“Kò tọ́ fun ọmọniyan ki o yan ọmọ-ìyá rẹ lódì tayọ ọjọ́ mẹ́ta, àwọn méjèèjì maa pàdé, eléyìí maa wa gbúnrí, èyí naa maa gbúnrí, ẹni tí ó ni oore ju ninu awọn mejeeji ni ẹni tí ó bá kọ́kọ́ sálámọ̀”
Choose an available translation of this Hadeeth
Hadeeth text
Lati ọdọ Abu Ayyub Al-Ansaariy- ki Ọlọhun yọnu si i- pe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Kò tọ́ fun ọmọniyan ki o yan ọmọ-ìyá rẹ lódì tayọ ọjọ́ mẹ́ta, àwọn méjèèjì maa pàdé, eléyìí maa wa gbúnrí, èyí naa maa gbúnrí, ẹni tí ó ni oore ju ninu awọn mejeeji ni ẹni tí ó bá kọ́kọ́ sálámọ̀”.
Explanation
Ẹni tí ó ni ọlá ju ninu awọn mejeeji ti wọn n jà yii ni ẹni tí o ba n gbìyànjú lati mu odì kúrò, ti o maa wa kọ́kọ́ salamọ, ohun tí a gba lero pẹ̀lú HAJRU nibi ni odì nítorí ìpín ti ẹmi, ṣùgbọ́n odì nítorí tí Ọlọhun, gẹgẹ bii yiyan àwọn ẹlẹṣẹ lódì, ati awọn oni adadaalẹ, ati awọn ọrẹ burúkú, eléyìí ko ni asiko, bi ko ṣe pe o nii ṣe pẹ̀lú anfaani nibi odì, ti o si maa kúrò pẹ̀lú kikuro rẹ.
Benefits
Ọla ti n bẹ fun salamọ, ati pe o maa mu ohun ti n bẹ ninu ẹmi kúrò, o si tun jẹ àmì fun ìfẹ́.
Ojúkòkòrò Isilaamu lori ijẹ ọmọ-iya ati ifẹ láàrin àwọn Musulumi.
Attribution
Categories
Share hadeeth
Sharing options · 0 Total shares

