankan, bẹẹni iṣan parikẹ rẹ naa ntana jade, bayi ni Anọbi (ki ikẹ…

