O ti to fun ẹ ki o fi ọwọ rẹ mejeeji ṣe bayii» lẹyin naa ni o fi ọwọ rẹ mejeeji lu ilẹ ni ẹẹkan, lẹyin naa ni o fi osi pa ọtun, ati ẹyin ọwọ rẹ mejeeji ati oju rẹ
Lati ọdọ Ammār ọmọ Yāsir - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ran mi ni iṣẹ kan, ni mo ba ni janaba ti mi o si ri omi, ni mo ba po ara mọ erupẹ gẹgẹ bi ẹranko ṣe maa n po ara mọ ọn, lẹyin naa ni mo wa ba Anabi - ki ikẹ ati ọla…

