Eyi tó lọ́lá jùlọ ninu awọn iranti Ọlọhun ni gbolohun: LAA ILAAHA ILLALLOOH, eyi tó sì lọ́lá jùlọ ninu awọn adura ni gbolohun: ALHAMDULILLAH
Lati ọdọ Jabir - ki Ọlọhun yọnu si i - ó sọ pé: Mo gbọ Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - tí n sọ pé: "Eyi tó lọ́lá jùlọ ninu awọn iranti Ọlọhun ni gbolohun: LAA ILAAHA ILLALLOOH, eyi tó sì lọ́lá jùlọ…

