HadeethEnc · 1.14.0
Adura ti Anabi maa n ṣe loorekoore ju ni:(( “Ọlọ́hun, Oluwa wa, fun wa ni oore ni aye, ati rere ni ìgbẹ̀yìn, ki O si daabo bo wa nibi iya ina”.))
Available translations
Choose an available translation of this Hadeeth
01
Hadeeth text
Lati ọdọ Anas- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Adura ti Anabi maa n ṣe loorekoore ju ni:(( “Ọlọ́hun, Oluwa wa, fun wa ni oore ni aye, ati rere ni ìgbẹ̀yìn, ki O si daabo bo wa nibi iya ina”.))
02
Explanation
Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – maa n ṣe adua lọpọlọpọ pẹ̀lú àwọn adua ṣókí tí o ko nǹkan ti o pọ sinu, ninu rẹ ni: «Olúwa wa, fún wa ní oore ní ayé àti oore ní ọ̀run, kí O sì ṣọ́ wa níbi ìyà Iná» Ó ko oore ayé sínú, bíi ìpèsè arisiki ti o rọrun ti o gbooro, ti o jẹ alaali, ati ìyàwó ti o daa, ati ọmọ itutu ojú, ati ìsinmi, ati ìmọ̀ tí ó wúlò, ati iṣẹ́ rere, àti ohun tí ó jọ ìyẹn ninu awọn ohun ti èèyàn n fẹ ati ohun ti wọn ṣe ni ẹtọ, ati daadaa alukiyaamọ bii lila nibi awọn iya sàréè, ati ibuduro ni ọjọ igbende, ati iná, ati riri iyọnu Ọlọhun, ati nini idẹra gbere, ati isunmọ Oluwa Ajọkẹ-aye.
03
Benefits
Fifẹ ṣíṣe àwọn adua ṣókí tí wọ́n ni ìtumọ̀ pupọ, lati fi kọ́ṣe Anọbi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a-.
Eyi ti o fi n pé julọ ni ki ọmọnìyàn da oore ayé papọ mọ ti ọ̀run nibi adua rẹ.
Eyi ti o fi n pé julọ ni ki ọmọnìyàn da oore ayé papọ mọ ti ọ̀run nibi adua rẹ.
Attribution
[Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]
Categories
Share
Share hadeeth
Sharing options · 0 Total shares

