HadeethEnc · 1.14.0
Mo jẹ ọkùnrin kan ti o maa n da atọ ireke lọpọlọpọ, mo maa n tiju lati beere lọwọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nitori ipo ọmọbinrin rẹ, mo wa pa Miqdad ọmọ Al-Aswad láṣẹ o si beere lọwọ rẹ, o sọ pe: "O maa fọ nnkan ọmọkunrin rẹ yoo si ṣe aluwala
Available translations
Choose an available translation of this Hadeeth
01
Hadeeth text
Lati ọdọ Aliy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo jẹ ọkùnrin kan ti o maa n da atọ ireke lọpọlọpọ, mo maa n tiju lati beere lọwọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nitori ipo ọmọbinrin rẹ, mo wa pa Miqdad ọmọ Al-Aswad láṣẹ o si beere lọwọ rẹ, o sọ pe: "O maa fọ nnkan ọmọkunrin rẹ yoo si ṣe aluwala ". O n bẹ fun Bukhari: O sọ pe: "Ṣe aluwala ki o si fọ nnkan ọmọkunrin rẹ".
02
Explanation
Aliy ọmọ Abu Toolib- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ pe atọ ireke- oun ni omi funfun ti kò ki ti o maa n fà tìkọ̀, o maa n jade lati inu nnkan ọmọkunrin nigba adun tabi ṣíwájú ibalopọ- maa n jáde lara oun lọpọlọpọ, Ko si mọ bi o ṣe maa ṣe pẹlu jijade rẹ, o wa tiju lati beere lọwọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-; nitori pe o jẹ ọkọ Fatimah ọmọbìnrin Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, O wa tọrọ lọdọ Miqdad ọmọ Al-Aswad lati beere lọwọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nipa ìyẹn, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- da a lohun pe: Ki o fọ nnkan ọmọkunrin rẹ lẹyin naa ki o ṣe aluwala.
03
Benefits
Ọla ti o n bẹ fun Aliy ọmọ Abu Toolib- ki Ọlọhun yọnu si i-, nigba ti itiju ko kọdi rẹ nibi gbigbe ibeere ju silẹ pẹlu alagata.
Nini ẹtọ yiyan ẹni kan lati lọ ba eeyan beere idajọ ẹsin.
Nini ẹtọ sísọ fun ọmọniyan nipa ara rẹ pẹlu nnkan ti o ba n ti i loju fun anfaani.
Jijẹ ẹgbin atọ ireke, ati jijẹ dandan fifọ ọ kuro ni ara ati aṣọ.
Jijade atọ ireke wa ninu awọn nnkan ti n ba aluwala jẹ.
Jijẹ dandan fifọ nnkan ọmọkunrin ati koropọn mejeeji nitori wiwa rẹ ninu hadiisi mii.
Nini ẹtọ yiyan ẹni kan lati lọ ba eeyan beere idajọ ẹsin.
Nini ẹtọ sísọ fun ọmọniyan nipa ara rẹ pẹlu nnkan ti o ba n ti i loju fun anfaani.
Jijẹ ẹgbin atọ ireke, ati jijẹ dandan fifọ ọ kuro ni ara ati aṣọ.
Jijade atọ ireke wa ninu awọn nnkan ti n ba aluwala jẹ.
Jijẹ dandan fifọ nnkan ọmọkunrin ati koropọn mejeeji nitori wiwa rẹ ninu hadiisi mii.
Attribution
[Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]
Categories
Share
Share hadeeth
Sharing options · 0 Total shares

