Dajudaju awọn eniyan ti wọn ba ti ri alabosi, ti wọn ko si gba a mu ni ọwọ rẹ mejeeji, o sunmọ ki Ọlọhun fi iya kan lati ọdọ Rẹ kari wọn
Lati ọdọ Abu Bakr- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo pe ẹyin eniyan, ẹ maa n ka aayah yìí: (Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ̀mí ara yín dọwọ́ yín. Ẹni tí ó ti ṣìnà kò lè kó ìnira ba yín nígbà tí ẹ bá ti mọ̀na), mo si gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-…

