Ẹsẹ mejeeji ẹru kan ko nii yẹ ni ọjọ igbedide titi ti wọn o fi bi i nipa ọjọ ori rẹ nibo ni o pari rẹ si, ati nipa imọ rẹ kini o fi ṣe, ati nipa dukia rẹ nibo ni o ti ko o jọ ati pe nibo ni o na an si, ati nipa ara rẹ nibo ni o lo o si
Choose an available translation of this Hadeeth
Hadeeth text
Lati ọdọ Abu Barzata Al-aslamiy - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Ẹsẹ mejeeji ẹru kan ko nii yẹ ni ọjọ igbedide titi ti wọn o fi bi i nipa ọjọ ori rẹ nibo ni o pari rẹ si, ati nipa imọ rẹ kini o fi ṣe, ati nipa dukia rẹ nibo ni o ti ko o jọ ati pe nibo ni o na an si, ati nipa ara rẹ nibo ni o lo o si».
Explanation
Alakọkọọ: Iṣẹmi rẹ nibo ni o pari rẹ sí?
Ẹlẹẹkeji: Imọ rẹ njẹ o wa a nitori ti Ọlọhun? Ati pe njẹ o fi ṣiṣẹ ṣe? Ati pe njẹ o mu un de ọdọ ẹni ti o lẹtọọ si i?
Ẹlẹẹkẹta: Dukia rẹ nibo ni o ti ko o jọ ṣe nibi ẹtọ ni abi níbi eewọ? Ati pe nibo ni o na an si, ṣe ibi nkan ti o yọ Ọlọhun ninu ni abi ibi ti o bi I ninu?
Ẹlẹẹkẹrin: Ara rẹ ati agbara rẹ ati alaafia rẹ ati ọdọ rẹ nibo ni o lo o si?
Benefits
Awọn idẹra Ọlọhun pọ lori awọn ẹru, ati pe yio bi i leere nipa idẹra eleyii ti o wa ninu rẹ, nitori naa o jẹ dandan fun un ki o gbe awọn idẹra Ọlọhun sí ibi tí yio yọ Ọ ninu.
Attribution
Categories
Share hadeeth
Sharing options · 0 Total shares

