Ẹni ti o ba ka harafi kan ninu tira Ọlọhun, o maa fi gba ẹsan daada kan, ati pe ẹsan kan yio maa ni ilọpo mẹwaa iru rẹ
Choose an available translation of this Hadeeth
Hadeeth text
Lati ọdọ Abdullāh ọmọ Mas‘ūd – ki Ọlọhun yọnu si i – o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: «Ẹni ti o ba ka harafi kan ninu tira Ọlọhun, o maa fi gba ẹsan daada kan, ati pe ẹsan kan yio maa ni ilọpo mẹwaa iru rẹ, mi o sọ wipe “alif lām mīm” harafi kan ni o, amọ alifu harafi kan ni, lāmu naa harafi kan ni, mīmu naa harafi kan ni».
Explanation
Lẹyin naa ni o wa ṣalaye pẹlu gbolohun rẹ ti o sọ pe: (Mi o sọ wipe “alif lām mīm” harafi kan ni o, amọ alif harafi kan ni, lām naa harafi kan ni, mīm naa harafi kan ni): Nítorí naa yio jẹ harafi mẹta ti o ko ẹsan ọgbọn sinu.
Benefits
O n bẹ fun oluka nibi gbogbo harafi kọọkan ninu gbolohun ti o ba n ka ẹsan kan ti wọn o ṣe adipele rẹ ni ọna mẹwaa iru rẹ.
Gbígbòòrò ikẹ Ọlọhun ati ọrẹ Rẹ latari pe O ṣe adipele ẹsan fun àwọn ẹrú Rẹ ni ti ọla ati ọrẹ lati ọdọ Rẹ.
Ọla ti n bẹ fun Alukurāni lori ọrọ ti o yatọ si i, ati jijọsin pẹlu kika a, ìyẹn ri bẹẹ nitori pe ọrọ Ọlọhun ti O ga ni.
Attribution
Categories
Share hadeeth
Sharing options · 0 Total shares

