Mo ha rakah mẹwaa lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-
Choose an available translation of this Hadeeth
Hadeeth text
Lati ọdọ ọmọ Umar- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Mo ha rakah mẹwaa lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-: Rakah meji ṣíwájú irun Zuhr, ati rakah meji lẹyin rẹ, ati rakah meji lẹyin irun Magrib ni ile rẹ, ati rakah meji lẹyin irun Ishai ni ile rẹ, ati rakah meji ṣíwájú irun Subhi; o jẹ asiko kan ti wọn ko ki n wọle ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nibẹ, Hafsoh sọ fun mi pe ti oluperun ba ti pe irun ti alufajari ba si ti yọ, o maa ki rakah meji, o wa ninu ẹgbawa kan pé: Dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n ki rakah meji lẹyin irun jimọh.
Explanation
Benefits
Ṣíṣe kiki naafila ninu ile lofin.
Attribution
Categories
Share hadeeth
Sharing options · 0 Total shares

