Tani awa?

Spread the love

من نحن؟

Ede Yoruba

Tani awa?

Awa ni Musulumi ti a njọsin fun Ọlọhun nikan ṣoṣo, ti ko si orogun fun Un, A ntẹle Al-Qur’an Alapọnle ati Sunna Anabi Muhammad - ki Ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a - gẹgẹbi agbọye awọn saabe rẹ - ki Ọlọhun yọnu si wọn.

Islam ni ẹsin imu Ọlọhun ni ọkan soso, O npepe lọ sibi ijọsin fun Ọlọhun nikan soso, ati sibi aanu, deede, ati iwa daada.

A gbagbọ pe:

• Ọkan soso ni Ọlọhun ati pe ko si orogun fun Un.

• Al-Qur’an ọrọ Ọlọhun ni.

• Muhammad - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ni Igbẹhin awọn Anabi.

• A gba gbogbo awọn Anabi gbọ - ki alaafia Ọlọhun maa ba wọn - gẹgẹbi Ibrahim, Musa, ati Isa ọmọ Maryam, A nifẹ gbogbo wọn, A si ni igbagbọ pe ojisẹ Ọlọhun ni gbogbo wọn.

• Igbende, ìṣírò iṣẹ, Alujanna, àti Ina jahannama nbẹ o.

Afojusun wa ni ijọsin fun Ọlọhun àti ṣiṣe àwùjọ wa ni anfaani.

Ọna iwọntunwọnsi ni a ngba ṣiṣẹ wa.

A npepe lọ sibi iwa rere, aanu, deede, ati ibagbepọ daada pẹlu gbogbo eniyan.

A nkọ gbogbo iwa ikọja-aala, iwa-ipanle, ati iwa-ifinran.

A nbọ̀wọ̀ fún àwọn òfin ilu tí a ngbé, a sì ń gbiyanju láti jẹ́ ẹni rere àti olùrànlọ́wọ́ fun àwọn ará àdúgbò wa.

Nipa Mọṣalaṣi:

Awọn mọṣalaṣi ni awọn aaye mimọ julọ ati aaye ti o lọla julọ lori ilẹ, awọn ni ile ti a kọ fun ijọsin fun Ọlọhun nikan ṣoṣo.

Moṣalaṣi ki i ṣe ti ẹnikẹni; ti Ọlọhun Ọba ni, o si wa ni ṣiṣi silẹ fun gbogbo ẹni ti o ba fẹ jọsin fun Ọlọhun, tabi ti o fẹ kọ ẹkọ nipa Islam, tabi ti o fẹ dari ẹmi rẹ̀ pada si ọdọ Ọlọhun.

Inu wa dun lati gba awọn ibeere yin pẹlu ọwọ ati ifarabalẹ.

Njẹ awọn ti kii ṣe Musulumi le wọ inu mọsalasi bi?

Bẹẹni, a nki yin kaabọ lati wa kọ imọ nipa Islam.

Ẹ le ṣabẹwo nigbakugba ti awọn oluṣakoso mọṣalaṣi tabi awọn olugbalejo ba wa ninu mọṣalaṣi, paapaa julọ:

• Ni awọn asiko irun maraarun.

• Ni Ọjọ Satidee ati Ọjọ Sunday ti wọn fi kalẹ fun gbigba alejo.

• Ni awọn ọjọ ọdun itunu aawẹ ati ọdun ileya.

• Nigbati wọn ba npalẹmọ lati tunu ninu osu Ramadan.

Mọsalasi aaye ijọsin, ẹkọ ati alaafia lo jẹ.

Awọn itọnisọna fun Ibẹwo:

• A fẹ ki a maa wu iwa irẹlẹ ati ibọwọ fun aaye naa, nitoripe ile Ọlọhun ni.

• Dandan ni ki a bọ bata wa ki a to wọ inu mọsalasi.

• Ẹnu ọ̀nà ọtọ ati aaye ikirun ọtọ wa fun awọn obinrin.

• Awọn aṣọ daada wa fun yiya ti a ba ni bukaata si wọn.

Fun ẹkunrẹrẹ alaye nipa Islam tabi ti ẹ ba nifẹsi Al-Qur’an kan:

https://sarhaan.com/

Ekaabọ

Emi nifẹ si iwe yii; nitoripe o seeṣe ki a fi kọ si inu awọn mọṣalaṣi, pẹlu hashtag ati oju opo wẹẹbu wa ni ṣoki.

Shopping Basket