“Imọra ni idaji igbagbọ, ati pe sisọ gbolohun ALHAMDULILLAH maa n kun òṣùwọ̀n, ati pe sisọ gbolohun ALHAMDULILLAH ati gbolohun SUBHAANALLAH, mejeeji maa n kun- tabi o n kun- nnkan ti o n bẹ laaarin sanmọ ati ilẹ
Choose an available translation of this Hadeeth
Hadeeth text
Lati ọdọ Abu Maalik Al-Ash’ari- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Imọra ni idaji igbagbọ, ati pe sisọ gbolohun ALHAMDULILLAH maa n kun òṣùwọ̀n, ati pe sisọ gbolohun ALHAMDULILLAH ati gbolohun SUBHAANALLAH, mejeeji maa n kun- tabi o n kun- nnkan ti o n bẹ laaarin sanmọ ati ilẹ, ati pe irun jẹ imọlẹ, saara jẹ awijare, suuru jẹ imọlẹ, Kuraani maa jẹ ẹri fun ẹ tabi ki o tako ẹ, gbogbo eniyan yoo maa jáde lọ ní aarọ ni ẹni ti o n ta ẹmi ara rẹ, ninu ki o la a kúrò ninu iná, tabi ki o ko ìparun ba a”.
Explanation
Benefits
Pataki mímú ojú tó irun ati pe o jẹ imọlẹ fun erusin Ọlọhun ni aye ati ọjọ igbedide.
Saara ṣíṣe jẹ ẹri lori ododo igbagbọ.
Pataki ṣíṣe iṣẹ pẹlu Kuraani ati gbigba a lododo lati le jẹ ẹri fun ẹ ti ko nii tako ẹ.
Ẹmi ti o ko ba ko airoju ba a pẹlu itẹle yoo ko airoju ba ẹ pẹlu ẹṣẹ.
Gbogbo eniyan dandan ni fun un pe ko ṣiṣẹ; ninu pe ki o bọ okun lọrun ara rẹ pẹlu itẹle tabi ki o ko iparun ba a pẹlu ẹṣẹ.
Suuru ṣíṣe n bukaata si atẹmọra ati wiwa ẹsan ti ilekoko si n bẹ nibẹ.
Attribution
Categories
Share hadeeth
Sharing options · 0 Total shares

