Ẹ ko lee wọ alujanna titi ti ẹ fi maa gbagbọ, ati pe e ko lee gbagbọ titi ti ẹ fi máa nífẹ̀ẹ́ ara yin, ẹ wa jẹ ki n juwe yin si nkankan ti o jẹ pe ti ẹ ba ṣe e ẹ máa nífẹ̀ẹ́ ara yin? Ẹ maa tan salamọ ka laarin ara yin
Choose an available translation of this Hadeeth
Hadeeth text
Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Ẹ ko lee wọ alujanna titi ti ẹ fi maa gbagbọ, ati pe e ko lee gbagbọ titi ti ẹ fi máa nífẹ̀ẹ́ ara yin, ẹ wa jẹ ki n juwe yin si nkankan ti o jẹ pe ti ẹ ba ṣe e ẹ máa nífẹ̀ẹ́ ara yin? Ẹ maa tan salamọ ka laarin ara yin».
Explanation
Benefits
Ninu pipe igbagbọ ni ki musulumi o fẹ fun ọmọ ìyá rẹ nkan ti o n fẹ fun ara rẹ.
Ṣiṣe fifọn salamọ ka ati wiwi i fún àwọn musulumi ni ẹtọ; latari nkan ti o wa nibẹ ni fifọn ifẹ ati ifọkanbalẹ ka laarin awọn eeyan.
A ko ki n salamọ ayaafi si musulumi; fún ọrọ rẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ti o sọ pe: "laarin yin".
O n bẹ nibi imaa salamọ mimu ikọyinsi-ara-ẹni ati ibaraẹni-yan-odi ati ikunsinu kuro.
Pataki ifẹ laarin awọn Musulumi ati pe dajudaju ninu pipe igbagbọ lo wa.
O wa ninu hadīth miran pe dajudaju gbolohun salamọ ti o pe ni: "As salaamu alaykum wa rahmotuLloohi wabarakātuHu", a ti pe o ti to ki a sọ pe: "As salaamu alaykum ".
Attribution
Categories
Share hadeeth
Sharing options · 0 Total shares

