Alaye iwẹ latara janaba
Lati ọdọ Maymūna iya gbogbo mumini - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Mo gbe omi iwẹ fun Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - mo si fi aṣọ kan bo o, o wa da omi si ọwọ rẹ mejeeji, ti o si fọ wọn, lẹyin naa ni o fi ọwọ ọtun rẹ da omi si ọwọ osi, o si fọ abẹ rẹ, ni o wa…

