“Njẹ ẹ mọ ohun ti n jẹ ọ̀rọ̀-ẹ̀yìn?”, wọn sọ pé: Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ ni wọn ni imọ ju, o sọ pé: “Oun naa ni ki o maa sọ nipa ọmọ-ìyá rẹ ohun ti o korira”
Choose an available translation of this Hadeeth
Hadeeth text
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- pe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Njẹ ẹ mọ ohun ti n jẹ ọ̀rọ̀-ẹ̀yìn?”, wọn sọ pé: Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ ni wọn ni imọ ju, o sọ pé: “Oun naa ni ki o maa sọ nipa ọmọ-ìyá rẹ ohun ti o korira”, wọn sọ pé: Ti ohun ti mo n sọ ba n bẹ lara ọmọ-ìyá mi ńkọ́? O sọ pe: “Ti ohun ti o n sọ ba n bẹ lara ọmọ-iya rẹ, o ti sọ ọrọ rẹ lẹ́yìn nìyẹn, ṣùgbọ́n ti ko ba si lara rẹ, o ti dá àdápa irọ́ mọ ọn nìyẹn”.
Explanation
Ṣùgbọ́n ti iroyin naa ko ba si lara rẹ, eyi tun buru ju ọ̀rọ̀-ẹ̀yìn lọ, oun ni BUHTAAN, itumọ rẹ ni: Adapa irọ mọ ọmọniyan pẹ̀lú nǹkan ti ko si lára rẹ.
Benefits
Didara ẹkọ àwọn saabe pẹ̀lú Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, nígbà tí wọ́n sọ pe: Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ ni wọn mọ̀ julọ.
Ki ẹni tí wọ́n ba bi ni ibeere nipa nǹkan ti kò mọ̀ sọ pe: Ọlọhun ni O ni imọ julọ.
Sharia ṣọ àwùjọ pẹlu ṣiṣọ àwọn ẹ̀tọ́ àti ijẹ ọmọ-iya laarin wọn.
Eewọ ni ọrọ-ẹyin ayafi ni àwọn iṣesi kan fun àǹfààní; ninu rẹ ni: Dida àbòsí padà, nibi ti ẹni tí wọ́n ṣe abosi si ti maa dárúkọ ẹni ti o ṣe abosi si i lọdọ ẹni ti o ba le ba a gba ẹtọ rẹ, o maa sọ pé: Lagbaja ṣe àbòsí fun mi, tabi o ṣe bayii fun mi, nínú rẹ̀ ni: Ìjíròrò nipa ọrọ ìgbéyàwó, tabi jijọ da nǹkan papọ, tabi mimu ilé ti ara ẹni, àti ohun ti o jọ ìyẹn.
Attribution
Categories
Share hadeeth
Sharing options · 0 Total shares

